Ẹ gbà wá o! Dókítà tó lé ní 2000 ló jápa kúrò ní Naijiria ní ọdún 2022 níkan ṣoṣo! - Ẹgbẹ́ Dokita kígbe!

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹgbẹ awọn dokita lorilẹede Naijiria, NARD ti kegbare lori ọgọọrọ awọn dokita to n kuro lorilẹede Naijiria lọ si okeere laarin ọdun kan.
Aarẹ ẹgbẹ awọn dokita NARD, Orji Innocent ni o kere tan dokita to le ni ẹgbẹrun meji lo kuro ni Naijiria lo si oke okun ni ọdun 2022.
Dokita Innocent ni ti ijọba ko ba tete wa wọrọkọ fi ṣada lori bi awọn dokita ṣe n kuro lọgọọrọ yii nkan a bajẹ ni ẹka eto iwosan.
‘’Ti ẹ ko ba ṣọra, ẹ o ri kan ri pe ko si dokita mọ ni Naijiria ’’
O ni ti ijọba ko ba tete kọ ibi ara si iṣẹlẹ yii, wọn o ji lọjọ kan ti ko si ni si dokita kankan mọ ni Naijiria
Aarẹ ẹgbẹ awọn dokita naa ni iwadii ti awọn ṣe ni Oṣu Kejila, ọdun 2022 fihan be awọn dokita ti japa lai wẹyin wo.
Wọn ni o kere tan aadọta dokita ni wọn n kuro ni Naijiria laarin ọṣẹ kan.
Bakan naa ni wọn wa kesi ijọba lati fikun iye owo ti wọn n la kalẹ fun eto iṣuna ẹka eto ilera ni ọdọọdun.
Dokita Orji Innocent ni awọn nilo ki owo eto iṣuna ajọ naa gbe pẹẹli si pẹlu idamarundinlogun, ki ẹka naa le gbori soke
Ọ̀wọ́ngogo igbéayé ní Naijiria ló mú wa jápa – Awọn dokita fesi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn dokita to jẹ ọjọ iwaju orilẹede Naijiria ni wọn n kuro lorilẹede Naijiria lai wẹyin wo.
Ọwọngogo ounjẹ, epo ati ohun amayedẹrun lo mu ki awọn eniyan faraya, ti wọn si n wa ọna miran lati pese ounjẹ fun awọn ati ẹbi wọn.
Japa to ti jẹ ọrọ to wọpọ laarin awọn ọdọ lo tun mọ si irinajo lọ si oke okun lọna ati wa atije ati atimu fun ara wọn.
Pupọ ninu awọn to n kuro naa ni wọn jẹ onimọ nipa ẹkọ ti wọn ti kọ ni fasiti, ti wọn ko si ri aje jẹun lọpọ ni Naijiria.
Ọpọlọpọ awọn dokita to n lọ si oke okun ni wọn sọrọ lori aisi eto igbayegbadun fun awọn lorilẹede Naijria, eyi lo mu wọn kuro lọgọọrọ.
Ẹka miran ti awọn eniyan tun ti n kuro lọgọọrọ ni ẹka eto ẹkọ, eto ilẹra, imọ ẹrọ ati imọ sayẹnsi.
‘’Iye owo ti mo n gba ni oojọ ni UK ni owo oṣu mi gẹgẹ bi dokita ni Naijiria’’

Dokita Kunle Ibisola to sọ iriri rẹ ni itan oun dabi ti ọpọ ọmọ Naijiria to japa lọ si oke ọkun.
Lati ileewosan UCH Ibadan ni Dr Kunle Ibisola ti kuro lọ si Scotland, ti iyawo ati ọmọ si n bọ laipẹ.
‘’Ko wumi lati kuro ni Naijiria, mo fẹ kọ ẹkọ si, ki n si duro lati fi iṣẹ ti mo kọ ran orilẹede mi lọwọ.’’
‘’Amọ idi ti mo fi kuro ni owo perete ti wọn n san gẹgẹ bi owo osu ati ọwọngogo igbe aye ni Naijiria’’
‘’Iye ti mo n gba gẹgẹ bi owo iṣẹ oojọ kan ni Scotland bayii ni mo n gba ni owo oṣu kan nigba ti mo wa ni Naijiria.’’
‘’Nigba miran wọn ko ni tilẹ san owo osu fun wa fun bi oṣu mẹfa si oṣu mẹsan nitori aibikita ijọba apapọ.’’
O tilẹ ṣeni laanu pe ọpọ agba dokita miran ko lee san owo ileẹkọ awọn ọmọ wọn nitori aisan owo oṣu wọn.’’
‘’Fun awọn to wa ni Naijiria, awọn naa n gbiyanju lati lọ si oke okun fun igbeaye to rọrun’’
Amọ awọn oludije sipo aarẹ lorilẹede Naijiria ni idibo gbogboogbo to n bọ ni Osu Keji, ọdun 2023 ti seleri lati mu eto ọrọ Naijiria to dẹnukọlẹ ji pepe si, ki ohun gbogbo si pada si ipo.












