Òkò rùgùdù lórí Portable torí Small Doctor, àwọn ọdọ Agege kọjú oro si lóde ijó

Oríṣun àwòrán, portablebaeby/Instagram
Gbajumọ olorin takansufe nni, Habeb Okikiola, ẹniti gbogbo ẹniyan mọ si Portable Ọmọ Olalomi lo ti kan ijangbọn lode ijo.
Isẹlẹ naa waye nigba ti awọn ololufẹ olorin Small Doctor n sọ ike omi lu lakoko to fẹ kọrin nibi ipatẹ orin to waye ni agbegbe Agege nilu Eko.
Saaju ni Portable ti kọkọ sọrọ kobakungbe si Small Doctor lori ẹrọ ayelujara amọ ti ọkunrin kan, Abul Abel ti bawọn pẹtu si aawọ wọn.
Ninu fidio nipa ohun to fa ija laarin awọn olorin mejeeji, eyi to ti gba ori ayelujara kan bayii, ni Portable ti fi ẹsun iwa ọdalẹ kan Small Doctor.
Portable ni Small Doctor kere si nọmba oun ninu awọn olorin ti o jade lati inu Agege.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Funra awọn ero iworan ni wọn fi owo wọn ra wahala - Portable Were Olorin
Nigbati Small Doctor n fi Portable han lati wa kọrin, ṣe ni awọn ọdọ agbegbe Agege bẹrẹ si sọ ike omi mọ, ti wọn ko si fẹ ko kọrin fun awọn.
Amọ kaka ki Portable bẹbẹ, ko si pẹtu sawọn ero iworan naa ninu, ṣe lo n fapa janu, to si n sọko ọrọ si wọn.
Idaamu Adugbo n pariwo pe awọn ero iworan naa to fi owo wọle sibi eto orin 'Awọn lo fi owo wọn pe wahala", eyii to mu ki inu bi awọn ọdọ Agege.
Bi o tilẹ jẹ pe onigbọwọ ipatẹ ayẹyẹ ijo naa, Small Doctor, rawọ ẹbẹ sawọn onworan naa, amọ se ni awọn ọdọ naa yari, ti wọn ko si fẹ ri igbẹ Portable laatan.
Ohun to si sokunfa bawọn onworan naa se yari kanlẹ ni pe wọn ni Portable fi ẹgbin rẹ Small Doctor lara, bẹẹ si ni ọmọ agbegbe Agege ni Small Doctor jẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Small Doctor ati Ika of Africa ti pari ija wọn
Nibayii, fidio tuntun ti Portable fi soju opo ayelujara Instagram rẹ ti sisọ loju rẹ pe ija ti pari laarin oun ati Small Doctor.
Ninu fidio naa la ti ri bi Were Olorin ati Small Doctor se di mọ ara wọn, ti wọn si pari aawọ naa.
Nibẹ si ni Small Doctor ti n ki Portable nilọ pe ko ye pariwo nitori pe oun ko fẹ ariwo rara.
Lẹyin o rẹyin, awọn akọrin takansufe mejeeji di mọ ara wọn , ti ija si pari, bẹẹ naa ni ọtẹ buse pẹlu.















