Coronavirus Cases in Africa:Ojú òpó Facebook Live ni mo ti wo ìsìnkú ìbátan mi

Mourners at Chris' funeral in western Kenya

Oríṣun àwòrán, Mercy Juma

Iwọn ẹsẹ bata mẹta sira ni wọn joko lori aga.Gbogbo eeyan to wa nibẹ lo wọ ibomu.

Gbogbo eeyan lo mọ nipa ilana ijọba Kenya lori isinku lasiko ajakalẹ Coronavirus.

Eeyan mẹẹdogun pere lo kopa ninu isinku ibatan mi, Chris, aago mẹsan owurọ si ni gbogbo eto gbọdọ ti pari.

Nigba ti ago meje yoo fi lu, awa ta ku ti rọ yika ẹrọ alagbeka wa ati ẹrọ kọmputa wa nibi ti a ti n wo isinku naa ti ọrẹ wa kan se alabapin rẹ loju opo Facebook Live.

Ọgọrọ wa la ṣetan lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun Chris. Elero eeyan nii se. Lọpọ igba a ma tan imọlẹ sawọn aaye akojọ to ba wa nibẹ.

Bi o ba rẹrin, ko si ẹni ti ko ni gbọ ohun rẹ koda bo ba wa ni jina jina sibi tẹ wa.

Oloogbe Chris

Oríṣun àwòrán, Courtesy of Mercy Juma

Bẹẹ si ni Chris naa a ma jẹ ipe awọn eeyan lasiko ti wọn ba nilo rẹ.

Bo ba ṣe ni ibi ayẹyẹ igbeyawo ni tabi isinku, Chris yoo ṣa ri pe oun pe awọn eeyan jọ ni sha.

Nitorinaa lọjọ ta n wi yi, awa naa jẹ ipe rẹ lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun un.

Ṣugbọn kini ọhun ko jọ ara wọn tan nitori pe a ko si nibi isinku bo ti se wu wa.

Mercy Juma

'A ko le kọ awọn orin rẹ to fẹran ju'

Ibatan mi ni Chris, inu ile kan naa ni wọn ti tọ wa dagba ti o si sun mọ mi ju ẹgbọn mi lọ.

Ilu Kisumu lo ku si ni iwọ oorun Kenya ni ọjọ Ajinde lẹyin ti aisan jẹjẹrẹ ẹdọ ti da a lagara fun bi ọsẹ melo kan.

Ijọba sọ ilana isinku rẹ fun wa. A gbọdọ sin in laarin ọjọ mẹta.

Wọn gbe oku sinu koto

Oríṣun àwòrán, Courtesy of Mercy Juma

Sugbọn bi iṣede ti ṣe de pupọ ninu awọn mọlẹbi rẹ mọlẹ ni olu ilu Nairobi, gbogbo wa kọ la le lọ si ibi isinku rẹ.

Ṣoki ni ọrọ iwaasu nibi isinku rẹ, wọn o si kọrin pupọ nibẹ.

Chris fẹran orin kikọ. A maa ba wọn lulu ninu ẹgbẹ akọrin ijọ sọọsi rẹ.

O jẹ ohun to fọwọkan eeyan lẹmi pe ko si ẹni to le kọ awọn orin rẹ to fẹran ju nibi isinku rẹ.

Nise ni mo n wo bi awọn ọrẹ ati alabase rẹ ti ṣe n kọ ọrọ nipa rẹ soju opo Facebook Live isinku rẹ.

Ni oju opo ayelujara nise lawọn eeyan n sọ nipa rẹ ti wọn si n fi ọrọ ikẹdun ransẹ.

Loba wa si mi lọkan wi pe, abi ki n tẹ awọn ọrọ yi jade ni ko ba le jẹ ọrọ ikẹdun nitori ko si iwe ta le kọ si.

Gbogbo nkan to n ṣẹlẹ ko jọ bi ti tẹlẹ. A ko le di mọra wa, ko si ẹni to le ri omije ẹni keji bẹẹ ko si ẹni le bu yẹpẹ si ori posi rẹ bi wọn ti ṣe n gbe e sinu saare rẹ.

''Facebook Live ti wọn n se muna lọ nitori naa mi o laanfaani lati wo irinajo ikẹyin Chris de ipari''

Bi a ba padanu ẹni ta fẹran, a maa n wa ọna lati daro wọn, a maa n wa ki eeyan bawa kẹdun ki a si pa ọkan pọ.Sugbọn lasiko ta dejumọle yi, bawo la ti se le se gbogbo wọnyi?

Inu mi ko dun.

Mi o figba kan lero pe maa sin ẹni ti mo fẹran loju opo ayeujara.

Mi o ro wi pe fifọwọ kan eeyan yoo mu mi lọkan bayi. O dabi ere sinima ni amọ emi gaan wa lara awọn to n kopa nibẹ.

Ibanujẹ lo jẹ pe Facebook Live naa muna lọ lojiji nitori aiṣedede nẹtiwọki.

Mi o laanfaani lati wo irinajo ikẹyin Chris de ipari.

Mi o ri bi wọn ti ṣe gbe posi rẹ sinu saare.Ni ilẹ Afrika lọdọ wa nibi, eto isinku jẹ ohun ti ọpọ ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu.

Àkọlé fídíò, Awọn agboku lorilẹede Ghana

O dabi iṣipo pada lati alaye lọ si ipo miran ti a ko mọ nipa rẹ.

Torinaa, a mu ọrọ awọn babanla wa to ti lọ ni pataki.

Bi eeyan ba ku lọdọ wa, a kii fi ọrọ ayẹyẹ ati eto isinku wọn sere rara.

Ni aarin awọn eeyan Luo ati Luhya ti mo ti wa ni iwọ oorun Kenya, ohun pataki ni iku eeyan jẹ ati isinku wọn.

Nipele nipe le leto isinku lọdọ wa

Tọwọtọwọ ni a maa fi n ṣeto isinku ẹni ba lọ.

Gbogbo eto ati ilana laa si maa n tẹle ki irinajo wọn lọ si odi keji ma ba kọsẹ rara.

Akọkọ ibẹ ni pe a kii kanju ṣe eto isinku agaga ti o ba jẹ ti agbalagba.

Isinku lọdọ wa jẹ asiko ayẹyẹ, koda laarin awọn to ba n ṣe idaro ẹni to lọ.

O ma n to ọsẹ kan gbako ti wọn fi n se isinku agbalagba.

Awọn eeyan a ma sunkun, ariwo ma n pọ, awọn eeyan maa n ṣe akojọpọ ti wọn a si ma ba ẹni tọfọ ba ṣe idaro.

Lasiko ta n sọ yii, wọn ma n dana igi tawọn eeyan a si su jọ lati maa sọrọ ẹni to lọ.

Wọn maa n pa ẹran etutu, wọn maa n dana, jijẹ mumu yoo wa rẹpẹtẹ fawọn to wa ba mọlẹbi daro. Akoko ti awọn eeyan maa n se afihan iṣọkan laarin mọlẹbi ati ọrẹ ni isinku maa n jẹ.

Bi isinku ba ku ọjọ kan tabi meji, wọn maa n tẹ oku sita kawọn eeyan ba le fifẹ han si i t'oun ti pe o ti dero ọrun.

Lọdọ awa eeyan Luo, o kere tan eto isinku mẹwaa la maa n ṣe lati fi dagbere ikẹyin fẹni to lọ.

O ṣeni laanu pe lasiko isinku Chris, a ko ribi dimọra wa, a ko ribi sunkun faraya, ko si apejọ awọn eeyan lati ṣe idagbere ikẹyin, ko si eyi ta ri ṣe nibẹ.

Awọn osisẹ ijọba duro digbi ni lati rii pe isinku naa lọ nibamu pẹlu ilana ti wọn la kalẹ.

Nitori eyi, o dabi ẹni pe idaro mi lori iku Chris ko tii pe.

Boya ti gbogbo nkan ba pada sipo, a o laanfani lati tun idaro rẹ sii bo ti ṣe tọ ati bo ti se yẹ.