Ikòͅ Taliban ti pa olórí agbésùnmòͅmí tó wà nídí ìsͅèͅlèͅ àdó olóró ní pápákòͅ òfúrufú ní Kabul

Aworan

Oríṣun àwòrán, EPA

Adari Ikoͅ agbeͅsunmoͅmi Islamic State to wa nidi isͅeleͅ jiju ado oloro si papakoͅ ofurufu ni Kabul, ni orileͅede Afganistan ni oͅdun 2021 ti ku.

Igbesunmoͅmi naa sekupa awoͅn araalu aadoͅjoͅ(170) peͅlu ikoͅ oͅmoͅogun Ameͅrika meͅtala.

Ijoͅba orileͅede Amerika lo fi iroyin naa lede pe awoͅn Taliban lo sͅekupa adari ikoͅ IS naa.

Orileͅede Amerika ni oͅgboͅtagiri agbesunmoͅmi naa ni woͅn pa ni nkan bi oͅseͅ melo seͅyin amoͅ ti woͅn se iwadii finifini ki woͅn to fi iroyin naa lede.

Aadoͅjoͅ araalu, ikoͅ oͅmoͅgun ileͅ Ameͅrika meͅtala ati oͅmoͅ ileͅ Geͅeͅsi meji, ati oͅmoͅ ara Ileͅ Geͅeͅsi ni ijoͅba Ileͅ Geͅeͅsi kede pe woͅn ba isͅeͅleͅ naa loͅ.

Amoͅ woͅn ko darukoͅ eͅni to ku oͅhun.

Ijoͅba Ameͅrika ni iwadii oͅfintoto ti woͅn se lo jeͅ ki woͅn fidi reͅ muleͅ pe lootoͅ ni oͅkunrin naa ti fi ileͅ se asoͅ ibora.

Woͅn ni oͅjoͅ aje ni ijoͅba ileͅ Amerika ti beͅreͅ si ni pe awoͅn moͅleͅbi awoͅn ti woͅn ba ninu isͅeͅleͅ ado oloro naa ni oͅdun meji seͅyin.

Iseͅleͅ ado oloro naa lo waye leͅyin wakati dieͅ ti ijoͅba ileͅ Yuroopu kede fun awoͅn eniyan woͅn lati mase sunmoͅ papakoͅ ofurufu Kabul nitori o seese ki iseͅleͅ laburu waye nibeͅ

Nkan bi aago meͅfa iroͅleͅ ni iseͅleͅ naa waye ni oͅjoͅ keͅrindinloͅgboͅn, osͅu keͅjoͅ, oͅdun 2021 ni Abbey Gate, ni papakoͅ ofurufu naa ti agbeͅsunmoͅmi kan boͅ si aarin awoͅn moͅleͅbi to n duro de oͅkoͅ ofurufu nibeͅ.

Awoͅn to peͅjoͅ sibeͅ ni woͅn reti oͅkoͅ ti yoo gbe woͅn loͅ kuroͅ ni orileͅede Afganistan, leͅyin ti Ameͅrika jawoͅ ninu ogun naa ti woͅn si ko awoͅn oͅmoͅogun woͅn kuro nibeͅ.

Aadoͅjoͅ araalu, ikoͅ oͅmoͅgun ileͅ Ameͅrika meͅtala ati oͅmoͅ ileͅ Geͅeͅsi meji, ati oͅmoͅ ara Ileͅ Geͅeͅsi ni ijoͅba Ileͅ Geͅeͅsi kede pe woͅn ba isͅeͅleͅ naa loͅ nigba naa loͅhun.

Awoͅn araalu si n da eͅbi ru ijoͅba ileͅ Amerika to koͅ awoͅn ikoͅ oͅmoͅogun reͅ kuro ni Afghanistan, ti woͅn si jeͅ ki awoͅn ikoͅ Taliban gba ijoͅba pada nibeͅ.