Nigeria Police Force: Buhari buwọ́lu ẹkùn iléeṣẹ́ ọlọ́pàá márùn ún tuntun káàkiri Nàìjíríà

Ọga ọlọpaa ati Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter/Nigeria Police Force

Ijọba apapọ ti buwọlu ẹkun ileeṣẹ ọlọpaa marun un tuntun ati tuntun ati ẹka ọtẹlẹmuyẹ meji lorilẹede Naijiria.

Ilu Akure ni ẹkun ti yoo maa ṣamojuto ipinlẹ Ekiti ati Ondo wa, ẹkun to n ṣakoso ipinlẹ Enugu, Anambra ati Ebonyi wa niluu Awka.

Ilu Yenagoa ni ibujoko ẹkun to n mojuto ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Bayelsa ati Rivers wa,.

Ẹkun ileeṣẹ ọlọpaa Maiduguri ni yoo maa ṣakoso ipinlẹ Borno ati Katsina, nigba ti olu ileeṣẹ ọlọpaa Kaduna ti ṣi lọ si ilu Katsina bayii.

Labẹ atunto yii bakan naa, ẹka FIB to wa labẹ ẹka FCIID tẹlẹ ti da duro bayii.

Ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede ti ni ẹka mẹjọ bayii pẹlu afikun ẹka FIB.

Aaarẹ Muhammadu Buhari to tun jẹ alaga ajọ to n ri si ọrọ ileeṣẹ ọlọpaa tun ti pin ẹka ọtẹlẹmuyẹ FCID ṣii.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá dóòlà ẹ̀mí ọmọ ogun orí omi tí wọ́n jígbé ní ìpínlẹ̀ Ondo

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti doola ẹmi ọmọ ologun ori omi, Ajare Uchegbulah Amadi, ti wọn ji gbe ni opopona Ago Ajayai, to wa ni Oba Akoko ni ipinlẹ naa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipilẹ ọhun, Tee-leo Ikoro lo fidi ọrọ naa mulẹ fun BBC.

Ọga ọlọpaa Naijria

Oríṣun àwòrán, "PoliceNG/Twitter

Ikoro ni wọn doola ẹmi ọkunrin naa ni nkan bi ago mẹrin afẹmọju Ọjọru, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu karun un ọdun 2020.

O ni lẹyin ti awọn ọlọpaa bẹrẹ si n tọpinpin awọn ajinigbe naa, ti awọn ajinigbe ọhun si ri pe ko si ibi ti wọn le foju pamọ si mọ ni wọn fi ọkunrin naa silẹ ninu igbo kiji kan to wa laarin ipinlẹ Ondo ati Kogi.

Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Undie Adie, ti wa kilọ fun awọn arinrin ajo lati ṣọra lasiko yii, papa bi ijọba apapọ ṣe gbẹsẹle irinajo lati ipinlẹ kan si omiran.

Ninu atẹjade kan to fi lede fun awọn akọroyin, Adie sọ pe awọn ajinigbe ti n lo asiko yii lati ji ọpọ eeyan gbe lọna ati bere owo gọbọi lọwọ awọn ara ile wọn.

Kọmiṣọna ọhun wa fi da awọn eeyan ipinlẹ naa loju pe ileeṣẹ ọlọpa ko ni dẹkun ati maa foju awọn ọdaran lede.

Lẹyin naa lo rọ awọn eeyan ipinlẹ Ondo lati kan si awọn agbofinro ti wọn ba kofiri afurasi tabi iwa ọdaran kankan lagbegbe wọn ko le rọ awọn ọlọpaa lọrun lati dabo bo wọn.