Yìnyín àbàadì ti ọ̀pọ̀ èèyàn mọ́ inú ọkọ̀ àti ilé, òkú sùn ní New York

Oríṣun àwòrán, Reuters
O to eeyan mejidinlọgbọn to ti padanu ẹmi wọn nítorí afẹsi yìnyín to ba apa ariwa Orilẹede Amẹrika ja.
Gẹgẹ bii wọn ṣe kede ọrọ naa, ọpọ awọn eeyan ni yìnyín ọhun ko fun lanfani lati jade sì ta, koda o ti awọn miiran mọ ninu ọkọ ayọkẹlẹ wọn fun ọjọ meji.
Iwadi fihan pe o sese ko jẹ pe yínyin yii lo tii buru julọ bayi.
Awọn onimọ nipa yìnyín tí ṣe ni ikilọ fun awọn araalu pe o se se ki yìnyín ọhun tún pele si to ba di ọjọ Isẹgun ọsẹ yii.
Yìnyín ọhun to wa lati Canada to si morile Mexico ni o ti ṣekúpa eeyan mẹrindinlọgọta.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Aarẹ Biden ba awọn araalu kẹdun
Aarẹ Orilẹede Amerika, Joe Biden tí buwọlu itọju pajawiri fun awọn ipinlẹ to koju yìnyín ọhun.
"Mo ba awọn to padanu mọlẹbi wọn lasiko yiikẹdun."
Mark Poloncarz, Ọga agba fun Ileeṣẹ Erie County niluu Buffalo ni "Ani igbagbọ pe a o ri opin yìnyín yìí sugbọn a ko ti de òpin rara.
"Ti a ko ba tete gbe igbesẹ, o le se akoba fun awọn eeyan wa."
Poloncarz tẹsiwaju pe pupọ awọn eeyan agbegbe naa lo tí padanu ẹmi wọn nitori wọn ko ni anfani lati mi daadaa nigba ti wọn n fi yìnyín naa simu.
O ni awọn ba oku awọn miiran ninu ọkọ ayọkẹlẹ wọn.
Yìnyín rán èèyàn 38 sọ́run, 200,000 kò ríná ọba lò

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O kere tan, eeyan mejidinlogoji lo ti gbẹmi mi bayii ni North Amẹrika, ti awọn onimọ si sọ pe iku wọn ko ṣẹyin otutu amuju ati iji lile to kọlu Amẹrika ati Canada.
Ijọba ilẹ naa fidi rẹ mulẹ pe eeyan mẹrinlelọgbọn lo ku nitori otutu nikan, nigba ti ilu Buffalo, ni New York jẹ ibi ti otutu naa ti milẹ julọ.
Ni Canada, eeyan mẹrin ku lẹyin ti bọọsi akero kan yọ lori yinyin lagbegbe Merritt, ni iha iwọ oorun Bristish Columbia.
Awọn onimọ sayẹnsi sọ pe awọn ko tii ri irufẹ iji ati yinyin bẹẹ ri.
Awọn to n sọ asọtẹlẹ nipa bi oju ọjọ yoo ṣe ri ti sọ pe iji naa yoo dẹ lẹyin ọjọ diẹ si asiko yii amọ wọn ti gba awọn araalu niyanju lati yẹba fun irinajo ti ko ba ṣe koko.
Bo tilẹ jẹ pe iji naa ti ba ọpọ nnkan jẹ, ina ijọba ti n pada si awọn agbegbe kan ti ina ọhun ti lọ ṣaaju.
O kere tan, nnkan bi ẹgbẹrun meji eeyan ni ko ni ina ijọba lọjọ ọdun Keresimesi lati nnkan bii miliọnu meji eeyan ṣaaju.

Ẹgbẹgbẹrun irinajo ọkọ ofurufu ni wọn ti wọgile nitori iji lile
Ẹgbẹgbẹrun irinajo ọkọ ofurufu ni wọn ti wọgile nitori iji lile naa, eyii ti ko jẹ ki ọpọ eeyan lanfani ati ṣe ọdun pẹlu awọn ẹbi wọn.
Nigba ti gomina ipinlẹ New York, to jẹ ọmọ bibi ilu Buffalo yoo sọrọ nipa iji naa, o ni jẹ eyii to buru julọ ninu itan ilẹ Amẹrika.
Lara awọn eeyan to ba iji lile pẹlu otutu yii lo ni wọn ba ninu ọkọ wọn, nigba ti wọn ri awọn mii labẹ yinyin.

















