Ìdí rèé tí àjọ ECOWAS fi gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tó fi de Niger, Mali, Burkina Faso àti Guinea

Oríṣun àwòrán, GETTY IMAGES
Ajọ iṣọkan iwọ-oorun ilẹ Afrika, ECOWAS ti gbẹsẹ kuro lori ofin ti wọn fi de orileede Niger, Mali, Burkina Faso ati Guinea lẹyin awọn ologun gba ijọba lawọn orilẹede naa.
Ọjọ Abamẹta to kọja yii ni ajọ naa gbe gege yii kuro nibi ipade awọn agbaagba orileede to wa labẹ ECOWAS ṣe ni olu-ilu Naijiria to wea niluu Abuja.
ECOWAS sọ nibẹ pe awọn ti le pe awọn orileede mẹrin yii wa sibi ipade wọn lori ọrọ eto aabo ati alaafia.
Gege ti wọn gbe lori awọn mẹrin yii tẹlẹ ni pe awọn orileede yooku ko nii ba wọn dowopọ yala lẹka eto irin ajo, okoowo tabi eto ọrọ aje.
Bakan naa ni ajọ yii tun sọ pe awọn yoo pe fun itusilẹ aarẹ ilkẹ Niger ti wọn rọ loye, Mohamed Bazaoum, ẹni ti wọn lo ṣi wa ninu igbekun awọn ẹṣọ ologun orileede naa.
ECOWAS gbe gege lori awọn orileede wọnyi, lẹyin ti awọn ẹṣọ ologun gbajọba kuro lọwọ awọn alakoso to wa nibẹ tẹlẹ.
Lara awọn gege ti wọn tun gbe le awọn orileede wọnyi ni titi awọn ẹnubode to wọn awọn orileede naa, gige ina mọnamọna to wọnu Niger ati awọn ohun to nii ṣe pẹlu eto ọrọ aje miran
Ni nnkan bi ọsẹ meloo kan sẹyin, Niger, Mali ati Burkina Faso ti kede pe awọn ti yọ ara awọn kuro ninu ajọ ECOWAS lẹyin ti fẹsun kan ajọ naa pe wọn gbe gege lori eto ọrọ aje awọn.
Lara awọn ohun ti ajọ naa sọ pe o fa ti awọn fi gege ọhun kuro ni;
Aawẹ
Idi pataki akọkọ ti ajọ ECOWAS fi gbe gege ọhun kuro ni pe gbogbo awọn Kristiẹni ni wọn n gba aawẹ lọwọ, eyi ti wọn pe ni lẹnti (Lent), ti awọn Musulumi naa si ti n wọnu oṣu aawẹ wọn ti wọn pe ni Ramadaani (Ramadan).
Ninu ọrọ wọn ti wọn sọ nibẹ, wọn ni: “Ajọ yii ti woye nipa asiko aawẹ awọn Kristiẹni ti a mọ si lẹnti, ati bi oṣu Ramadaani tun ṣe n wọle de.”
Aawẹ jẹ asiko kan ti awọn eeyan nilo irufẹ awọn ounjẹ kan to le ṣe ara wọn loore nipa ilera pipe.
Sibẹ, ni asiko yii, ẹkunwo ti wa lori awọn ounjẹ kan pẹlu bi awọn eeyan ṣe n beere fun un ni gbogbo igba.
Ikaanu ara ẹni
Ni afikun si ti aawẹ yii, ajọ ECOWAS tun ni imọlara fun awọn idi ti wọn fi gbe awọn gege yii kuro lori awọn orileede mẹrẹẹrin naa.
Ati pe, gege ti wọn gbe lori awọn orileede ọhun ti jẹ ki pupọ awọn ounjẹ gbowo lori.
Bakan naa, bi orileede Naijiria ṣe ja ina mọnamọna ti wọn fun Niger danu ti sọ ọpọ agbegbe lorileede naa sinu okunkun biribiri
Ohun to ṣẹlẹ yii si fa akabo fun awọn olokoowo to si mu ifasẹyin ba eto ọrọ aje, eyi to mu ki awọn ti owo diẹdiẹ n wọle si lọwọ tẹlẹ maa sunkun, nitori nnkan ko lọ deede mọ.
Ajọ naa sọ pe gege ti wọn gbe lori awọn orileede yii yoo ṣakoba fun iṣẹ eto aabo to n lọ lọwọ lawọn ẹkun iwọ oorun ilẹ Afrika kaakiri.
“Bi awọn orileede yii ṣe yọwọ kuro ninu ajọ yii yoo ṣakoba fun iṣẹ eto aabo ati ifọwọsọwọ nipa bi nnkan ṣe n lọ lati mojuto eto aabo ati gbigbogun awọn agbebọn aṣekapani lawọn ẹkun yii.
“Awọn bii ilana eto aabo ilu Accra ati iranwọ eto aabo agbaye (International Security Assistance Force).” atẹjade naa sọ
Latigba ti iditẹgbajọba ọhun ti waye, ipenija aisi eto aabo ti wa lekun sii lawọn orileede yii.
Bi wọn ṣe n kọlu awọn ẹṣọ ologun ti wa n peleke sii ni Mali ati Niger, eyi to n fa iku awọn ologun ati araalu.
Ọpọ awọn ajọ ati awọn eeyan ni wọn ti n pe ajọ ECOWAS lati gbe gege naa kuro lori awọn orileede wọnyi.
Koda, lọsẹ to kọja, aarẹ ologun tẹlẹri lorileede Naijiria, Ọgagun Yakubu Gowon to jẹ ẹnikan to ṣẹku ninu awọn olodasilẹ ajọ ECOWAS pe awọn alakoso ajọ naa lati gbe gege yii kuro lori awọn orileede naa.
Niger ba ara rẹ ninu iṣoro yii lẹyin ti awọn ologun gbajọba lọwọ iṣakoso Mohamed Bazoum ninu oṣu keje, ọdun to kọja.
Fun igba pipẹ, awọn amoye ti pe awọn adari ajọ yii lati ṣọra wọn, ki wọn si farabalẹ si ohun ti gbogbo ọmọ ẹgbẹ naa ba n fẹ.
Bo tilẹ jẹ pe awọn alakoso ECOWAS duro lori igbesẹ wọn lai sọ ohunkohun lori awọn orileede ti wọn ko tẹle eto oṣelu awa-ara-wa, sibẹ Ọjọgbọn Jibrin Ibrahim sọ fun BBC pe kii ṣe ijakulẹ bi wọn ba duro, niwọn igba to ba jẹ pe lati mu erongba wọn ṣẹ ni.
Ọpọ awọn olugbe orileede Niger ni wọn ti n sunkun nipa bi iṣoro ṣe ba igbe aye wọn nipa awọn ẹnubode ti wọn tipa lẹyin iditẹ-gbajọba.
Awọn ọlọja ati olokoowo ti fi owo kun iye ti wọn n ta awọn ọja wọn, ti wọn si n sọ pe titi ẹnubode pa latari iditẹ-gbajọba lo fa a.
Ọpọ awọn olugbe ilu Yamai lo n sọ pe bi owo ọja ṣe gbowo lori lasiko yii ko ṣẹlẹ ri, ti wọn ko si ri iru rẹ ri.















