Ìdí mẹ́rin rèé tí ààrẹ Buhari fi kọ̀ lórí gbèndéke gbígba owó Naira àtijọ́...

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Aareͅ Muhammadu Buhari ti salaye idi meͅrin ti oun ko ni fi gboͅ ipe awoͅn eniyan fun ki woͅn sun gbedeke oͅjoͅ ti woͅn yoo deͅkun gbigba owo Naira atijoͅ loͅwoͅ awoͅn eniyan moͅ

Aareͅ Buhari ni kii sͅe ero awoͅn lati fi aye ni awoͅn meͅkunu lara amoͅ awoͅn gbe igbeseͅ naa lati deͅkun iwa ibajeͅ lawujoͅ ni.

O ni bio tileͅ jepe awoͅn eniyan n ke gbajari pe asiko yii lera pupoͅ fun woͅn amoͅ aareͅ ni aigboͅdoͅmase ni ayipada owo naira naa.

Aareͅ orileͅede Naijiria ni o poͅn dandan lasiko yii lati gbe iru igbeseͅ beͅeͅ fun ayipada rere lorileͅede Naijiria.

Agbeͅnusoͅ fun aareͅ, Mallam Garba Shehu lo soͅ beͅeͅ lori idi ti woͅn fi takun pe oͅjoͅ koͅkanleloͅgboͅn, Osu Kini ni yoo jeͅ gbedeke gbigba owo Naira atijoͅ loͅwoͅ awoͅn eniyan.

Aareͅ ni igbese naa kii se lati ni awoͅn meͅkunu lara ti woͅn n sͅe isͅeͅ oojoͅ woͅn amoͅ lati deͅkun iwa ibajeͅ lawujoͅ ati awoͅn ti woͅn ko owo ilu pamoͅ lati luu ni ponpo.

Ijoͅba Buhari wa salaye leͅkunreͅreͅ idi meͅrin ti woͅn fi gbe igbeseͅ naa...

Lilu owo ilu ni ponpo

Ijoͅba aareͅ Buhari ni awoͅn eniyan kan ti lu owo ilu ni ponpo, ti woͅn si ko awoͅn omo yii pamoͅ ni oͅna aitoͅ.

Woͅn ni atunsͅe to bao wo Naira yoo dena kiko owo ilu jeͅ ati kiko owo ilu ti woͅn lu ni ponpo si ile woͅn.

Ayederu owo Naira

Ijoba Naijiria ni iwadii fihan pe oͅpoͅloͅpoͅ ayederu owo ileͅ wa loti kun ileͅ kun ile, ti awoͅn eniyan si n hu iwa ibajeͅ ni idi reͅ

Woͅn ni opoͅlopoͅ awoͅn eniyan ni woͅn n teͅ owo jade ninu yara woͅn, nitori naa oͅna ti woͅn le fi gbogun ti eyi ni lati sͅe atuteͅ owo naira naa.

Gbigba Riba ati ajeͅbanu

Iwa ajeͅbanu peͅlu nkan to woͅpoͅ lorileͅede Naijiria ti awoͅn eniyan n koju, eleyii to ti mu ifaseͅyin ba idagbasoke orileͅede Naijiria.

Ijoͅba ni awoͅn eniyan n lo ipo woͅn lati fi ja orileͅede Naijiria, ti woͅn si n ko owo pamoͅ.

Igbesunmoͅmi

Ijoͅba aareͅ Buhari ni idi miran ti awoͅn fi gbe igbese yiyi owo naira pada ni pe awoͅn agbesunmoͅmi tib a owo naira jeͅ nipa gbigba owo eͅmi loͅwoͅ awoͅn eniyan.

Ijoͅba ni owo ti woͅn rigba loͅwoͅ awoͅn ti woͅn n jigbe ti fun woͅn lagbara si lati maa ji awoͅn eniyan gbe.

Woͅn ayipada owo yii yoo safihan iwa aburu awoͅn ajinigbe naa nitori woͅn a ko owo woͅn jade, eleyii ti ko si ni fun woͅn ni anfaani lati maa ji awoͅn eniyan gbe moͅ nitori owo.

''A ko setan lati ni awoͅn meͅkunnu lara''

Malam Garba Shehu ni aareͅ Buhari mo wi pe nkan lera fun awoͅn oͅmoͅ Naijiria ni asiko yii.

Bakan ni aareͅ moͅ wi pe awoͅn olokowo kekeeke wa ti woͅn ko nilo ati loͅ ile oifowopamoͅsi ki woͅn to le ra oͅja tabi ta oͅja.

Nitorinaa woͅn fi da awoͅn eniyan loju pe ijoͅba yoo gbiyanju lati mu aye roͅrun fun awoͅn eniyan ati pe gbogbo eniyan ni yoo ri owo da pada si apo isuwoͅn woͅn.

Amoͅ ijoͅba ni awoͅn eniyan ko tete koͅbi ara si gbedeke oͅjoͅ ti woͅn yoo deͅkun nina owo titeͅleͅ naa ni ohun gbogbo s.e loͅju poͅ lasiko yii.

Kò sọ́rọ̀ mọ́ lẹ́yìn January 31 tówó náírà àtijọ́ yóò di pàǹtí - Emefiele

New Note

Oríṣun àwòrán, Others

 Banki apapọ orilẹ-edeNaijiria (CBN) ti sọ pe oun ko ni fikun ọjọ ti o kede pe opin yoo de ba nina owo naira atijọ.

Ọdun to kọja ni CBN kede owo igba naira, ẹẹdẹgbẹta naira ati ẹgbẹrun kan naira tuntun to si sọ pe ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kini, ọdun 2023 yii ni opin yoo de ba nina awọn owo naira naa.

 Gomina banki apapọ orilẹ-ede yii (CBN) Godwin Emefiele kede eyi lẹhin ipade Igbimọ awọn alaṣẹ Iṣowo ti banki orilẹ-ede yii (MPC) ni Abuja.

 Godwin Emefielemi ni , iwa ijinigbe ati gbigba owo itusilẹ ti dinku lati igba ti banki apapọ ti kede iwe-owo mẹta ti tun naa.

O tun sọ pe akoko ti a banki apapọ kede lati paarọ awọn owo naira atijọ pẹlu awọn owo naira tuntun ti to fun awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria lati lọ si awọn banki ati lati gba awọn owo naira titun.

Ọpọlọpọ awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ni wọn ti n sọrọ lori bi won yoo se ri owo naira titun mẹtẹẹta naa gba.

Bẹẹ ni banki apapọ orilẹ-ede yii si ti tẹnumọ pe lẹyin ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kinni ọdun yii ni ohun ko ni gba owo naira atijọ mo.

 Laipe yii ni CBN paṣẹ ki awọn banki orilẹ-ede yii dawo sisan wo titun ninu banki ki wọn si ko won sinu ẹrọ ATM ki itankalẹ owo titun naa le pọ si.

 Banki apapọ orilẹ-ede yii tun ṣe eto lati paarọ owo ki gbogbo awọn to wa ni igberiko le ni ore ọfẹ lati paarọ awọn owo ọwọ wọn.

Ile-igbimọ Aṣoju sofin ati Igbimọ awọn Gomina Naijiria ti beere lọwọ CBN lati fa ọjọ naa ṣiwaju lati jẹ ki awọn ọmọ orilẹede Nàìjíríà ri owo tuntun na gba.