Olupele ti ìlú Ipele, Ọba Victor Aganun tẹri gbaṣọ

Oba Victor Oluwasegun tó tẹri gbaṣọ

Oríṣun àwòrán, Others

Kábíyèsí, Ọba ìlú Ipele, ìjọba ìbílẹ̀ Owo ní ìpínlẹ̀ Ondo, Ọba Victor Oluwasegun Aganun, Iredokun I ti darapọ̀ mọ́ àwọn babańlá rẹ̀.

Ọba Oluwasegun Aganun ni Olupele kọkàndínlógún kó tó lọ darapọ̀ mọ́ àwọn babańlá rẹ̀.

Nígbà tó ń kéde ìpapòda Ọba onípò kìíní náà ní òwúrọ̀ ọjọ́rú fún àwọn olóyè, ọmọọba Olatunbọsun Aganun ní àwọn kò ní ṣọ̀fọ̀ kábíèsì nítorí baba ti fi ohùn kalẹ̀ kó tó re ìwàlẹ̀ àṣà.

Ó ní bàbá òun gbé ìgbé ayé réré tó sì fi àwọn ìtàn lélẹ̀ ní ìlú Ipele kó tó di wí pé ó tẹ́rí gbaṣọ.

Olupele pẹlu gómìnà Akeredolu nígbà tí Ọba ń gba ọ̀pá àṣẹ

Oríṣun àwòrán, Others

Oba Victor Oluwasegun Aganun

Oríṣun àwòrán, Others

Ó ṣàlàyé pé Oba Aganun ni Ọba Ipele àkọ́kọ́ tí wọ́n sọ di onípò kìíní, tí gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo sì gbé ọ̀pá àṣẹ lé lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí Olupele.

Ọmọọba Olatunbosun Aganun sọ fún àwọn olóyè pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ètò ìsìnkú ní kíákíá.

Ní ọjọ́ Kẹrìnlélógún, oṣù Kẹta ọdún 2022 ni wọ́n yan Oba Victor Oluwasegun gẹ́gẹ́ bí Olupele ti ìlú Ipele tí gómìnà Akeredolu sì gbé ọ̀pá àṣẹ lé e lọ́wọ́ ní ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹjọ ọdún 2022 bákan náà.

Ní ọjọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹfà ọdún 1948 ni wọ́n bí Oba Victor Oluwasegun Aganun sínú ẹbí Iredokun Akapo Ilana ti ìlú Ipele.

Olori Banke Aganun, àwọn ọmọ, ọmọọmọ ló gbẹ́yìn Kábíyèsí.