ICPC rọ ààrẹ Buharí láti dá àwọn ọ̀gá àgbá ilé iṣẹ́ tọ́rọ́ ṣí mọ́ lórí dúró

Ile Iṣẹ ICPC

Oríṣun àwòrán, ICPC

Alága àjọ tó n ri sí ọrọ awọn tó n lu owó ìlú ni pònpó àti àwọn ẹsẹ̀ míràn ICPC, ọjọ̀gbọ́n Bolaji Owasanoye tí naka ìdọ̀tí sí àwọn fásìtì, ilé iwòsàn ijọba apapọ, àwọn ilé iṣẹ́ ijọba tí wọ́n ń tẹ abá ìsúnà.

Owó tí wọ́n ti fi kún àbá ìsúná wọ́n ti tó bílíọnù méjìdínlógún o lé ọwọ́ mẹ́sàn naira èyí sì wáyé láàrin Fasiti olùkọni àgbà fún iṣegun ti Benin gẹgẹ bi wọn ṣe fí bílíọnù kan ó lé ọwọ kan lé (1.1Bílíọnù), Federal Medical Centre Bayelsa bílíọnu kan o dín díẹ (915 miliọnu) Fasiti Nnamdi Azikwe, bílíọnu kan o dín díẹ̀ (907 miliọnu).

Àwọn fasiti to ku ni Fasiti Jos ọgọrin mẹrin mílíọnu lé mẹrindinlọgọrun (896) miliọnu), ilé ìwòsàn University College Ibadan (701 mílíọnu) Fasiti Usnman Dan Fodiyo (636 mílíọnù) àti Fasiti Ibadan (558 mílíọnù).

Owasanoye ṣàlàyé pé ICPC ti gba bílíọnu meji Naira nípa bi wọn ṣe f'imú fin'lẹ láti rí àwọn iṣẹ́ akanṣe awọn ọmọ ilé ìgbìmọ asòfin (Constituency projects).

Ọgá àgbà náà sí ní láti bi osù mẹ́wàá ṣẹ́yìn ni ajọ náà ti gba àwọn ǹkan iní ti à fojuri ti owo rẹ̀ to Bílíọnù mejilélọgbọ̀n, yála ki ijọba gbẹsẹ le e pátápáta tàbi ki wọn gba fun igba diẹ̀ ki igbẹjọ to pari.

Bakan náà ni o fi kún un pé ni ti owó, àwọn ti gba ní dọla àti naira owó to lé ni bilọnù mẹta báyìí.

Ọ̀gá ICPC wa rọ ààrẹ Buhari láti dá àwọn ọga ajọ ati ilé iṣẹ́ ti igbá ọ̀rọ̀ náà ṣí mọ lórí dúró titi ti ìwádìí yóò fi parí.

Àkọlé fídíò, 'Lóṣù mẹ́ta sẹ́yìn, mò ń wa ọkọ̀ taasín, ṣùgbọ́n wọ́n sọ mí di afọ́jú lọ́san gangan'