Ẹrù tí mo tẹ̀lé ló kó mi yọ nínú ìjàmbá tó pa ọ̀gá mi Wigwe àti àwọn mìí - Olusola Faleye

HERBERT WIGWE

Oríṣun àwòrán, HERBERT WIGWE/TWITTER

Olusola Faleye, to jẹ amugbalẹgbẹ ọga aga agba ile ifowopamọ Access Holdings to di oloogbe, Herbert Wigwe, ti tu pẹrẹpẹrẹ ọrọ lori bi ori ṣe ko o yọ ninu ijamba ọkọ ofurufu to pa ọga rẹ ati iyawo, pẹlu ọmọ rẹ.

Faleye lo ṣalaye ọrọ naa nibi ayẹyẹ iyẹsi ikẹyin ti awọn ọlọla ilu kan ṣe fun oloogbe naa niluu Eko.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, o ni oun ko ni anfaani lati wọ ọkọ ofurufu ti oloogbe naa ti pade iku nitori pe ẹru wọn ko le gba ọkọ naa.

O ni eyi lo mu ki oun wọ ayọkọlẹ pẹlu ẹru naa lati lọ ba wọn nibi ti wọn n lọ.

Ọjọ kẹsan an, oṣu Keji, ọdun 2024 ni ijamba ọkọ ofurufu ọhun waye ni orilẹ-ede America.

Ki lo ṣẹlẹ ṣsaju ijamba ọkọ ofurufu naa?

Lati Naijiria ni Wigwe, iyawo rẹ Chizoba ati ọmọ rẹ ọkunrin, Chizzy, Faleye ati Abimbola ti rinrinajo lọ siluu London, ti wọn si gba ibẹ lọ siluu Palms Springs, ni California, ni America.

Ọgbẹni Faleye sọ pe oun ranti pe nigba ti awọn wa loju ofurufu, oun beere lọwọ rẹ pe ṣe o rọrun fun un lati fo ninu ọkọ ẹlikọpita loru ọganjọ.

"Esi ti ọga fun mi ni pe ko si iyọnu, nitori Amercia la wa, wọn si ni ẹrọ igbalode to le riran daadaa ninu okunkun.”

Faleye sọ siwaju si pe ọkọ meji lo n duro de awọn ni papakọ ofurufu.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

O ni ẹyọkan gbe oloogbe naa ati awọn ẹbi rẹ lọ sidi ẹlikọpita nigba ti ọkọ keji yoo ko ẹru wọn lọ ba wọn nibi ti wọn n lọ nitori wọn ko le ko ẹru naa sinu ọkọ ẹlikọpita.

O ni oun wa wo pe ko ni tọ ki oun ba wọn wọ ọkọ ẹlikọpita ṣugbọn ki ẹru wọn ma tete de ibi ti wọn n lọ.

Faleye ni oun wa sọ fun Wigwe pe oun yoo rinrinajo naa pẹlu ọkọ lori ilẹ pẹlu ẹru wọn, eyi ti oun yoo wa ko ba wọn nibẹ, ti ọga oun si sọ pe ko buru.

“Mo lọ ba a, mo sọ fun pe, ọga, mo ro pe yoo dara ki n tẹle ọkọ pẹlu awọn ẹru yii lati wa gbe wọn ba yin, o ni odaa, ko buru.

“Mo wa ni ki Ọlọrun maa ṣọ wọn.”

Tani Herbert Wigwe?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Wigwe to ti fi igba kan jẹ igbakeji ọga agba banki Access, pada di ọga lọdun 2014 lẹyin ti oludokowo pọ rẹ, Aigboje Aig-Imoukhuede fi ipo naa silẹ lọdun 2014.

Ọdun 1966 ni wọn bi Herbert Onyewumbu Wigwe, niluu Port Harcourt, nipinlẹ rivers.

O gba oye imọ ijinlẹ akọkọ ninu iṣiro owo lati University of Naijiria, to w ani Nsukka nipinlẹ Enugu lọdun 1987.

O gba iwe ẹri keji ninu imọ nipa eto ile ifowopamọ ati iṣuna lọdun 1991, ni University College of North Wales, nipasẹ ẹkọ ọfẹ ti ijọba ilẹ Britain.

Lẹyin naa lo kawe nipa akoso ọrọ aje ni Fasiti ilu London.

Wigwe bẹrẹ iṣẹ oluṣiri owo nileeṣẹ Coopers & Lybrand, ko to o darapọ mọ ile ifowopamọ Guaranty Trust Bank nibi to ti ṣiṣẹ fun ọpọlọpọ ọdun.

Lọdun 2002, Ọgbẹni Wigwe ati ẹni ti wọn jọ n dokowo pọ, Aigbpje Aig-Imoukhuede, ra Access Bank.

Laarin ọdun 2002 si 2017, banki naa kuro ni ipo karundinlaadọrin ni Naijiria, si ipo kẹrin laarin awọn banki to tobi julọ.

Orukọ iyawo Wigwe ni Chizoba, wọn si bi ọmọ mẹrin funra wọn.