Spurs ti tẹsiwaju ninu idije FA Cup lẹyin ti wọn na Swansea

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ẹgbẹ agbabọọlu Spurs ti wọ ipele to kagun si ti asekagba ninu idije FA Cup lẹyin ti wọn f'agba han Swansea.
Tottenham naa Swanse ni pẹlu ami ayo mẹta sodo.
Christian Eriksen lo kọkọ ba Spurs jẹ bọọlu niṣẹjukọkanla ti wọn bẹrẹ ere lẹyin igba ti Erik Lamela gba bọọlu si.
Awọn alejo ti ikọ agbabọọlu Swansea gba naa wọn ko ni awọn ko fikun fun wọn.
Sugbọn igbiyanju wọn ko jamọ nnkankan titi di ipari apakinni ere naa nigba ti Erik Lamela gba bọọlu wọle lẹyin igba to gba bọọlu lati ọdọ Moussa Sissoko.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Lẹyin igba ti wọn bẹrẹ apa keji ifẹsewọnsẹ naa, ni Christian Eriksen ba Spurs jẹ bọọlu ẹlẹkẹta lori iṣẹju kẹtalelọgọta.








