Ìwádìí fihàn pé Emefiele lo ayédèrú ìbuwọ́lù Buhari àti Mustapha gba $6.2m jáde láti CBN - EFCC

Aworan Godwin Emefiele

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ajẹbanu ti sọ pe iṣẹ iwadii fihan pe gomina banki apapọ Naijiria, CBN tẹlẹ ri, Godwin Emefiele fi ayederu ibuwọlu aarẹ ana, Muhammadu Buhari ati ti akọwe ijọba apapọ tẹlẹ ri, Boss Mustapha gba $6.2m jade lati banki CBN.

Bamaiyi Haruna Mairiga to jẹ onimọ nipa iwe kikọ silẹ to n ṣiṣẹ pọ pẹlu ajọ EFCC lo fidi ọrọ yii mulẹ nibi to ti n jẹri nile ẹjọ ni Ọjọbọ niluu Abuja nibi igbẹjọ ẹsun iwa ajẹbanu ti wọn kan Emefiele.

Ọgbẹni Mairiga ṣalaye pe ẹri to daju wa pe ayederu ibuwọlu lo wa ninu iwe ti Emefiele fi gbowo jade lati CBN.

O tun fidi rẹ mulẹ pe ibuwọlu to wa lori iwe ti gomina banki CBN tẹlẹ ri fi gbowo jade yatọ si ibuwọlu Buhari gan an ati ti Mustapha.

Ẹri iwe mejeeji ti wọn sọ pe wọn fi sanwo fáwọn onwoye ibo lati ilẹ okeere ni wọn gbe si iwaju adajọ Hamza Muazu ni Ọjọbọ.

Mairiga ni iwadii akọṣẹmọṣẹ mii yatọ si oun tun fidi rẹ mulẹ pe ayederu ibuwọlu Buhari ati Mustapha lo wa lori iwe ti Emefiele fi gbowo jade ni banki CBN.

Nigba ti agbẹjọro Emefiele, Matthew Bukaa(SAN) n fi ọrọ wa Mairiga lẹnu wo, Mairiga ni iṣẹ ti EFCC gbe foun loun ṣe wi pe oun ko tiẹ mọ idi ti Emefiele fi n jẹjọ gan an nile ẹjọ.

Ti ẹ o ba gbagbe, ṣaaju ni ijọba apapọ kọwe s'awọn ajọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ Interpol pe oun n wa ọmọ Naijiria mẹta lori ẹsun pe wọn gbìmọ pọ pẹlu Emefiele ṣe ayederu ibuwọlu aarẹ ana, Buhari ati Mustapha to jẹ akọwe ijọba apapọ tẹlẹ.

Ijọba ni owo to le ni miliọnu mẹfa owo dọla ni wọn fi ayederu ibuwọlu gba jade lati banki CBN.

Ìjọba képe ọlọ́pàá Interpol láti mú afurasí mẹ́ta tó lo ayédèrú ìbuwọ́lù Buhari gba ₦9bn ní CBN

Interpol

Oríṣun àwòrán, Interpol

Ìjọba Nàìjíríà ti ta ọlọpaa Interpol lólobó láti bá àwọn nawọ́ gán àwọn afurasí mẹ́ta kan tí wọ́n ṣe àdàmọ̀dì òǹtẹ̀ ààrẹ àná ní Náíjíríà, Muhammadu Buhari láti fi gba owó tùùlù jáde ní akoto owó ilé ìfowópamọ́ àgbà Nàìjíríà, CBN.

Ìwé àkọránṣẹ́ kan tí ìjọba kọ sí Interpol ni wọ́n ti ní àwọn afurasí náà tún ṣe àdàmọ̀dì òǹtẹ̀ akọ̀wé ìjọba sí ààrẹ Buhari nígbà náà, boss Mustapha láti gba owó $6.23m ní CBN.

Àwọn afurasí náà gẹ́gẹ́ bí lẹ́tà ọ̀hún ni Odoh Ocheme, tó jẹ́ òṣìṣẹ́ CBN, Adamu Abubakar àti Imam Abubakar.

Olùwádìí pàtàkì kan tí ààrẹ Bola Tinubu gbà láti ṣèwádìí àwọn ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́ tí wọ́n fi kan gómìnà àná fún ilé ìfowópamọ́ CBN, Godwin Emefiele ló kọ lẹ́tà náà sí Interpol gba ọ́fíìsì ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà.

Wọ́n ní ìwádìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Odoh Ocheme, ẹni tó ti na pápá bora báyìí àti àwọn méjì yòókù náà gbìmọ̀ pọ̀ láti jí owó tó tó bílíọ̀nù mẹ́sàn-án náírà látara ṣiṣẹ́ ayédèrú ìwé kan èyí tí wọ́n ní Buhari ló buwọ́lu ìwé náà.

Lẹ́tà náà ṣàfihàn pé ìjọba Nàìjíríà ní àwọn ti ṣetán láti ka ẹ̀sùn mẹ́fà sáwọn ènìyàn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà lọ́rùn nílé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wà ní Abuja àmọ́ tí àwọn ènìyàn náà ti na pápá bora.

Ẹ̀wẹ̀, Adájọ́ Inyang Ekwo ti ilé ẹjọ́ gíga Abuja ti gbé àṣẹ kalẹ̀ lọ́jọ́ Kejìdínlógún oṣù Kìíní ọdún 2024 pé kí wọ́n fi òfin gbé àwọn afurasí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà.

Godwin Emefiele ló ti ń kojú ìgbẹ́jọ́ ní ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wà ní Maitama fẹ́sùn ṣíṣe owó ìlú báṣubàṣu èyí tí ìjọba àpapọ̀ fi kàn-án.

''Buhari kọ́ ló buwọ́lu N9bn táwọn kan gbà láti CBN fi sanwó fáwọn ònwòye ètò ìdìbò''

Akọwe ijọba apapọ orilẹede Naijiria tẹlẹ ri, Boss Mustapha ti sọ pe iwe aṣẹ ayederu lawọn eeyan kan lo lati gba owo to le ni biliọnu mẹsan an naira jade lati banki apapọ Naijiria, CBN lati sanwo fawọn onwoye eto idibo ilẹ okeere loṣu Keji ọdun 2023.

Ọgbẹni Mustapha fidi ọrọ yii mulẹ gẹgẹ bi ẹlẹri nibi igbẹjọ gomina CBN tẹlẹ, Godwin Emefiele ni ile ẹjọ giga to wa niluu Abuja lọjọ Iṣẹgun.

Ni ọjọ kẹjọ oṣu Keji ni ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ajẹbanu fẹsun kan Emefiele pe o gbimọ pọ pẹlu ọkunrin kan, Odoh Ocheme to ti salọ bayii, lati gba biliọnu mẹsan naira jade lati banki CBN eyi ti wọn sọ pe akọwe ijọba apapọ lo beere fun owo ọhun pẹlu lẹta to ni ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kinni ọdun 2023 lori.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹwẹ, ni ọjọ Aje ni ẹlẹri akọkọ, Onyeka Ogbu ṣalaye bi gomina CBN tẹlẹ ri ti paṣẹ pe ki banki apapọ CBN san owo to le ni biliọnu mẹsan an naira fawọn onwoye eto idibo gbogbo Naijiria lọdun 2023.

Lẹyin naa ni Ogbu to jẹ igbakeji ọgagba adari awọn ẹka banki ni CBN ṣiṣẹ lori ati gbe ọhun jade.

Nigba ti o n sọrọ niwaju ile ẹjọ giga niluu Abuja, Mustapha ni ko si ẹni to buwọlu iwe kankan lati gbe owo naa jade ninu oun ati aarẹ Muhammadu Buhari nigba naa.

O ni oun o tiẹ gba owo kankan yala lati CBN tabi ẹnikan.

‘’Ni gbogbo asiko ti mo fi jẹ akọwe ijọba apapọ, mi o fi oju gan an ni iwe ti wọn ni Buhari buwọlu lati gba owo naa jade lati banki apapọ CBN.

Mo le sọ pe pẹlu akoko ti mo fi jẹ akọwe ijọba orilẹede Naijiria, tii ṣe ọdun marun un ati oṣu meje, Buhari kọ lo buwọlu iwe naa.

Idi akọkọ ni pe lẹta to ba ni ami aarẹ Naijiria kii ni nọmba mọ.

Ẹkeji ni pe mo ti wo lẹta naa, mo si ti kaa, kii ṣe lẹta ni igbimọ alaṣẹ ijọba maa n lo lati fi igbesẹ ijọba ranṣẹ,'' Mustapha lo sọ bẹẹ.

Mustapha ko si ohun to kan ijọba apapọ pẹlu sisan owo fawọn onwoye eto idibo lati ilẹ okeere.