Nǹkan tó le fa irú èsúkè tó sọ Sisi Quadri di èrò iléèwòsàn kó tó kú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Muktar Oyebamiji to jẹ ọkan lara awọn aburo gbajumọ oṣere ati adẹrinpoṣonu to di oloogbe, Tolani Quadri Oyebamiji, ti ọpọ tun mọ si Sisi Quadri, ṣalaye fun BBC Yoruba pe esuke lo bẹrẹ si ni i ṣe oloogbe naa lera-lera ti awọn fi gbe e lọ sile iwosan.
Ọgbẹni Muktar sọ pe ni ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keji ni awọn pe, Quadri ṣubu nibi to ti n ṣere itage lọwọ. Eyi to mu ki ẹbi rẹ lọ ọ gbe wa sile.
"A si gbe wọn lọ sile iwosan, wọn si sọ pe aisan iba ni wọn ni, eyi ti wọn ṣe itọju wọn nibẹ."
Muktar fidi rẹ mulẹ pe ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji ni Sisi Quadri jade kuro nile iwosan lẹyin to gba itọju tan.
Yatọ si aisan iba ti Sisi Quadri ni, aburo rẹ ọhun tun sọ fun BBC pe o ni aisan ọgbẹ inu amọ wọn n tọju rẹ.
Aburo oloogbe naa ṣalaye pe lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keji, ni oloogbe ṣadeedee bẹrẹ si ni ṣe esuke lera-lera.
"Nigba ti esuke naa ko duro ni dokita ile iwosan ti a gbe wọn lọ sọ pe ki a maa lọ ile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun fasiti LAUTECH niluu Ogbomoso.
Fun ra rẹ naa lo fi ẹsẹ rin wọ ile iwosan LAUTECH nibi ti o ti pada jade laye."
Kinni a n pe ni esuke?
Gẹgẹ bi awọn akọṣẹmọṣẹ dokita oniṣegun ṣe ṣalaye, esuke maa n ṣẹlẹ nigba ti iṣan to so ẹdọ-foro mọ aya ba ṣadeedee kako, ti eeyan si n mi gule gule.
Awọn dokita ni esuke le ṣadeedee ṣẹlẹ si eeyan, o ṣi tun le ṣẹlẹ ni asiko ti eeyan ba n mu ọti, jẹun tabi mu siga lọwọ.
Esuke maa n saba lọ fun ra rẹ ni, amọ, ti o ba ti n ju wakati bi meloo kan lọ, tabi ti o ti n to ọjọ meji, aisan kan to wa ninu ara lo maa n ṣaba ṣe okunfa iru esuke bẹẹ.
"Esuke le jẹ apẹẹrẹ arun rọparọsẹ"
Dokita Diana Greene-Chandos to jẹ onimọ nipa itọju ọpọlọ nile ẹkọ giga fasiti Ohio l'Amerika sọ pe ti eeyan ba n se esuke lera lera, o le jẹ apẹẹrẹ pe ẹni naa fẹ ẹ ni aarun rọparọsẹ.
O ni esuke naa le l'agbara de bi wi pe, wọn maa ni lati gbe iru ẹni bẹẹ lọ si wọọdu ti wọn ti n fun awọn alaisan ni itọju pajawiri.
Dokita Greene-Chandos ṣalaye pe iru ẹni ti o ba ṣe esuke yii maa ri pe aya n dun oun, pajapaja n mu un ni gbogbo ara ati pe ẹni naa ko tun ni riran daadaa.
O ni irufẹ esuke yii maa n lagbara gan an, to si nii ṣe pẹlu aarun rọparọsẹ to maa n ṣakoba fun ẹgbẹ kan ninu ọpọlọ.
Kinni o n fa esuke lile?
Awọn onimọ ìṣẹgun fidi rẹ mulẹ pe esuke to l'agbara ko fi bẹẹ wọpọ.
Wọn ni o maa n ṣoro lati mọ ohun to ṣe okunfa esuke gan an.
- Amọ, wọn ni lara awọn nnkan to maa n ṣe okunfa iru esuke yii ni ṣiṣe aniyan tabi awọn to ba ti ni aarun ọpọlọ ri.
- Bakan naa, awọn to ba ti ṣe iṣẹ abẹ ni ikun ri maa n ṣe esuke to l'agbara.
- Awọn dokita onimọ ìṣẹgun tun sọ pe awọn to ba ni aarun inu ẹdọ tabi ikun naa le ni irufẹ esuke yii.
- Oyun nini ati aarun jẹjẹrẹ to fi mọ ọti amupara naa maa n fa esuke lile.
- Aarun inu egungun ogooro ẹyin ati otutu aya naa n fa esuke lile.
Njẹ esuke le ṣekupa eeyan?
Awọn dokita onimọ ìṣẹgun sọ pe esuke lile le sọ eeyan di ero ile iwosan, amọ, wọn ni ko wọpọ rara pe o le pa eeyan.
Wọn sọ pe esuke lile le ṣẹlẹ nigba ti ẹmi ba ti fẹ bọ lara eeyan, amọ, aisan to ti wa ninu ara lo maa n ṣe okunfa eleyii.
Wọn fidi rẹ mulẹ pe o le jẹ oogun ti eeyan lo lasiko to ṣe aisan lo gb'ọwọ odi ti o si di esuke.
Kinni ọna abayọ si esuke?
Awọn dokita ṣalaye pe ti esuke ba ti n ju ọjọ meji lọ, onitọun ni lati lọ ile iwosan ni kiakia lati ri dokita.
Wọn ni ti esuke ba ti n ṣe eeyan lera-lera, yala lasiko ti o n jẹun tabi sun lọwọ, o yẹ kí ẹni naa gba ile iwosan lọ ki o to di nnkan nla.
Wọn ni dokita lo le ṣe oniruuru ayẹwo lati mọ ohun ti o ṣe okunfa esuke lile naa.
Awọn dokita ni esuke le dawọ duro nigba ti eeyan ba ti gba itọju lori aisan to n fa a.















