UNICEF: Ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ pọ̀ ju ilé ìgbọ̀nsẹ̀ lọ l'órílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Ile igbọnsẹ ita gbangba kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ida mọkandinlogoji ninu ọgọrun awọn ọmọ orilẹede Naijiria ni wọn lanfani si ile igbọnsẹ to jẹ pe idile kan nikan lo n lo o

Ẹ gbọ na, ninu ẹrọ ibanisọrọ ati ile igbọnsẹ ewo gan lo ṣe pataki ju?

Ibeere yii lo n gba ẹnu ọpọ kan bayii lẹyin ti Ajọ to n risi idagbasoke ọmọ wẹwẹ lagbaye, UNICEF sọ pe awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria to ni ẹrọ ibanisọrọ pọ ju awọn to lanfani ile igbọnsẹ lọ.

Ko si ani-ani pe iṣoro igbọnsẹ pọ lorilẹ-ede Naijiria, paapaa julọ lawọn ẹsẹ pupu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Ọṣun Decides:'Màá san gbogbo owó oṣù òṣìṣẹ́ lékunréré'-Akinbade

Amọṣa awọn onka ti ajọ UNICEF wa fi sita nibi idanilẹkọọ kan lo tun da bi ẹni pe o kọ ọpọ onwoye nibi idanilẹkọọ naa ni ominú.

Gẹgẹ bii ọga agba fun imọtoto ati omi to mọ gaara lajọ UNICEF, Zaid Jurji ṣe sọ, ogoje miliọnu lawọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria to ni ẹrọ ibanisọrọ, ṣugbọn miliọnu mẹtadinlọgọrun lawọn to ni anfani ile igbọnsẹ.

O ni ida mẹtadinlogoji ninu ọgọrun awọn ile eto ilera lorilẹ-ede Naijiria lo ni ile igbọnsẹ fawọn alaisan.

Ile igbọnsẹ igbalode kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ko si aniani pe iṣoro igbọnsẹ pọ lorilẹede Naijiria, papaa julọ lawọn ẹsẹ pupu

Bakan naa lo ni ida mọkandinlogoji ninu ọgọrun awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ni wọn lanfani si ile igbọnsẹ to jẹ pe idile kan nikan lo n lo o.

"Lai si ile igbọnsẹ, ọranyan ni fun awọn eeyan lati wa ibi ti wọn yoo tura si; ita gbangba si ni ọna abayọ niru ipenija bẹẹ, eleyi si lee fa ọpọ arun bii igbẹ gbuuru, ọnigbameji tabi iba pọnju-pọntọ"

Ọga agba UNICEF naa ṣalaye pe, "ẹgbẹrun mejilelọgọfa awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria, ninu eyi ti ẹgbẹ mẹtadinlaadọrun ti jẹ ọmọ wẹwẹ, ni aisan igbẹ gbuuru n ran lọ sọrun lọdọọdun; bẹẹ ni biliọnu marundinlẹẹdẹgbẹta naira ni orilẹ-ede Naijiria n padanu lọdun nitori aisi imọtoto to yẹ".

Àkọlé fídíò, Ìkọ BBC Yorùbá ṣe àbápade ọkùnrin tó ní òún le darí òjò síbi tó wù òun