Ilé ẹjọ́ fi afurasí mẹ́tàlá tó pa Ọba Segun Aremu sí ẹ̀wọ̀n

Oríṣun àwòrán, JOHN ADEWOYE
Ile ẹjọ Majisireeti kan niluu Ilọrin, ni ipinlẹ Kwara ti fi afurasi mẹtala to lọwọ ninu iku Olukoro ti ilu Koro, ajagunfẹhinti Segun Arẹmu.
Ijọba ibilẹ Ekiti, ni ilu Koro wa, ni ipinlẹ Kwara.
Eyi waye nibi igbẹjọ to waye ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ karun-un, oṣu Kẹta, ọdun 2024.
Ẹsun ipaniyan ati ijinigbe ni ileeṣẹ ọlọpaa fi kan awọn afurasi naa.
Awọn afurasi naa ni Godwin Jacob, Olowofela Oyebanji, Adefalolu Ayodele, Tewasie Francis, Babatunde Samuel, Godwin Joseph ati Issa Mumee.
Aṣoju ileeṣẹ ọlọpaa to ko wọn wa sile ẹjọ sọ pe, ẹnikan ti orukọ rẹ n jẹ Aremu Simon Adeyemi, lo fi ọrọ iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti, nipa iku Ọba Aremu.
Ọwọ ọlọpaa tẹ wọn ni ọjọ kẹtala, oṣu Keji, ọdun 2024 lẹyin ti ọwọ palaba awọn ọdaran ọhun sẹgi.
“Arakunrin Aremu ṣalaye fun awọn ọlọpaa pe, niṣe ni awọn afurasi ọhun na imọ si oun, ti wọn si paṣẹ fun pe ko tẹle wọn.
“Eyi waye lẹyin ti ọkunrin naa koju wọn, lasiko to kiyesi irin wọn ni ayika ọmọ-ọmọ rẹ ọkunrin.
“O sọ pe ọmọ-ọmọ oun raaye gba ẹnu ọna ẹyinkule ile salọ, amọ awọn afurasi ọhun pa kabiesi, ti wọn si tun gbe iyawo rẹ ati ẹlomiran salọ.
Adajọ agba to n gbọ ẹjọ naa, Monisola Kamson ni ki awọn afurasi ọhun tẹsiwaju lati wa ni ọgba ẹwọn Okekura titi di ọjọ ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹta, ti wọn yo tun pada sile ẹjọ.
Awọn to ku ni Miracle Solomon, Abraham Kehinde, Muhammed Bello, Muhammed Muhammed, Ahmadu Umaru ati Muhammed Dankai.
Gẹgẹ bii iwe ẹsun awọn ọlọpaa, awọn afurasi yi n gbe ni adugbo ọtọọtọ ni ijọba ibilẹ Ekiti.
Ohun to ṣẹlẹ sẹyin

Ọjọbọ, ọjọ kinni, oṣu Keji, ọdun 2024, ni awọn agbebọn yawọ ilu Koro, ti wọn si yinbọn pa ọba alaye ilu na, ki wọn to tun ji iyawo rẹ ati awọn mii gbe lọ.
Ọkan lara awọn agba ilu naa, Taiwo Atọlagbe ṣalaye pe nkan bi aago mejọ alẹ ni awọn ajinigbe ọhun yabọ aafin.
Ọgbeni Atọlagbe tun fi idiẹ mulẹ pe, awọn ajinigbe naa tun ji olori kabiyesi ti wọn pa ati eyaan meji mi.
Lẹyin ọjọ diẹ ni wọn beere ọgọrun-un miliọnu Naira fun itusilẹ awọn ti wọn ji gbe.
Pasitọ kan, Adeyemi Simon Aremu, ti o jẹ ọmọ ọdun metalelọgọrin to moribọ lọwọ awọn ajinigbe to ṣekupa ọba ilu Koro nipinlẹ ṣalaye ohun ti oju rẹ ri.
Ni alẹ ọjọ kiini, osu Keji, ọdun 2024, ni awọn ajinigbe yawọ ilu Koro ni ìjọba ibilẹ Ekiti ni ipinlẹ Kwara, wọn seku pa Ọbalaye ilu naa, Ọgagun fẹyinti Segun Aremu, wọn si tun ji Olori Iyabo Aremu ati ọmọbìnrin kan gbé lọ.
Pasitọ Aremu sọ wi pe oun n jẹun alẹ lọwọ ni awọn gende mẹfa wọle pẹlu ibọn lọwọ ti wọn si ni ki oun ka lọ.
O ni bi wọn ṣe n mu oun lọ ni wọn ri Olori labẹ igi ọsan, ti wọn si pa awa mejeji pọ ati ọmọbinrin kan ti wọn n pe ni Fẹranmi gba inu igbo lọ.
"Nise ni ibọn n ro ti ẹru si n bawa, igba ti mi o ni okun mọ lati tẹsiwaju, wọn bẹrẹ si n wọ mi nilẹ titi a fi de ibikan ti wọn ti ni ki gbogbo wa doju bolẹ.
Ni aafin Onikoro ti ilu Koro, awọn olugbe ilu naa fidi ẹ mulẹ pe, ko si ẹni to le salaye idi ti wọn fi pa Kabiesi, wọn ni ṣe ni awọn ba Kabiesi ninu agbara ẹjẹ lagbala nibi ti o ti n mu ohun mimu ẹlẹrin dodo.












