Violence against women: Ìjọba pàṣẹ lọ rọọ́kún nílé fún òṣìṣẹ́ káńsù tó lú obìnrin kan ní ìpínlẹ̀ Ogun nítorí ìséde

Aworan oṣiṣẹ kansu naa

Oríṣun àwòrán, @TeeBaibie

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Wọn ti paṣẹ rọọkun nile fun awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ Ifọ ni ipinlẹ Ogun ti wọn fihan ninu fidio kan to n ja rayinranyin lori ayelujara nibi to ti n lu arabinrin kan lolu ileeṣẹ ijọba ibilẹ naa labẹ awawi pe oun n fi ofin konile o gbele mulẹ nibẹ.

Eeyan kan loju opo twitter, @TeeBaibie lo fi fidio naa sita nibi ti awọn oṣiṣẹ kansu naa ti n gbiyanju ati jo taya ọkọ arabinrin naa lọjọ Satide lagbegbe Ojodu Abiọdun.

Arabinrin naa ni oun ti ṣalaye pe awọn ko mọ pe awọn ti kọja ala ilẹ ipinlẹ Eko wọ ipinlẹ Ogun lasiko naa eleyii to ni awọn oṣiṣẹ kansu naa faake kọri, wọn ko gbọ.

Kii ṣe iroyin mọ pe inira ni fun ọpọ eeyan lati mọ aala laarin ipinlẹ Eko ati Ogun nitori awọn eeyan ti kọle wọnu ara wọn ni ipinlẹ mejeeji.

Bi o tilẹ jẹ wi pe ipinlẹ Eko ti dẹwọ ofin koni o gbele kaakiri gbogbo ọjọ to wa ninu ọsẹ, ofin konile o gbele ṣi n fidi mulẹ ni ipinlẹ Ogun ni ọjọ Abamẹta ati ọjọ Aiku.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Gẹgẹ bi obinrin naa ṣe sọ oun ati ọkọ rẹ ni wọn jumọ jade ni ọjọ naa lati lọ ra awọn nnkan ti wọn yoo lo fun ayẹyẹ ọjọ ibi smọ wọn to n bọ lọna ti wọn fi pade awọn oṣiṣẹ kansu naa.

Amọṣa ọrọ ba ibomiran yọ nigba ti arabinrin naa gbiyanju lati beere ibi ti ileeṣẹ ijọba ibilẹ naa wa lọwọ arakunrin kan ti o pada wa mọ oruks rẹ si Ọgbẹni Peter.

Arakunrin naa lo n tẹle to si n ka nnkan to n ṣẹlẹ silẹ ki o to di wi pe arakunrin Peter naa ṣa dede yii lojiji to si di igbaju ati igbamu fun un.

Ninu atẹjade kan to fi sita, alaga ijọba fidihẹ ni ijọba ibilẹ Ifọ, Họnọrebu Fọla Salami ni iwadii ti bẹrẹ lori ọrọ naa ati pe gbogbo awọn oṣiṣẹ ti ọrọ naa kan lo ti gba aṣẹ lọ rọọkun nile ti wọn ko si ni gba owo oṣu.