Títí tí mo fi pé ẹni ọdún méjìdínlógún, n kò rí bàtà wọ̀ - Adeboye

Oríṣun àwòrán, rccg
Oluṣọaguntan agba fun ijọ Redeemed Christian Church of God, Pasitọ Enoch Adeboye ti ṣalaye pe ohun pataki ti ayajọ Keresimesi jẹ fun oun.
Adeboye ni oun jẹ ọkan lara awọn eeyan ti iwaye Jesu Kristi, ti ajọdun Keresimesi da le lori, ṣe pataki fun nitori ayipada to mu ba igbe aye oun lati ipo otoṣi wa si ọlọrọ.
Pasitọ Adeboye sọrọ yii ninu iwaasu ọdun to gbe kalẹ eyi to pe akori rẹ ni “Ẹbun alailabuku” lọjọ Aiku.
Pasitọ Adeboye ni ọdun mejidinlogun gbako ni oun ko fi ri bata wọ si ẹsẹ laye oun.
Nibi ti ẹbi mi tosi de, gbogbo wa la n jo, lọjọ ti baba mi ra aburada"
O sọ eyi nigba to n ṣe agbekalẹ ara rẹ gẹgẹ bi apẹrẹ bi Jesu Kristi ṣe n wọ aye eniyan, to si n mu iyipada ba aye bẹẹ.
“Gbogbo ẹyin ti ẹ mọ diẹ nipa ipilẹ mi, ẹ o mọ pe atapata dide ẹda ni mi.
Inu oṣi to lagbara ni mo ti bẹrẹ. Nibi ti baba mi toṣi de, awọn otoṣi gan an tun n pe e ni otoṣi debi wi pe ni ọjọ to ra aburada, gbogbo wa la n jo.
"Fun ọdun mejidinlogun akọkọ nile aye mi, nibi ti nnkan le de, n ko ni bata kankan.
Lẹyin eyi mo gba Jesu sinu aye mi, gbogbo nnkan si n yi pada fun mi. Ẹ wo mi loni.
Tẹlẹ orukọ ilu mi ko si ninu maapu orilẹede Naijiria. Amọṣa, loni nitori pe mo gba Jesu, orukọ ilu mi ti han ninu iwe afihan maapu gbogbo agbaye.”















