Russia ń fún àwọn ọ̀daràn láǹfàní láti lọ jagun ní Ukraine dípò kí wọ́n kojú ilé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Novosibirsk courts administration
- Author, Olga Ivshina
- Role, BBC Russian
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Nnkan bii aago meje owurọ ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2024 ni ọlọpaa de sile Andrey Perlov lagbegbe Novosibirsk, ni Siberia.
O ti kọkọ ji jade laarọ to si jade lati lọ ṣe ere idaraya, eyii lo mu ki ọlọpaa mu lọ sile rẹ fun ayẹwo finifini.
Ẹsun ti wọ fi kan ọkunrin naa ni pe o ji owo ti iye rẹ to $32,000 ni apo ẹgbẹ agbabọọlu kan to jẹ adari rẹ.
Awọn mọlẹbi rẹ sọ pe ohun kan ṣoṣo to ṣe ko ju pe o n gba awọn ọmọde laaye lati gba bọọlu lori papa iṣere naa lai gba owo iwọle lọwọ wọn.
Ṣugbọn awọn to fẹsun kan an sọ pe o gba owo, ti ko si jẹ ki owo naa de ọwọ awọn to alaṣẹ ẹgbẹ agbọọlu ọhun.
Ẹni ọdun mejilelọgọta ni Perlov, o si gba ami ẹyẹ Olympic lọdun 1992 fun irin gbigbe.
O ti wa latimọle bayii fun nnkan bii oṣu mẹfa, awọn mọlẹbi rẹ si sọ pe ijọba n gbogun ti i ko le lọ darapọ mọ awọn ologun to n koju Ukraine.
Wọn ni ijọba ṣeleri fun pe oun yoo wọgile ẹsun ti wọn fi kan an lẹyin ogun naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọmọ afurasi naa, Alina ni “o kọ jalẹ, a si pariwo sita lori awọn iwe iroyin.
“Lẹyin naa ni wọn gbe lọ sinu ahamọ to le koko nibi ti wọn ti pada tun fi ọrọ naa lọ ọ.”
Alina sọ pe lẹyin ti baba oun tun kọ lati lọ darapọ mọ awọn ologun to n koju Ukraine ni wọn ko faye gba a mọ lati ri awọn mọlẹbi rẹ.
Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe ohun to pamọ pe wọn n lo awọn ẹlẹwọn fun ogun Ukraine, awọn iwadii BBC fi han pe awọn ọgara ati ọdaju ọdaran ni wọn n lo tẹlẹ.
Iroyin ni lọwọ yii, awọn agbẹjọrọro ti n sọ fun awọn onibara wọn ti wọn fẹsun kan pe o ṣeeṣe ki wọn lọ jagun kaka ki wọn lọ jẹjọ nile ẹjọ.
A gbọ pe inu oṣu Kẹta ọdun yii ni wọn buwọlu ofin tuntun naa, to n tumọ si pe ẹnikẹni to ba le tọwọ bọwe adehun, ko ni koju ile ẹjọ lẹyin to ba daran tan, wọn yoo si fa iwe ẹsun rẹ ya lẹyin ti ogun Russia ati Ukraine ba pari.
Amọ igbesẹ naa ti doju eto idajọ Russia bolẹ gẹgẹ bi ohun to Olga Romanova, to jẹ ajafẹ ọmọniyan kan sọ.
O ni “Ni bayii, ọlọpaa le mu eeyan lori oku to ṣẹṣẹ pa, wọn maa fi ṣẹkẹṣẹkẹ mu lọwọ, ti ọdaran naa yoo si sọ pe ẹ woo, mo yan lati lọ jagun, wọn yoo si pa iwe ẹṣun ipaniya naa rẹ lẹsẹkẹsẹ.”

Oríṣun àwòrán, Vera Salnitskaya
Ọwọ ileeṣẹ wa tẹ fọran ohun kan ti wọn ka silẹ nibi ti agbẹjọro kan n ti n sọ anfani to wa ninu ki ọdaran tọwọ bọwe adehun ogun dipo ko lọ jẹjọ.
Ẹni ti wọn n sọrọ rẹ ninu fọran naa ni wọn ti kọkọ ran lẹwọn ọdun mẹta.
Ohun ti a gbọ ninu fọran naa ni pe “O le sẹwọn ọdun mẹfa mii fun ẹsun miran yii, mo ba jiroro lori bo ṣe maa tọwọ bọwe adehun ogun, ti wọn ba gba adehun rẹ wọle, yoo lọ jagun, wọn yoo si fa iwe ẹsun rẹ ya.”

Oríṣun àwòrán, Lipavsky family vk.com
Yaroslav Lipavsky lọ darapọ awọn ologun lẹyin to yan lati ṣe bẹẹ dipo ko koju ile ẹjọ.
Lẹyin ọjọ meji to darapọ mọ ologun ni wọn ran lọ si Ukraine, o si pade iku rẹ lẹyin ọsẹ kan nibẹ.
Iroyin ni ọmọ ọdun mejidinlogun pere ni Yaroslav Lipavsky, oyun si wa ninu ọrẹbinrinrẹ.

Oríṣun àwòrán, 72.ru Iryna Sharova
Nigba ti ileeṣẹ ajagunta, Wagner kọkọ n gba awọn ẹlẹwọn siṣẹ, adari rẹ, to ti doloogbe bayii, Yevgeny Prigozhin n mu awọn ẹlẹwọn lati ọgba ẹwọn ti wọn n ko awọn ọdaju arufin si.
Iwadii BBC ti mu ki a ri bi wọn ẹ n ko awọn ẹlẹwọn naa siṣẹ ologun ati ohun to maa n ṣẹlẹ lẹyin iku wọn.

Oríṣun àwòrán, Sergey Vologin family archive/ @jungerbahmut telegram
Ileeṣẹ iroyin BBC kan si ijọba Russia lori ọrọ Andrey Perlov, ati pe ṣe lootọ ni wọn n gbogun ti i lati lọ darapọ mọ awọn ologun to n koju Russia, ijọba naa kọ lati fesi si awọn ibere wa.












