Mọ̀lẹ́bí kéde ètò ìsìnkú Herbert Wigwe, ìyàwó àti ọmọ rẹ tó ku nínú ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú

Oríṣun àwòrán, Herbert Wigwe
Idile oloogbe Herbert Wigwe to jẹ ọga agba ileeṣẹ Access Holdings ti kede eto isinku ilumọọka olokoowo naa.
Ọjọ mẹfa ni eto isinku yi yoo fi waye ki wọn to sìn oku wọn.
Ṣaaju ni Wigwe kagbako iku ninu ijamba ọkọ ofurufu elikopta to waye ni orileede America.
Wigwe, iyawo rẹ ọmọ wọn Chizi ati awọn eeyan mii lo wa ninu baalu to ja lulẹ ọhun.
Ninu wọn ni Abimbola Ogunbanjo adari Nigerian Exchange Group tẹlẹ wa.
Ileeṣẹ iroyin Naijiria nii The Cable jabọ wi pe eto isinku yoo bẹrẹ pẹlu eto ayẹsi ikẹyin ti yoo waye ni Eko Hotel lọjọ Kẹrin oṣu Kẹrin.
Lọjọ Kẹwa oṣu Kẹrin ni asekagba yoo waye ni ile ijọsin RCCG Lion of Judah Parish ni Isiokpo, ijọba ibilẹ Ikwerre ni Rivers.
Laarin ọjọ Kẹrin sí ikẹwa ti wọn yoo kasẹ eto nilẹ awọn eto miran yoo waye.

Oríṣun àwòrán, X/Herbert Wigwe
Igbimọ to n risi irinajo lorilẹede Amẹrika, US National Transportation Safety Board ti salaye pe awọn eeyan ipinlẹ California rí bí ọkọ baalu to n ko ọmọ Naijiria mẹta ṣe gbina, ko to di pe o gba ẹmi wọn,
Awọn to wa ninu ọkọ naa ni Ọga agba fun ile ifowopamọ Access Bank, Herbert Wigwe, iyawo, ọmọ rẹ ati Ọga tẹlẹri fun NGX, Abimbola Ogunbajo, ti wọn si ti jade laye.
Ọkọ baalu Airbus EC 130B4 pẹlu nọmba idanimọ N130CZ ni ijamba ni agbegbe Halloran Springs ni California lọjọ kẹsan an ọdun 2024, to si mu Awakọ ati akẹgbẹ rẹ lọ.
Gẹgẹ NTBS ṣe salaye, awọn osojumikoro sọ pe ni ọjọ ti iṣẹlẹ naa sẹlẹ, oju ọjọ rí bí adapọ ojo ati iyi.
"Gẹgẹ bii awọn agbofinro ṣe salaye, ọpọ awọn osojumikoro to n rìn irinajo nínu ọkọ pe nọmba ipe pajawiri 911 lati pe akiyesi wọn si iṣẹlẹ naa.
"Awọn Osojumikoro sọ pe oju ọjọ ko dara, ti ojo ati iyi sì dapọ." Iwadii salaye.
NTSB tẹsiwaju pe gbogbo ẹyẹ ara ọkọ baalu naa lo fọn kakiri agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye.
Iwadii ni ọpọ awọn ẹsọ ara ọkọ baalu ni wọn rí níbi iṣẹlẹ naa.
Awọn to ti ṣe idaro fun Wigwe
Lati orilẹede Naijiria lọ si orilẹede Amẹrika ati gbogbo agbaye lapapọ, ẹka idokowo tí ṣe idaro fun Ọga agba ileeṣẹ Access Holding.
Aarẹ Naijiria, oloselu pẹlu awọn ekan ilu kaakiri agbaye lo ti sọrọ sita lori iṣẹlẹ naa.
Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ni ibanujẹ ọkan ni iku Wigwe, iyawo ati ọmọ jẹ.
O sapejuwe Wigwe gẹgẹ bii ẹlẹyinju aanu to mọ isẹ rẹ.
Bakan naa ni Aarẹ orilẹede France, Emmanuel Macron naa ransẹ ibanikẹdun, to si gbe sori opo ayelujara Facebook.
O sapejuwe Wigwe gẹgẹ ọrẹ orilẹede France to fẹ ibasepọ to dan mọran wa laarin Naijiria ati France.
Bakan naa, minisita fun isuna ni Naijiria tẹlẹ, Ngozi Okonjo-Iweala, ẹni to tun jẹ aarẹ ajọ kara-kata l'agbaye, World Trade Organization, naa kẹdun iku Wigwe.
Okonjo-Iweala loju opo ‘X’ rẹ ni iku Ọgbẹni Wigwe jẹ kayeefi ati adanu manigbagbe.
Awọn ekan ilu Femi Otedola, minisita fun ẹka irinna oju ofurufu, Festus Keyamo, Tony Elumelu naa pẹlu awọn to tí ransẹ ibanikẹdun si mọlẹbi Wigwe.
Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Herbert Wigwe

Oríṣun àwòrán, X/Herbert Wigwe
Lati alẹ ọjọ kẹsan an oṣu keji ọdun 2024, ni orukọ ọga agba Access Bank, Herbert Wigwe, ti n tan kalẹ, paapaa lori ayelujara
Amọ pupọ ni ko mọ ohunkohun nipa ọkunrin naa, ju pe o jẹ ọga agba ọkan lara awọn banki to tobi julọ ni Naijriia.
Wigwe to ti fi igba kan jẹ igbakeji ọga agba banki naa, pada di ọga lọdun 2014 lẹyin ti oludokowo pọ rẹ, Aigboje Aig-Imoukhuede fi ipo naa silẹ lọdun 2014.
Ọdun 1966 ni wọn bi Herbert Onyewumbu Wigwe, niluu Port Harcourt, nipinlẹ rivers.
O gba oye imọ ijinlẹ akọkọ ninu iṣiro owo lati University of Naijiria, to w ani Nsukka nipinlẹ Enugu lọdun 1987.
O gba iwe ẹri keji ninu imọ nipa eto ile ifowopamọ ati iṣuna lọdun 1991, ni University College of North Wales, nipasẹ ẹkọ ọfẹ ti ijọba ilẹ Britain.
Lẹyin naa lo kawe nipa akoso ọrọ aje ni Fasiti ilu London.
Wigwe bẹrẹ iṣẹ oluṣiri owo nileeṣẹ Coopers & Lybrand, ko to o darapọ mọ ile ifowopamọ Guaranty Trust Bank nibi to ti ṣiṣẹ fun ọpọlọpọ ọdun.
Lọdun 2002, Ọgbẹni Wigwe ati ẹni ti wọn jọ n dokowo pọ, Aigbpje Aig-Imoukhuede, ra Access Bank.
Laarin ọdun 2002 si 2017, banki naa kuro ni ipo karundinlaadọrin ni Naijiria, si ipo kẹrin laarin awọn banki to tobi julọ.
Orukọ iyawo Wigwe ni Chizoba, wọn si bi ọmọ mẹrin funra wọn.















