Kí ló fa kí ìbínú obìnrin burú ju ti ọkùnrin lọ láti ọdún 2017?
Gẹgẹ bi isẹda awọn obinrin, onisuuru ati onifarada ni ọpọ eeyan mọ wọn si sugbọn awọn isẹlẹ to n tọwọ awọn obinrin waye lẹnu lọọlọ yii n kọ ni lominu.
Awọn onwoye si lo ti woye pe ọna alagbara ni awọn obinrin n gba binu lẹnu lọọlọọ yii.
Bo se ninu ile, ibi isẹ tabi ni awujọ, isẹ iwadi ti fihan pe ibinu awọn obinrin ti n buru si lati ọdun 2017 jakejado agbaye.
Koda, awọn obinrin jakejado agbaye ti n jade lati fi ẹhonu wọn han lawujọ nipa awọn ohun to tako ilọsiwaju wọn.
Ẹhonu awọn obinrin yii si lo maa n mu ibinu ati ẹhonu alagbara lọwọ lọpọ igba.

"Ijakulẹ, irẹwẹsi ọkan ati aisi igbẹkẹle lo n fa ibinu ọpọ obinrin"
Gẹgẹ bi onisẹ iwadi kan ti salaye, ijakulẹ ti ọpọ obinrin n ba pade ti mu ki aisi igbẹkẹle ati irẹwẹsi ọkan ba wọn.
O ni awọn isẹlẹ yii lo mu kawọn obinrin maa fa ibinu yọ, ti wọn kii si gbọ tabi gba mọ lasiko ti ibinu wọn ba de.
Ọpọ awọn obinrin to ba n binu yii ni ibinu wn maa n gba to ogun isẹju tabi ju bẹẹ lọ, ki inu wọn to rọ.
Asiko yii, lo ni wọn si le ba nnkan jẹ pupọ nipa oniruuru ọna ti wọn n gba fi ibinu wọn naa han.
Iwadi naa ni ibinu obinrin le ni ipa to buru pupọ, ti wn ko ba tete da wọn duro.
















