Wo àwọn kókó ìpàdé láàrín ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC pẹ̀lú TUC, tó ń mú àwọn ọmọ Nàìjíríà wòye pé ìjà ti tán

Aworan Joe Ajaero ati Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

Ijọba apapọ ṣe ipade pọ pẹlu ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati TUC niluu Abuja lọjọ Aiku lori awuyewuye to jẹyọ lori bi ijọba ti yọ owo iranwọ ori epo bẹntiroolu kuro.

Wọnyii ni awọn koko ti wọn sọrọ le lori nibi ipade naa gẹgẹ bi minisita eto iroyin ati ilanilọyẹ, Mallam Mohammed Idris ṣe ṣalaye ninu atẹjade to fi sita:

i. Ijọba apapọ kede ẹgbẹrun mẹẹdọgbọn naira agẹgẹ bi owo iranwọ fun gbogbo oṣiṣẹ fun oṣu mẹfa na.

ii. Ijọba tun ileri ṣe lori ati pese bọọsi CNG to yoo maa gbe awọn eeyan ni ẹdinwo lati le koju iṣoro ọwọngogo owo ọkọ lati igba ti ijọba ti yọ owo iranwọ ori epo bẹntiroolu kuro.

iii. Ijọba apapọ tun ṣeleri lati pese owo fawọn oniṣowo kekeke nibi ipade naa.

iv. Bakan naa ni ijọba apapọ tun kede nibi ipade ọhun pe oun ti yọ owo ori VAT kuro lori epo disu fun oṣu mẹfa na.

v. Ijọba apapọ tun kede pe oun yoo bẹrẹ si ni san N25,000 loṣooṣu fun idile fun miliọnu mẹẹdogun fun oṣu mẹta eleyii ti yoo bẹrẹ lati oṣu Kẹwaa yii titi di oṣu Kejila.

Ipinnu ijọba ati ẹgbẹ oṣiṣẹ lẹyin ipade

i. Ijọba apapọ ati ẹgbẹ oṣisẹ NLC ati TUC pinnu nibi ipade wọn wi pe gbogbo ọrọ ti wọn jọ sọ papọ le niyanju nigba tawọn oṣiṣẹ ba wa nibi iṣẹ ti wọn ko gunle iyanṣẹlodi.

ii. Ẹgbẹ oṣiṣẹ pe fun alekun owo oṣu sii, awọn aṣoju ijọba nibi ipade naa si ṣeleri lati sọ ẹbẹ wọn fun Aarẹ Bola Tinubu fun agbeyẹwo.

iii. Ijọba yoo gbe igbimọ kan dide lati ṣiṣẹ lori imuṣẹ ileri ijọba pẹlu ati maye dẹrun fawọn araalu latari iyọkuro owo iranwọ ori epo bẹntiroolu.

iv. Ohun miiran ti wọn tun fẹnuko le lori ni ọrọ aawọ awọn ẹgbẹ onimọto roodu(RTEAN) ati nọṣọna(NURTW) nipinlẹ Eko eleyii ti wọn sọ pe o fẹ amojuto ni kiakia.

Gomina Babajide Sanwo-Olu ipinlẹ Eko to kopa ninu ipade ọhun pẹlu ẹrọ agbọrọkaye ṣeleri lati yabnju ọrọ naa.

v. Ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati TUC yoo ṣe agbeyẹwo ohun ti ijọba apapọ pinnu lati ṣe, wọn si le da iyanṣẹlodi ti wọn fẹ gunle duro lati le tubọ fikun lukun pẹlu ijọba sii.

Gbogbo òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ ni yóò jẹ àǹfàní N25,000 àfikún owó oṣù tí Tinubu kéde – iléeṣẹ́ ààrẹ Nàìjíríà

Olori awọn oṣisẹ nile iṣẹ aarẹ lorilẹede Naijiria, Femi Gbajabiamila ti kede pe gbogbo oṣiṣẹ ijọba apapọ ni yoo jẹ anfani ẹgbẹrun mẹẹdọgbọn naira owo iranwọ ti Aarẹ Bola Tinubu kede ninu ọrọ apilẹkọ to bawọn ọmọ Naijiria sọ lati ṣe ayajọ ọdun kẹtalelọgọta ti orilẹede Naijiria gba ominira.

Tinubu kede owo iranwọ yii fawọn oṣiṣẹ latari ọwọngogo nkan lẹyin ti ijọba yọ owo iranwọ ori owo epo bẹntiroolu.

Gbajabiamila sẹ ikede yii nileeṣẹ aarẹ lọjọ Aiku lẹyin ti aarẹ Tinubu ti kọkọ kede owo iranwọ naa fawọn oṣiṣẹ ijọba onipo kekeke nikan tẹlẹ.

'Ohun ti awọn ọmọ Naijiria n sọ lori ayelujara nipa ẹkunwo naa lo mu igbesẹ tuntun yii jade'

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

‘’Nigba tawọn eeyan bẹrẹ si ni sọrọ lori ẹrọ ayelujara X ti ọpọ mọ si Twitter tẹlẹ ni a tete sọ fun aarẹ ohun tawọn eeyan n sọ.

Lọgan naa si ni Tinubu paṣẹ wi pe gbogbo oṣiṣẹ ijọba apapọ ni yoo jẹ anfani owo iranwọ naa.

Ko si ohun to n jẹ awọn oṣiṣẹ to n gbowo to kere tabi to pọ, oṣiṣẹ ni oṣiṣẹ n jẹ.

Mo ni gbagbọ pe awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ yoo semẹdọ bayii, wọn o si fagile iyanṣẹlodi ti wọn fẹ gunle lọjọ kẹta oṣu kẹwaa,’’ Gbajabiamila lo sọ bẹẹ.

Ijọba apapọ ṣe ikede yii lẹyin ipade to waye laarin ijọba ati awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati TUC lati rawọ ẹbẹ si wọn pe ki wọn ma gunle iyanṣẹlodi ti wọn fẹ bẹrẹ lọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹta oṣu kẹwaa yii.

Awọn minisita mii naa wa nibi ipade ọhun to waye niluu Abuja lọjọ Aiku.

Lọjọ Iṣẹgun to kọja lawọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati TUC kede pe awọn yoo gunle iyanṣẹlodi ọlọjọ pipẹ lọjọ kẹta oṣu kẹwaa nitori owo iranwọ ori epo ti ijọba yọ.

Ipade laarin ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati TUC si n lọ lọwọ lori akitiyan ijọba lati ri pe ẹgbẹ oṣiṣẹ ko da iṣẹ silẹ lọjọ Iṣẹgun.