Ketu Flood: Ọ̀tọ̀ lọ̀rọ̀ táa ń pè ìjọba sí o, ẹ wá wò ó
Ko pẹ ti iroyin tan ka pe agara ojo gbe awọn ọmọde meji kan lọ ni agbegbe Ketu ni ipinlẹ Eko, BBC Yoruba gbiyanju lati lọ ba awọn obi awọn ọmọ naa sọrọ.
Ṣugbọn ọ̀tọ̀ lohun a ba lọ, ọtọ lohun taa ba bọ lati adugbo naa.
Niṣe lariwo n sọ heee pẹlu bi alagbalugbu omi ṣe wọ ni gbogbo adugbo naa.
Olugbe kan ti BBC Yoruba ba sọrọ, John Okegbola sọ pe "omi ko gbe ọmọ kankan lọ, ti omi ba gbe ọmọ lọ lati ijẹta, ko si bi ko ṣe ni maa wa ọmọ. Ko si si ohun kankan to n lọ ladugbo yii ti mi o ki n mọ, ko si ẹni kankan to n wa ọmọ".
John ni. Asọdun awọn eeyan pọ ni pẹlu iroyin ti wn n pe kiri. O ni aduru dukia to n sọnu ni gbogbo igba ti ẹkun omi yii ba bẹrẹ ti ko si si ohun ti ijọba ṣe.
Ariwo pe ijọba fi ẹtẹ silẹ, wọn n pa lapalapa ni awọn ara adugbo n kigbe pẹlu bi wọn ṣe n banujẹ lọwọlọwọ.