Àjọ ORBDA ní kí ìpínlẹ̀ Ogun, Eko, Osun gbáradì fún omíyalé

Àkọlé fídíò, Gbọ́ ìkìlọ tí àjọ ORBDA fí síta lórí ẹ̀kun omi tí yóò wáyé ní Eko,Ogun ati Osun
Àjọ ORBDA ní kí ìpínlẹ̀ Ogun, Eko, Osun gbáradì fún omíyalé
Aworan afihan omi to n tu jade

Oríṣun àwòrán, Facebook/oorbda

Igi gogoro ma fi bọ mi loju, ni paapa eleyi to niṣe pẹlu ẹkun omi ni Naijiria, o di dandan ka bẹrẹ si ni lọgun rẹ lati jina jina.

Eleyi lo difa fun bi ọga agba ajọ to n mojuto iṣakoso omi ni ipinlẹ Ogun,Ogun-Oshun River Basin Development Authority,ORBDA ti ṣe fi ikilọ sita faraalu lori ẹkun omi lọdun 2023.

O fi ikilọ yi sita lasiko to n fọrọwerọ pẹlu akọroyin BBC Yoruba lori ipalẹmọ de ẹkun omi ti awọn alaṣẹ ti kilọ pe yoo waye.

Alagba Olufemi Odumosu to jẹ ọga ajọ ọhun sọ pe omi kii kilọ tabi duro de awọn eeyan ko to fa ijamba paapa lasiko ojo.

Odumosu tẹsiwaju pe ajọ to n wo bi oju ọjọ ṣe ri ni Naijiria ti ta awọn lolobo nipa ẹkun omi tawọn naa si ti n sọ fun awọn to le kan.

''Ipinlẹ Osun, Ogun ati Eko wa labẹ awọn ipinlẹ ti o wa ninu ewu omiyale.''

Ninu awọn ilu to darukọ, o ni Abeokuta wa lara awọn ilu ti yoo kan. Tori naa o ni awọn ti n ṣe igbaradi ni ajọṣepọ pẹlu awọn ijọba ipinlẹ ati ibilẹ ibi ti yoo de.

Lori Daamu Oyan ti awọn araalu maa n pariwo rẹ pe o maa n fa omiyale, Odumosu sọ pe bi kii ba ṣe ti Daamu yi tawọn fi n dari omi,ọpọ ibi ni ijamba omiyale ko ba de.

O wa rọ awọn to n kọle si ojuọna omi lati jawọ ninu iru iwa bayi tori pe omiyale kii woju eeyan to ba delẹ tan.