Africans in China: Ọmọ Naijiria sọ bí wọ́n ṣe lé òun jáde kúrò nílé nítorí ó jẹ́ aláwọ̀dúdú

Àkọlé fídíò, Africans in China: Wọ́n lé mi jáde kúrò nílé nítorí mo jẹ́ ènìyàn dúdú

Ọpọlọpọ awọn ọmọ ilẹ Afrika to wa ni ilẹ China lasiko arun Coronavirus ni wọn sọ iriri idẹyẹsi to sẹlẹ si wọn ni be.

Onisowo lati orilẹede Naijiria lọ si China ni ṣe ni wọn le oun kuro ni inu ile, ti wọn si lọ ti oun mọ ibi kan nitori ayẹwo arun Coronavirus.

Ẹlomiran ni nise ni wọn ti ilẹkun lẹyin ti wọn ko si gba ki awọn jade lẹyin ti ayẹwo fihan pe ohun ko ni arun Coronavirus.

Wọn wa rọ ijọb akaakiri ilẹ Afrika lati wa gbe awọn kuro ni ilẹ China.