Wo àwọn orílẹ̀-èdè tó lówó àti èyí tó tòṣì jùlọ ní Afrika

Oríṣun àwòrán, getty images
Ọpọ eeyan lo gbagbọ pe ilẹ Afrika lo toṣi julọ laarin awọn akẹgbẹ rẹ lagbaye.
Eyi ko ṣẹyin eto ọrọ aje to dẹnu kọlẹ, ogun abẹle, bi nnkan ko ṣe lọ deede fun awọn olugbe ilẹ naa ati bi awọn eeyan rẹ ṣe n fi ilu silẹ lọ si orilẹ-ede miran.
Wayi o, ajọ IMF ti kede orukọ awon orilẹ-ede to lowo ati awọn to toṣi julọ ni Afrika.
Awọn orilẹ-ede marun un to lọrọ julọ ni Afrika.
1. Mauritius
Mauritius ni orilẹ-ede to lọrọ julọ ni Afrika latari bi ọrọ aje rẹ ṣe gbooro, to si ni ọpọ awọn ileeṣẹ nla nla.
2. Libya
Bo tilẹ jẹ pe orilẹ-ede naa koju ogun ati iṣoro ọrọ aje lawọn ọdun diẹ sẹyin, oun ni orilẹ-ede keji to lọrọ julọ ni Afrika.
Eporọbi ni Libya fi n ṣe ọrọ aje.
3. Botswana
Okuta iyebiye diamond ni Botswana fi n ṣe ọrọ aje, o si tun ko ọpọ owo si ẹka eto ọrọ aje rẹ, o tun n fi wo to n ri nibẹ gbọ bukata araalu.
4. Gabon
Lara awọn ohun alumọni to wa ni Gabon ni epo, ati awọn nnkan mii to n di owo fun orilẹ-ede ọhun.
Iroyin ni ijọba orilẹ-ede naa tọju nnkan alumọni rẹ daadaa lo mu ko wa ni ipo kẹrin ni Afrika.
5. Egypt
Lara awọn nnkan ti Egypt fi ṣe ọrọ aje ni irinajo afẹ, iṣẹ ọgbin ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Awọn orilẹ-ede to toṣi julọ ni Afrika ree
1. South Sudan
Ọdun 2011 ni South Sudan gba ominira, o si ti fi igba kan jẹ orilẹ-ede to kere julọ lagbaye.
Ogun abẹle atawọn ohun amayedẹrun ti orilẹ-ede naa ko ni lo sọ ọ di ero ẹyin lawujọ akẹgbẹ rẹ.
2. Burundi
Orilẹ-ede kekere ni Burundi ni ila oorun Afrika, o si ti dojukọ oniruuru iṣoro ni ẹka eto ọrọ aje rẹ.
Bo tilẹ jẹ pe ida ọgọrin (80%) awọn olugbẹ rẹ lo n ṣiṣẹ agbẹ, airi ounjẹ jẹ ṣi n ba orilẹ-ede ọhun finra lnitori bi wọn ṣe n bi ọmọ rẹpẹtẹ.
3. Central African republic
Lọwọ yii, iṣoro ọrọ oṣelu ati ikọlu awọn ẹgbẹ ajijagbara lo n ba CAR finra.
Gbogbo nnkan lo ti di ọwọngogo nibẹ latari ogun to waye ni Ukraine, bẹe naa ni orilẹ-ede ọhun n dojukọ iṣoro ọgbẹlẹ.
4. Democratric Republic of Congo
Pupọ eeyan to n gbe ni DRC lo n gbe ninu isẹ ati oṣi.
Ọpọ eeyan orilẹ-ede ọhun ni ko ri ounjẹ jẹ, nigba ti pupọ ninu wọn ko ni anfaani si eto ilera ati eto ẹkọ to ye koro.
Sibẹsibẹ, ṣe ni wọn n bi ọmọ bẹrẹ.
5. Mozambique
Lara awọn iṣoro ti Mozambique ni, ni oriṣiriṣi ajakalẹ aarun, bi awọn araalu ṣe n bimọ leralera ati awọn ere oko ti so daadaa.














