Femi Falana: Ojú Elzakzaky kan ti fọ́ nítorí àìsí ìtójú tó
Oríṣun àwòrán, Google
Àkọlé àwòrán, Agbẹjọ́rọ̀ fún Elzakzaky, Femi Falana ní ọdún 2015 tí wọn ti wà látìmọ́lé ni wọ́n kò tíì ní ìtọ́jú tó péye.
Ile ẹjọ giga ni Kaduna ti pasẹ ki ijọba ipinlẹ Kaduna fun adari ẹgbẹ Shia lorilẹ-ede Naijiria, Ibrahim Elzakzaky ati iyawo rẹ, Zinat ni eto iwosan to peye.
Adajọ Gideon Kurada pasẹ naa lasiko ti wọn gbo ẹsun onigun mẹjọ ti ijọba ipinlẹ Kaduna fi kan awọn mejeeji pe wọn n daabo bo awọn ọdaran ati awọn apaniyan to n gbogun ti ipinlẹ naa.