Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ fẹ́ gùnlé ìyanṣẹ́lódì aláìní gbèdéke, ìdí rèé

Olùkọ́ tó ń kọ iṣẹ́ sójú pátákó ìkọ̀wé

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní orílẹ̀ èdè Ghana ti ń gbèrò láti bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì aláìní gbèdéke káàkiri orílẹ̀ èdè náà bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá ọdún 2022.

Lára àwọn òṣìṣẹ́ tó máa kópa níbi ìyanṣẹ́lódì náà ni àwọn dókítà, olùkọ́, àwọn agbẹ̀bí, àwọn nọ́ọ̀sì, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àtàwọn míì.

Akọ̀wé àpapọ̀ fún ẹgbẹ́ Trade Union Congress, TUC ní orílẹ̀ èdè, Dókítà Yaw Baah ní gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ló fẹnukò pé kí àwọn bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì àyàfi tí ìjọba bá dáhùn sí ìbéèrè àwọn.

Baah kéde pé nítorí ìjọba ń gbèrò láti yá owó ìfẹ̀yìntì àwọn ni àwọn ṣe fẹ́ lọ fún ìyánṣẹ́lódì náà.

“Ó dìgbà tí ìjọba bá kéde rẹ̀ ní gbangba wí pé àwọn kò ní fi ọwọ́ kan owó ìfẹ̀yìntì àwọn kí àwọn tó ṣẹ́wẹ́le ìyanṣẹ́lódì.”

Ó ní àwọn ń ṣe ìkìlọ̀ fún ìjọba láti má fi ọwọ́ kan owó àwọn bí ìjọba ṣe kéde ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá wí pé àwọn fẹ́ yá àwọn owó kan.

Ó ṣàlàyé pé bí ìjọba bá filè tọwọ́bọ owó náà láti yá, àwọn òṣìṣẹ́ yóò ní ìṣòrò láti gba owó ìfẹ̀yìntì wọn nígbà tí wọ́n bá kúrò lẹ́nu iṣẹ́.

Báwo ni ìyanṣẹ́lódì náà yóò ṣe ṣàkóbá fún àwọn ènìyàn Ghana?

Ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ girama ní orílẹ̀ èdè Ghana (GNAT), ẹgbẹ́ àwọn dókítà àti nọ́ọ̀sì àti ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ni ìrètí wà wí pé wọn yóò kópa nínú ìyanṣẹ́lódì yìí.

Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé gbogbo ilé ìwòsàn, ilé ẹ̀kọ́ girama àti ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ni yóò wà ní títì pa.

Ipa èyí yóò lágbára púpọ̀ lórí àwọn ènìyàn Ghana pàápàá fún àwọn tó ń lo ilé ìwòsàn ìjọba.

Ghana ṣe ìdádúrò gbígba gbèsè ilẹ̀ òkèrè

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Mínísítà fètò ìsúná orílẹ̀ èdè Ghana, Ken Ofori Attah ètò pàsípààrọ̀ kan láti mú àdínkù bá àìrajaja ètò ọrọ̀ ajé tó ń bá àwọn olùdókoòwò orílẹ̀ èdè náà fínra.

Bákan náà ni ìjọba tún kéde wí pé àwọn ti ṣe ìdádúrò owó yíyá láti ilẹ̀ òkèrè.

Ìjọba Ghana ní gbígba gbèsè láti ilẹ̀ òkèrè ń ṣe àkóbá fún owó orílẹ̀ èdè náà.

Wọ́n ní àwọn kò ní san àwọn gbèsè kan tí àwọn ń san lọ́wọ́ títí nǹkan máa fi bọ̀ sípò fún orílẹ̀ èdè àwọn.