Kogi àti Bayelsa: Gomina Yahaya Bello ti Kogi àti David Lyon ti Bayelsa gba ìwé ẹ̀rí INEC

Yahaya

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Gomina Yahaya Bello gba iwe ẹri mo yege lọwọ ajọ eleto idibo

Ajọ eleto idibo INEC ti fun gomina ti wọn kede pe o jawe olubori ninu idibo ipinlẹ Kogi, Yahaya Adoza Bello ni iwe ẹri lati pada sipo gomina.

Edward Onaja naa gba iwe ẹri o pegede lati gba ipo igbakeji gomina ipinlẹ Kogi Adájọ́ àgbà ní Kogi búra fún igbákejì gómìnà tuntun.

Awọn mejeeji ni wọn ti jọ n tukọ ipinlẹ Kogi naa papọ lẹyin ti Yahaya Bello ti fa Onoja kalẹ gẹgẹ bi igabkeji rẹ tẹlẹ.Yahaya Bello, Gomina ìpínlẹ̀ Kogi kéde Onoja ní ìgbákejì tuntun

David

Oríṣun àwòrán, Inec

Àkọlé àwòrán, INEC fun David Lyon to dije dupo gomina labe APC

Bi ajọ eleto idibo INEC ṣe n fun Gomina Yahaya Bello ati Onoja igbakeji rẹ ni iwe ẹri o yege naa ni wọn n fun David Lyon ni Bayelsa.

David lo dije dfupo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Bayelsa pẹlu Senetọ Biobarakuma Degi-Eremienyo to jẹ igbakeji rẹ.

Arabinrin May Agbamuche-Mbu to jẹ adari ajọ eleto idibo ni ẹkun Bayelsa, Edo, ati ipinlẹ Rivers lo fun awọn mejeeji ni iwe ẹri yii ni Yenagoa Bayelsa loni.

Lyon ni oun fi iwe ẹri naa sọ ori awọn eniyan ipinlẹ Bayelsa lẹyin to dupẹ lọwọ ajo INEC, awọn agbofinro ati awọn oṣiṣẹ elto aabo gbogbo pe wọn ṣiṣẹ daadaa.

Gomina Bello ati Onoja igbakeji rẹ a bẹre iṣẹ fun saa iṣejọba tuntun yii ni ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kinni, ọdun 2020.

Ogbeni Muhammed Haruna to jẹ kọmiṣọna fun ajọ eleto idibo ni ẹkun Kogi, Kwara, ati Niger lo fun wọn ni iwe ẹri naa loni ni Lokoja.

Àkọlé fídíò, Ohun tawọn eeyan Kogi n sọ saaju idibo Gomina

Bello naa gboriyin fawọn eniyan ipinlẹ Kogi pẹlu ileri tuntun lati ṣeto ijọba to dara lasiko yii.

Gomina tuntun naa nṣeleri lati ṣiṣẹ pẹlu awọn agbofinro lati ṣawari awọn to ṣiṣẹ ibi ṣaaju, idibo ati lasiko idibo ni ipinlẹ Kogi.