Ìpè pàjáwìrì sí BBC dóòlà ẹ̀mí obìnrin mẹ́fà tó há sínú ọkọ̀ yìnyín

Oríṣun àwòrán, Supplied to BBC
- Author, By Khue B Luu
- Role, BBC News Vietnamese, London
Olupẹjọ ọmọ orilẹede Faranse fidi rẹ mulẹ pe awakọ akẹru naa ti kọkọ duro lọna nibi ti o ti pe ileeṣẹ ọlọpaa nigba lẹyin to gbọ ohun awọn eeyan.
Olupẹjọ ni awakọ naa ko mọ bo ya oun ti ṣe ohun to lodi si ofin.
Ileeṣẹ ti awakọ naa ba a ṣiṣẹ ti sọ fun wa pe awakọ naa ṣe iranwọ fawọn ọlọpaa pẹlu bi o ṣe dahun awọn ibeere wọn ti o si tun fi ohun silẹ.
Wọn fi awakọ naa silẹ lai fi ẹsun kankan kan an, o si tẹsiwaju irinajo rẹ.
Awọn obinrin mẹfa kan ti bọ lọwọ iku ojiji lẹyin ti ileeṣẹ iroyin BBC ṣagbateru bi awọn ọlọpaa ṣe ṣawari ọkọ onifiiriiji ti wọn wa ninu rẹ lorilẹ ede Faranse.
Awọn obinrin naa ti mẹrin ninu wọn jẹ ọmọ orilẹ ede Vietnam ti awọn meji to ku Si wa lati Iraq lo ha sinu ẹrọ amunkan tutu to wa lẹyin ọkọ akẹru kan nibi ti wọn ko ti mi daadaa mọ.
Ọkan lara wọn lo pe BBC lori ago lati inu ọkọ ọhun.
Lẹyin naa ni BBC sọ fawọn ọlọpaa ti awọn ọlọpaa si ṣe awari ọkọ naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Faranse sọ fun BBC pe awọn ti fọrọ wa awakọ naa lẹnu wo.
Ipe pajawiri
"Ni ọsan Ọjọru ni atẹjiṣẹ kan wọle sori foonu mi eyi to sọ pe " awọn eeyan kan ti gbá ibo orilẹ ede Faranse kọja sí ilẹ Gẹẹsi pẹlú ọkọ amunkan tutu.
Ko pẹ rẹ ni mo gba ipe kan eyi ti ẹni to pe n beere pe ṣe mo wa ni ilẹ Yuroopu?
Ẹni to pe mi naa bẹbẹ lohun rara pe ki n ṣe iranwọ fun oun ni kiakia.
Bayii ni mo rántí bi oru ṣe pa awọn ọmọ orilẹ ede Vietnam mọkandinlogoji ṣe ku sẹyin ọkọ tirela kan lọdun 2019 ni Essex
Awọn eeyan kan lo fẹ fi wọn ṣe owo.
Mi gbiyanju lati béèrè ibeere kan tabi méjì lọwọ ẹni to pe mi naa.
Ohun ti mo ṣa gbọ ni pe awọn eeyan mẹfa kan há sinu fìrííjìì lẹyin ọkọ akẹru.
Ko sí ẹni to mọ nọmba ọkọ naa, ibi to wa ati ibi to n lọ.
Ọdọbínrin kan tẹ atẹjiṣẹ sí mi lati inu ọkọ naa to ko ọgẹdẹ.
O ni irin nla ni wọn fi ti ilẹkùn ọkọ naa pa.
Fidio awọn obinrin to ha sinu fìrííjìì ọkọ akẹru
Fidio kan ṣafihan inu ọkọ akẹru ti ẹru kun inu rẹ, ati aye diẹ tàwọn to wa ninu rẹ jokoo sí.
Níbẹ ni ọkan lara wọn ti wukọ, o ni oun ko le mi daadaa mọ ni ede Oyinbo.
Obìnrin naa sọ fun mi pe awọn ti lo bíi wakati mẹwaa lẹyin ọkọ naa, ati pe ẹru bẹrẹ sí ni ba awọn lẹyin ti wọn ri pe awakọ naa ti morile ọna ibo miiran.
Lọgan ni kan sí awọn akẹgbẹ mi ni BBC ti wọn n gbe ni orilẹ ede Faranse ati akoroyin iwe iroyin Le Monde niluu London eleyii to sọ fun akẹgbẹ tiẹ naa niluu Paris eyi to mọ nipa wiwọle ati jijade awọn eeyan lati orilẹ ede kan sí omiiran.
Bí a ṣe ṣ'awari ọkọ naa
Obìnrin to bá mi sọrọ lanfaani lati sọ fun pẹlu ẹrọ GPS to wa lori foonu rẹ ibi ti wọn wa gan an eleyii to jẹ ki n ri ọkọ naa loju popo E15 lẹba Dracé ni ariwa ilu Lyon.
Bayii ni mo sọ fun akẹgbẹ mi lorilẹ ede Faranse pe ki a kan sí agọ olopaa to sun mọ ibi ti ọkọ naa wa.
Ṣadeedee ni a o mọ ibi ti wọn wa mọ
Ṣadeedee ni n ko ri ọkọ naa mọ lori foonu mi
Sugbọn obinrin yii sí n ti atẹjiṣẹ ranṣẹ sí mi.
O sọ pe wọn ti pa ẹrọ amule tutu, eleyii to jẹ ko nira lati mi.
Mo gbiyanju lati rọ wọn pe ki wọn sí máa rọju pe awọn ọlọpaa maa to de ibi ti wọn wa.
Lẹyin ti a tí jọ sọrọ diẹ, mẹta ninu awọn obinrin naa kọ lati wa pẹlu rẹ, mi o mọ idi ti wọn fi ṣe bẹẹ.
Amọ, wọn ya fọto nọmba ọkọ akẹru naa.
Bayii ni mo tun ṣe bẹrẹ sí ni ri ibi ti ọkọ naa wa.
Awọn ọlọpaa to wa ni ẹkun Rhone sọ fun wa pe awọn ti mọ ibi ti ọkọ naa wa, awọn si ti n fọrọ wa awakọ naa lẹnu wo.
Awọn obinrin mẹrin orilẹ ede Vietnam to wa ninu ọkọ naa jẹwọ pe awọn eeyan kan ṣèlérí lati gbe awọn lọ sí ilẹ Gẹẹsi ni.
Ọkan ti temi balẹ pe nkan kan kó le ṣe wọn.
Lẹyin naa iwadii fihan pe lati orilẹ ede Lithuania ni ọkọ naa ti n bọ.
Amọ, mi o le sọ pato ohun to sí n mu mi ranti iṣẹlẹ awọn eeyan mọkandinlogoji to ku sẹyin tirela nigba ti wọn n kọja ni ibode.














