Iléẹjọ́ sọ afurasí tó ṣekúpa Ọba aládé méjì sẹ́wọ̀n nílùú Ekiti

Aworan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti gbe ọkan lara awọn ajinigbe to ṣekupa Ọba alade meji niluu Ekiti lọ si ile ẹjọ.

Bubuga Lede, ẹni ọdun mẹdọgbọn ni ileẹjọ Magistrate ni ko lọ ma gba atẹgun lọgba ẹwọn Ado Ekiti fun ọgbọn-ọjọ, to si tun sun igbẹjọ si oṣu kẹrin.

Aṣoju ileeṣẹ ọlọpaa ni ileẹjọ, Insipẹtọ Osuolale Yomi sọ fun Ileẹjọ pe afurasi naa ni iwadi fihan pe o lọwọ ninu sise iku pa Ọba David Babatunde ati Ọba Samuel Olatunde Ishola.

Bakan naa lo tun fẹsun kan pe o gbiyanju lati ji Ọba Samuel Adebayo Fatoba ati Bamidele Ibikunle Joseph, to jẹ awakọ gbe lọ.

O ni ofin orilẹede Naijiria ko fi aye silẹ fun irufẹ iwa bayii paapa labẹ ofin to dirọ iwa ọdaran.

O ni ọwọ tẹ afurasi naa ni agbegbe Ikole-Ekiti lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kinni ọdun 2024 pẹlu awọn ohun ija oloro.

Agbẹjọrọ afurasi naa ni Olusoji Oladele.

Adajọ O.F. Bamidele wa palasẹ pe ki wọn fi afurasi naa sọgba ẹwọn Ado Ekiti fun ọgbọn ọjọ titi amọran yoo fi wa lati DPP, to si tun sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹrin ọdun 2024.

Ki lo sẹlẹ saaju?

Awon ori ade meji lawọn agbebon naa sekupa nigbati wọn n pada bọ lati ipade lobaloba ti wọn lọ ṣe niluu Irele-Ekiti.

Awon Ọba meji naa ni, Onimojo ti Imojo Ekiti, Oba Olatunde Samuel Olusola ati Elesun ti Esun Ekiti, Oba David Babatunde Ogunsola.

Amọ, ori ko Oba Adebayo Fatoba ni Ori-Ade kẹta, Alara ti Ara–Ekiti, yọ ninu ikọlu ibi naa.

Awọn igbimọ lọba lọba nipinlẹ Ekiti ti rọ ijọba apapọ ati ti ipinlẹ lati fun wọn ni aṣẹ lati le maa daabo bo agbegbe wọn lati iṣẹlẹ ijinigbe to ṣẹlẹ lera wọn.

Ọba Ayorinde Ilori, Olojudo ti Ido-Ekiti to tun jẹ Alaga fun gbogbo awọn Ọba nipinlẹ Ekiti tun kepe ijọba lati ṣe ifilọlẹ ọlọpaa ipinlẹ lati koju iṣoro eto abo to mẹhẹ nipinlẹ naa.

Ọrọ yii lo waye lakoko ti awọn lọba lọba ṣe ipade pọ pẹlu Gomina Abiodun Oyebanji ati awọn ẹsọ alaabo gbogbo nipinlẹ Ekiti ninu oṣu kinni.