Ogun Killing: Ọmọ ọdún 23 jẹ́wọ́ bó ṣe pa ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ́, ẹni ọdún 60 nípinlẹ̀ Ogun

Iya agbalagba

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Arakunrin kan ẹni ọdun mẹtalelogun ni iroyin sọ pe o jẹwọ pe oun pa ẹgbọn iya oun to jẹ ẹni ọdun ọgọta lẹyin ti iroyin sọ pe Babalawo dẹru ba a pe oun yoo pe oku naa ko wa gbẹsan lara ẹni to pa a.

Ni agbegbe Ipokia ni ipinlẹ Ogun ni a gbọ pe Asogba Dasun ti pa Iyabo Dasun to jẹ ẹgbọn iya rẹ.

Alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi lo fi eyi lede fun awọn oniroyin lọjọ Abamẹta.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, Oyeyemi ni lẹyin ti arakunrin naa jẹwọ ni awọn fi ọwọ ofin mu u.

Oyeyemi ni awọn ọmọ oloogbe meji wa ta wọn lolobo ni agọ ọlọpaa to wa ni Ipokia.

"Wọn wa fẹjọ sun ni agọ wa pe lọjọ kejilelogun oṣu kẹjọ lawọn gbọ iroyin iku iya awọn ti lẹni to jẹ pe ko ṣaisan kankan."

Wọn tẹsiwaju pe tori awọn ko ro ibi si ẹnikẹni, awọn pinu lati sin in lai sọ ohunkohun fun ọlọpaa.

"Ṣugbọn lẹyin isinku ni wọn gbọ finrin finrin pe wọn ri afurasi ọhun to jẹ ọmọ aburo iya awọn ninu ile wọn lọjọ ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ ko si pẹ to kuro ni wọn kede pe arabinrin ọhun ku".

Ọrọ yii ti wu ọpọlọpọ ifura jade laarin ilu ti wọn si leri pe awọn yoo tẹsẹ ile bọ ọ nipa gbigbe ẹbọ ti yoo tu aṣiri ẹni yoo wu ko ṣe iru iṣẹ ọhun.

Kete ti o gbọ ohun ti ilu fẹ ṣe lori ọrọ yii ni afurasi naa, Dansu Asogba jade sita lati jẹwọ pe oun loun wa nidii ọrọ naa.

Oyeyemi ni kete ti awọn gbọ iroyin pe afurasi yii jẹwọ ni ọga ọlọpaa to wa ni ẹkun ti Ipokia, SP Adebayo Hakeem ko awọn ọlọpaa lọ sibẹ lati lọ fi panpẹ ọba mu arakunrin ọhun.

Nigba ti ọwọ ọlọpaa tẹ ẹ, Dansu gba pe oun loun pa oloogbe naa, to si sọ fun ọlọpaa pe idi toun fi ṣe e ni pe oun gbagbọ pe oun lo pa akọbi ọmọ oun ati pe oun lo wa nidii oyun kan to walẹ lara iyawo oun.

Oyeyemi fi kun un pe irin ni Dansu fi gba arabinrin naa lọrun eyi to si la iku lọ.

Ẹwẹ, kọmisọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Edward Ajogun ti paṣẹ pe ki wọn gbe afurasi naa taara lọ si ẹka awọn ọtẹlẹmuyẹ fun iwadii ati idajọ rẹ.

Àkọlé fídíò, È gbọ òun ti ojú awọn ara ipinle Ogun rí lọwọ ìṣẹlẹ omiyale