Ọ̀sìn ewúrẹ́ tí mò n ṣe le mú mi figa-gbága pẹ̀lú àwọn tó n gba owó oṣù

Àkọlé fídíò, Ọ̀sìn ewúrẹ́ tí mò n ṣe le mú mi figa-gbága pẹ̀lú àwọn tó n gba owó oṣù

Dudu Adamu jẹ oniṣowo ewurẹ ni ipinlẹ Jigawa.

O sọ fun BBC pe oun wa lara awọn obinrin ti gomina ipinlẹ naa, Abubakar Badaru, fun ni ewurẹ lati fi maa ṣe ọrọ aje.

O ṣalaye pe abo ewurẹ meji ati obukọ kan ni oun fi bẹrẹ ọsin ẹran, to di agbo ẹran nla bayii.

O sọ pe ọsin ewurẹ naa lo mu ki awọn ọmọ oun ni anfaani lati lọ si ileewe.

Bakan naa lo ni igbagbọ pe gbogbo ibi ti obvinrin ba n de laye ni iṣẹ ọwọ oun yoo gbe oun de.