Wo ìgbésí ayé Pele láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ pẹ̀lú àwòrán

Pele

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Edson Arantes do Nascimento tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Pele, akọni agbabọ́ọ̀lù ti jáde láyé lẹ́ni ọdún méjìlélọ́gọ́rin àmọ́ ipa rẹ̀ nínú eré bọ́ọ̀lù ń tẹ̀síwájú.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Pele ti fi eré bọ́ọ̀lù gbígbá sílẹ̀ láti ọdún 1977, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló gbà pé ọba àwọn agbabọ́ọ̀lù ni Pele tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì fẹ́ràn rẹ̀ gidigidi káàkiri àgbáyé.

Àwọn àwòrán yìí ṣàfihàn ìgbé ayé Pele

Pele

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ní ọjọ́ Kẹtàlélógún. oṣù Kẹwàá. ọdún 1940 ni wọ́n bí Edson Arantes do Nascimento ní ìlú Tres Coracoes ní ẹkùn ìlà oòrùn Brazil.

Kò là kò ṣagbe ni àwọn òbí rẹ̀ tó sì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ láti fi rán àwọn ẹbí rẹ̀ lọ́wọ́.

Pele kò ní owó láti fi ra bọ́ọ̀lù, ìwé ìròyìn ló máa ń fi sínú ìbọ̀sẹ̀ láti fi ṣe bọ́ọ̀lù.

Ọ̀kan lára àwọn ìtàn mánigbàgbé rẹ̀ ni ìgbà tó rí tí bàbá rẹ̀ ń sunkún nígbà tí orílẹ̀ èdè Brazil pàdánù ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé ọdún 1950 sọ́wọ́ Uruguay.

Edson ṣèlérí fún bàbá rẹ̀ nígbà náà pé òun máa gba ife ẹ̀yẹ náà kí inú bàbá òun le dùn.

Pele

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Pele kọ́kọ́ gbá ẹgbẹ́ agbabọ́ọ̀lù Santos lọ́dún 1956 ní ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún.

Lẹ́yìn ọdún méjì ló gbá fún orílẹ̀ èdè Brazil níbi ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé ọdún 1958.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò kópa nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ méjì nínú ìdíje náà, góòlù mẹ́fà ló jẹ fún Brazil láti gba ife ẹ̀yẹ ọdún náà.

Òun ṣì ni ẹni tí ọjọ́ orí rẹ̀ kéré jùlọ tó gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé.

Pele

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àwòrán yìí ń ṣàfihàn bí Pele ṣe ń dìmọ́ àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀, Zito lẹ́yìn tí wọ́n tún gba ife ẹ̀yẹ náà lọ́dún 1962 ní orílẹ̀ èdè Chile.

Pele kò báwọn parí ìdíje náà nítorí pé ó ti fi ẹsẹ̀ ṣèṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ìdíje náà.

Pele

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Pele jẹ góòlù 1,283 láàárín ọdún mẹ́wàá tó bẹ̀rẹ̀ sí ní gbá bọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́.

Níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ kan tó gbá fún ẹgbẹ́ agbabọ́ọ̀lù rẹ̀ lọ́jọ́ kọkàndínlógún oṣù Kẹsàn-án ọdún 1969 ló ti jẹ góòlù 1,000.

Àwọn èrò tó fi mọ́ àwọn akọ̀ròyìn yawọ orí pápá ìṣeré láti gbé Pele kọ́rùn.

Pele

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọdún 1970 ni Pele dé òtéńté nígbà tí Brazil tún gba ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé fún ìgbà kẹta.

Ìgbà náà ni àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ṣàfihàn ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán oní kọ́lọ̀.

Títí di àsìkò yìí, Pele nìkan ni agbabọ́ọ̀lù tó gba ife àgbáyé ní ẹ̀ẹ̀mẹ̀ta.

Pele

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ní ọdún 1971 ni Pele kò gbá bọ́ọ̀lù fún orílẹ̀ èdè Brazil mọ́ tó sì fi gbígbá bọ́ọ̀lù fún àwọn ẹgbẹ́ agbabọ́ọ̀lù náà kalẹ̀ lọ́dún 1977 lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínlógójì.

Ìjọba Brazil kò fi àyè gba Pele láti gbá fún àwọn ẹgbẹ́ agbabọ́ọ̀lù ilẹ̀ Yúróòpù láwọn àsìkò tó fi ń gbá bọ́ọ̀lù ní ojú méjèèjì tí èyí sì ṣe okùnfà ìdí tí kò fi kúrò ní Santos.

Pele

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Pele ti fi eré bọ́ọ̀lù gbígbá sílẹ̀, ó máa ń kópa nínú àwọn ìdíje kọ̀ọ̀kan tó bá jẹ́ àkànṣe.

Ní ọdún 1990 ló gbá bọ́ọ̀lù fún Brazil fún ìṣẹ́jú márùndínláàdọ́ta níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọ̀rẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ tí wọ́n gbá ní London.

Pele

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lẹ́yìn tí Pele fẹ̀yìntì lórí gbígbá bọ́ọ̀lù, òkìkí àti àwọn ipa rẹ̀ kò parẹ́ lórí àṣà.

Ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà kan tó jẹ́ oníṣẹ́ ọnà, Andy Warhol ní Pele wà lára àwọn tó yí ìgbàgbọ́ òun padà dípò níní òkìkí ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún, ìṣẹ́jú sẹ́ńtúrì mẹ́ẹ̀dógún ló ní.

Pele ati Sylvester Stallone

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Pele kò gbìyànjú láti ṣiṣẹ́ gbígba àkóso eré bọ́ọ̀lù àti pé láwọn àsìkò tó ń gbá bọ́ọ̀lù ní ojú méjèèjì, ó ṣe káàkiri àgbáyé.

Bákan náà ló tún kópa nínú eré sinimá àti fíìmù àgbéléwò tó fi mọ́ fíìmù Escape to Victory tí wọ́n ṣe lọ́dún 1981 níbi tí òun àti Sylvester Stallone kékeré ti kópa.

Pele ati Nelson Mandela

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bẹ́ẹ̀ náà ló bá àwọn èèkàn káàkiri àgbáyé ṣe.

Níbi yìí, ó wà pẹ̀lú olórí orílẹ̀ èdè South Africa tẹ́lẹ̀ rí, Nelson Mandela lọ́dún 2007.

Nígbà tí Mandela ń sọ̀rọ̀ nípa Pele, Mandela ní ó máa ń dàbí kí ènìyàn máa wo ògo Ọlọ́run lára ọmọdé ni nígbà tí ènìyàn bá n wo Pele nígbà tó bá ń gbá bọ́ọ̀lù.

Pele

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lílo orúkọ Pele lásán wúlò fún orílẹ̀ èdè náà láti gba àlejò àgbáyé fún ìdíje Olympics lọ́dún 2016.

Nínú àwòrán yìí ni omi ti ń jábọ́ lójú Pele lẹ́yìn ìgbìmọ̀ tó ń rí sí Olympics gbà kí Brazil ṣe agbátẹrù ìdíje náà lọ́dún 2009.

Pele

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìgbésí ayé Pele ní àwọn kùdìẹ̀kudiẹ kan tó fi mọ́ ṣíṣe ìgbéyàwó ní ẹ̀ẹ̀mẹ̀ta àti ọmọ márùn-ún.

Ó tilẹ̀ gbà pé òun kò mọ iye ọmọ tí ó ṣeéṣe kí òun ní síta nítorí àwọn ìbáṣepọ̀ tó ní nígbà èwe.

Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀, Edinho ló jẹ́ agbabọ́ọ̀lù. Àmọ́ Edinho lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n láàárín ọdún 2005 sí ọdún 2019 fẹ́sùn gbígbé egbògi olóró àti ṣíṣe owó kúmọkùmọ.

Pele

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọdún 2012 ni ìlera Pele ti ń mẹ́hẹ lẹ́yìn tó ṣe iṣẹ́ abẹ méjì tí àìsàn kíndìnrín náà sì ń ba fínra.

Ní ọdún 2021 ni àwọn dókítà tún ṣe àwárí àìsàn jẹjẹrẹ ní ara rẹ̀.

Iko agbaboolu Brazil

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nítorí ìlera rẹ̀, Pele kò le lọ sí orílẹ̀ èdè Qatar fún ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé ọdún 2022.

Orí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán ló ti wò ó ní orí ibùsùn ní ilé ìwòsàn.

Àwọn agbabọ́ọ̀lù Brazil gbé àsíá tí wọ́n kọ orúkọ Pele sí dání lẹ́yìn tí wọ́n lu South Korea.