Coronavirus: Ṣé ọtí leè dènà tàbí pa àrùn Coronavirus bi?
Oriṣiriṣi ahesọ lo ti n waye nipa awọn ohun to lee pa, tabi dena arun Coronavirus.
Bawọn kan ṣe n sọ pe omi ati iyọ lee dena arun naa, lawọn mii n sọ pe ọti lile bii ogogoro, jẹdi, ṣepẹ ati bẹbẹ lọ lee kapa arun naa.
O jẹ ohun iyalẹnu pe awọn kan ba ara wọn nile iwosan lẹyin ti wọn mu amuju ọti koju aru naa.
BBBC Yoruba sọ oju abẹ niko lori bi ọrọ naa ṣe jẹ.