Nigerians Evacuated from UK: Àyẹ̀wò fihàn pé ọmọ Nàìjíríà 215 láti UK kò ní coronavirus
Idunnu ṣubu layọ fawọn abọde lati ilẹ Gẹẹsi si Naijiria lẹyin ayẹwo fihan pe ko si ẹni to ni aarun coronavirus ninu wọn.
Awọn ọmọ Naijiria naa ti wọn jẹ okoo le lugba o din marun un ni wọn gunlẹ si papakọ ofurufu ilu Eko lọjọ kẹjọ oṣu karun un yii.
Lati ilu Eko ni ijọba ti ko wọn lọ si Abuja nibi ti wọn wa fun iyasọtọ fun ọsẹ meji gẹgẹ bi alakalẹ ajọ eleto ilera lagbaaye, WHO ṣee laa kalẹ.
Agbẹnusọ awọn eeyan naa, Muyiwa Lucas to bawọn akọroyin sọrọ ṣalaye pe ijọba ṣe itọju awọn daadaa ni ibudo iyasọtọ tawọn wọn fun ọsẹ meji l'Abuja.
O ni ohun to dabi iṣoro diẹ ti awọn koju rẹ ni bi ajọ NCDC ko ṣe tete sọ esi ayẹwo tawọn ṣe fun awọn.
O ni awọn ti ṣeto bi awọn yoo ṣe wọ ọkọ ofurufu pada si ilu Eko bayii.
- Alárùn coronavirus 245 ní Nàìjíríà ní àkọsílẹ̀ rẹ̀ lọ́jọ́ Ẹ̀ti
- Àwọn ìbejì Akeugbagold kò le rìn dáadáa mọ́ lẹ́yìn tí wọ́n dáwọn padà
- Àwọn ìbejì Akeugbagold kò le rìn dáadáa mọ́ lẹ́yìn tí wọ́n dáwọn padà
- Àwọn alárùn coronavirus ṣe ìwọ́de ní Gombe, wọ́n ní ìjọba n febi pa wọ́n
- Aláàfin gbé àṣẹ kalẹ̀ láti dènà àtúnṣẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ 'Soka'nílùú Ọ̀yọ̀
- Ṣọ́ọ́ṣì kan sí ìlẹ̀kùn rẹ̀ fún àwọn mùsùlùmí láti kírun Jímọ̀ ní Germany