'Òfin tí NAFDAC fi de ọtí inú ọ̀rá ti kóbá fàájì àti ọrọ̀ ajé wa'

Àkọlé fídíò,
Awọn ọti inu ọra

Oṣu Keji, ọdun 2024, ni ajọ to n mojuto nnkan jijẹ ati oogun ni Naijiria, NAFDAC, kede pe oun ti fi ofin de ṣiṣe, tita ati minu awọn ọti ti wọn n ṣe sinu ọra pelebe ati ike.

Awọn alaṣẹ ajọ naa sọ pe igbesẹ naa waye nitori ipa ti awọn ọti naa n ni lara ilera araalu ati ayika.

Lootọ ni Nafdac sọ awọn ewu to rọ mọ ọ, amọ ero araalu ṣe ọtọọtọ lori eyi, paapaa awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ to n ṣe wọn, awọn to n ta a , ati awọn to n mu u.

Ifọrwanilẹnuwo ti BBC ṣe pẹlu awọn oniṣowo to n ta awọn ọti naa ti ọpọ mọ si pẹlẹbẹ, fihan pe inu awọn eeyan naa ko dun si igbesẹ ajọ ọhun rara.

Ọgbẹni Michael Fatokun to jẹ ẹnikan to fẹran lati ma a mu awọn ọti pelebe naa sọ pe ipa kekere kọ lo ni lara awọn to n mu.

O ni nitori pe iye ti wọn n ta awọn ọti kekeeke naa ko wọn, o mu ko rọrun fun awọn lati ra fun faaji ara wọn, ati fun ẹlomiran.

“Kii ṣe gbogbo eeyan lo ni owo lati ra ọti beer.

Arabinrin to jẹ oniṣowo awọn ọti yii sọ pe lati igba ti ajọ Nafdac ti kede pe oun fi ofin de awọn ọti naa, ni ko ti yá lori igba mọ.

“Ojoojumọ ni mo ma n ra a fun tita, amọ lati igba ti wọn ti fi ofin de e, tita rẹ ko ya daadaa mọ.

Ẹlomiran, to jẹ oniṣowo, Damilola sọ pe oun rọ ajọ naa lati da awọn ọti naa pada sori igba, nitori pe tita rẹ ni oun fi n gbọ bukaata ẹbi oun

Oniṣẹ ọwọ kan to jẹ kafinta, Monsuru Ganiyu, sọ pe mimu awọn ọti naa ma n jẹ ki iṣẹ oun lọ daadaa. O ni koda, o ma n pa ironu rẹ.

Alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ TUC, nipinlẹ Ogun, ọgbẹni Akeem Lasisi, sọ pe fifi ofin de awọn ọti inu ọra pelebe ati ike, yoo mu ki awọn eeyan ma a mu awọn oogun oloro.

“Igbesẹ ti Nafdac gbe yoo mu ki awọn eeyan ma a mu awọn nnkan ti ijọba ko fi ọwọ si.”

Ninu ọrọ tiẹ, ọmọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọti, ẹka ti ilu Ota nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Afolabi Wahab sọ fun BBC pe ko din ni ẹgbẹrun kan aabọ oṣiṣẹ to padanu iṣẹ wọn nileeṣẹ ti oun ti n ṣiṣẹ lẹyin ikede naa.