Coronavirus: updates: ìlú kan rèé l'Abuja tí kò mọ̀ rárá nípa Covid-19

Awọn obinrin Zokutu

Pẹlu bi ijọba orilẹede Naijiria ṣe ko owo lorii fifi awọn ileeṣẹ iroyin polongo nipa bi ajakalẹ arun Coronavirus ṣe n ran to, awọn ilu kereje kereje kan ṣi wa to wa lokunkun nipa arun aṣekupani naa.

Abule Zokutu ko ju bi irin wakati meji fun ọkọ lati aarin gbungbun ilu Abuja nibi ti ikọ amuṣẹya ti aarẹ yan to n ṣiṣẹ ojoojumọ nipa fifun awọn eeyan niroyin nipa Coronavirus wa.

Ṣugbọn awọn olugbe ilu yii ni awọn ko gbọ iroyin daadaa nipa bi arun naa ṣe n ran ati bo ṣe le ṣakoba fun awọn.

O ti le lọgọrun ọjọ bayii ti Naijiria ti ni ẹni akọkọ to ni arun Coronavirus bayii, koda itanka arun naa ti sun ọpọn de awọn ilu igberiko sibẹ, ṣe ni iye rẹ n goke sii lojojumọ.

Akọsilẹ to wa lọwọlọwọ bayii fi han pe o ti le lẹgbẹrun lọna ogun eeyan to ti lugbadi arun naa ti o si ti le ni ẹẹdẹgbẹta to ti gba ibẹ ku ni Naijiria.

Ọna pataki kan ti ijọba n gba fi ọrọ sita lori arun naa ni nipasẹ ẹrọ mohunmaworan, rẹdio ati lori itakun ayelujara.

Ṣugbọn abule Zokutu ko ni ọna to dara, ko si họsibitu koda ko si itakun agbaye lati wo ori ẹrọ ayelujara fun iroyin. Wọn o tun ni ina ọba lati gbọ rẹdio tabi tẹlifisan nipa Coronavirus ati ọna ti ijọba n polongo pe wọn le gba dena rẹ.

Rose Mishayi
Àkọlé àwòrán, Rose Mishayi ni awọn ko mọ bi coronavirus ṣe ri

"Coronavirus yii, awa o mọ nkankan nipa rẹ o ati bo ṣe n ran awọn eeyan. Nibayii a o mọ ẹni ti yoo ṣalaye fun wa nipa rẹ".

Ara ilu naa kan, Mishayi sọ pe "a kan gbọ pe Coronavirus wa ni Naijiria ṣugbọn a o tilẹ mọ ohun to jọ".

Ṣugbọn bi akọroyin BBC ṣebẹwo si ilu naa, ṣe lawọn araalu n ṣe owo tiwọn lọ ni rẹpẹtẹ lai naani lilo ibomu tabi ṣiṣe ijina sira ẹni.

Agbẹ lo wọpọ ni ilu naa wọn si ni awọn ko mọ ohun to n jẹ COVID-19.

Hajara ni ijọba maa n ṣe bii pe awọn ko ṣe pataki.

"Asiko ipolongo idibo nikan. ni ijọba maa n ranti wa bi idibo ba si ti tan, wọn a gbagbe wa". Solomon sọ eyi fun BBC.

Awọn obinrin Zokutu
Àkọlé àwòrán, Awọn araalu ilu Zokutu ko lanfaani si omi to daa

Solomon fi kun un wipe niwọn igba ti awọn wa lokunkun, igberi aisan yii lawọn le wa.

Ẹwẹ, minisita fun iroyin, Lai Muhammed ni awọn ti nawo le ipolongo pẹlu awọn ileeṣẹ iroyin lati da awọn ọmọ Naijiria lẹkọọ.

O ni ida mọkandinlọgọrun ọmọ Naijiria lo ti gbọ.

Awọn obinrin Zokutu n pọn omi

Ṣugbọn ikọ amuṣẹya ti aarẹ yan ni iṣẹ ṣi ku lati jẹ ki awọn eeyan mọ sii paapaa lawọn igberiko.

Awọn ara ilu Zokutu ni awọn ko tii ko firi ẹni kankan ti wọn gbeṣẹ le lọwọ lati maa polongo nipa Coronavirus pẹlu bo ṣi ṣe jẹ pe ẹgbẹ Abuja lawọn wa.