Coronavirus survivor: Kòkòrò coronavirus sì wà lára mi títí mo fi kúrò ní ibùdó ìtójú àwọn alárùn covid-19

Àkọlé fídíò, Coronavirus survivor: Àntí Korona ni wọ́n n pè mí l'ádùúgbò láti ìgbà tí mo ti ní Covid-19

Ọkan lara awọn eeyan to ti la ewu ajakalẹ aarun coronavirus nilu Eko, l’orilẹ-ede Naijiria, Motosinoluwa Afolaranmi, sọ iriri rẹ fun BBC News Yoruba.

O ṣalaye pe lati oru ọjọ ti awọn eleto ilera ti wa gbe oun kuro nile, ni awọn eeyan ti mọ pe oun ni aarun naa, nitori pe ẹnikan ya fidio oun lasiko ti wọn wa gbe e, o si fi si ori ayelujara.

O sọ pe igbeaye ko ri bakan naa mọ lati igba ti oun ti pada sile, nitori pe awọn ara adugbo n dẹyẹ si oun.

Bakan naa lo sọ pe ijọba n gbiyanju lori amojuto aarun naa ni Naijiria, ṣugbọn omi ṣi ku lamu.

Ẹkunrẹrẹ ọrọ wa ninu fidio naa.