Coronavirus treatment: Àjọ NAFDAC sọ pé Nàìjíríà kò ní dẹ́kun lílo hydroxychloroquine láti fi tọ́jú coronavirus

Oogun hydroxychloroquine

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọjọ Aje ni ajọ WHO kede pe oun ti da didan hydroxychloroquine duro naa.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Botilẹjẹ wi pe ajọ eto ilera l'agbaye, WHO, ti da didan oogun iba, hydroxychloroquine wo, fun itọju aarun coronavirus, Oludari Agba fun ajọ to n mojuto ṣiṣe oogun ni Naijiria, NAFDAC, Dokita Mojisola Adeyeye sọ pe Naijiria yoo tẹsiwaju lati dan oogun naa wo.

Dokita Adeyeye sọ pe akọsilẹ fihan pe oogun hydroxychloroquine n ṣiṣẹ fun itọju aarun Covid-19 lara awọn to ni i, paapa awọn ti aarun naa ko ti i wọ lara ju boṣeyẹ lọ.

Adeyeye sọ ọrọ yii lẹyin ọjọ diẹ ti kọmisana fun eto ilera nipinlẹ Eko, ti aarun Covid-19 pọ si ju ni Naijiria, Ọjọgbọn Akin Abayomi, sọ pe ipinlẹ naa ti bẹrẹ si ni dan oogun naa wo.

Oludari ajọ NAFDAC, sọ fun ileeṣẹ amogunmaworan TVC pe, "awọn akọsilẹ wa fi dawa loju pe hydroxychloroquine n ṣiṣẹ fun awọn alarun Covid-19.

Nitori naa, ao tẹsiwaju lati danwo ni Naijiria".

Idi ti ajọ WHO fi da didan hydroxychloroquine wo fun igba diẹ

Lọjọ Aje, ajọ WHO da didan oogun naa wo duro, lẹyin ti abọ iwadii kan sọ pe oogun naa le pa awọn alarun Covid-19.

Awọn oluwadi eto ilera lati ajọ Lancet lo ṣe iwadii naa.

Wọn si ṣe laarin ẹgblrun lọna mẹrindinlọgọrun eeyan to ni aarun coronavirus, bi ẹgbẹrun mẹẹdogun si ni wọn lo hydroxychloroquine tabi chloroquine fun.

Iwadii naa si lo fihan pe o ṣeeṣe ki awọn ti wọn lo oogun naa fun ko wa ninu ewu lati ku tabi ni aarun ọkan, ju awọn ti wọn ko lo o fun lọ.

Ṣugbọn Dokita Adeyeye sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo naa pe "oun ko mọ boya akọsilẹ lati ọdọ awọn oyinbo tabi ilẹ Africa ni ajọ WHO ti ri akọsilẹ rẹ.

O sọ pe "oriṣiriṣi nkan lo maa n jẹyọ ti a ba n dan oogun kan wo.

Oogun kii ṣi ṣe iṣẹ bakan naa lara eeyan, koda ki wọn o jẹ ọmọ iya kan naa."

"Nitori naa, akọsilẹ WHO le ri bẹ ẹ, to ba jẹ pe aarin awọn oyinbo ni wọn ti ṣe iwadii wọn.

Mi o lero pe akọsilẹ kankan wa lati ilẹ africa, nitori pe iṣẹda wa yatọ."

Awọn orilẹ-ede miran to n lo hydroxychloroquine

Bi i Naijiria, orilẹ-ede Brazil naa sọ pe awọn ko ni dawọ lilo oogun naa fun awọn ti aarun naa ko fi bẹ ẹ wọ lara, ati awọn to ti ws lara.

Orilẹ-ede Brazil wa lara awọn ti aarun naa fi ọwọ ba ju l'agbaye.

O ti le ni 370,000 eeyan to ti ni Covid-19 nibẹ.

Bakan naa ni Aarẹ ilẹ America, Donald Trump, sọ pe oun n lo oogun naa ki oun o maa ba ko aarun naa.

Ṣugbọn, ajọ to n mojuto ṣiṣe nkan ti ẹnu n jẹ , ati oogun l'orilẹ-ede naa ti kilọ pe ki awọn eeyan o maa lo o.

Àjọ NAFDAC ti pàṣẹ́ pé kí iléèṣẹ́ apòògùn kan ṣe Chloroquine láti fi tọ́jú coronavirus

Ajọ to n mojuto ṣiṣe, lilo ati tita ogun oyinbo ni Naijiria, NAFDAC, ti fun ileeṣẹ apoogun oyinbo kan ni aṣẹ lati ṣe ogun Chloroquine fun itọju coronavirus.

Eyi jẹyọ ninu atẹjade kan ti ọga agba ajọ naa, Ọjọgbọn Christianah Adeyeye fi sita l'oṣu Kẹta.

Adeyeye sọ pe igbesẹ naa waye lẹyin ayẹwo ti awọn onimọ iṣegun oyinbo ṣe lawọn ileewosan kan ni China, ti esi ayẹwo wọn si fihan pe Chloroquine le kapa otutu aya ti aarun Coronavirus ba fa, ti eyi si le ke ẹmi aarun naa kuru.

O sọ pe lootọ ni ajọ naa ti fi ofin de lilo chloroquine fun itọju aisan iba ni Naijiria, ṣugbọn wọn ti n ṣe agbeyẹwo rẹ pada lati fi koju aarun tuntun, coronavirus.

Àkọlé fídíò, Sogidi Lake: Kòṣẹja-kòṣèèyàn lá bá nínú adágún odò náà -Ojedele

Nafdac sọ pe wọn yoo dan ogun chloroquine naa wo lara awọn eniyan to ba ni aarun naa lati le mọ boya yoo ṣiṣẹ fun.

Adeyeye tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe awọn oluwadii ni orilẹ-ede France ati America ti gbiyanju ogun naa fun itọju coronavirus, ti wọn si sọ pe o ṣiṣẹ.

"Ipinlẹ Eko yoo bẹrẹ si ni dan chloroquine wo lati mọ bi yoo ṣe ṣiṣẹ si."

Ṣugbọn ṣa, ajọ NAFDAC gba awọn ara ilu ni imọran pe ki wọn o ma lo ogun chloroquine lai gba imọran lọwọ dokita wọn, nitori aṣilo rẹ le fa inu rirun, ki oju o ma a wo baibia, ori fifọ, ati ara yiyun.

Aṣẹ yii ko tumọ si pe wọn ti bẹrẹ si ni i lo chloroquine fun itọju coronavirus, ṣugbọn wọn ti ṣe ọpọlọpọ ogun naa pamọ lati lo, ti awọn ọpọ eeyan ba ko aarun naa.