Nollywood Yoruba: Kìí ṣe sinimá ni mò ń ṣe, ìṣẹ̀lẹ̀ ojú ayé gangan ní sùgbọ́n...

Oríṣun àwòrán, Omotayo Amokade/instagram
Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ló ti fẹ́ fa orí ayélujára ya nítori fọ́nran kan tí ọ̀kan lára àwọn òṣèré tíátà Nollywood Yoruba Olatayo Amokade tí gbogbo ènìyàn mọ̀ si Ijebu ju sori ayelujara lọ́sàn òní.
Ìbeèrè ti wọ́n bèrè ni pé, Ah! ṣe Ijebu ko ti ṣe igbeyawo tẹ́lẹ̀ ni?, Ṣe Ijebu ń ṣe ayájọ́ ọjọ́ ìgbéyàwó pẹ̀lú aya rẹ̀ ní? àti àwọn onírúrúru ìbéèrè míràn.
Ó kọ́kọ́ ju àwọran òun àti ọmọbìnrinkan sórí àtagbà ìkànsiraẹni Instagram rẹ pẹlu àmì ifẹ́ láì kọ àkọlé kankan si.
Ní kété ti eyí balẹ̀ ló tún ju fọ́nran ibi ti òun pẹ̀lú ìyàwó ọlẹ̀lẹ̀ ti ń fẹsẹ rajo.
Bótilẹ̀ jẹ̀ pé, ní ẹnu lọ́lọ́ yìí ọ̀ps àwọn eléré orí ìtàgé lọ n fi àwọn irú ǹkan báyìí dá awọn olólùfẹ́ wọ́n lárayá.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Sùgbọ́n ní ti Olatayo Amokade, eyi kìí ṣe Sinimá rárá o bíkò ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ ojú ayé.
Ijebu sàlàyé pé Fọ́nran ati fóto tó safihan ìyàwó tuntun àti òun, sùgbọ́n ọ̀rẹ́ ọkọ ìyáwó lásán ni òun jẹ́.
Bí ó ṣe ri lójú yín , bẹ́ẹ̀ náà ló ri lójú ọ̀pọ̀ àwọn òṣèré Nollywood bi wan ṣe n ki Ijebu ni mẹ́sàn mẹ́wàá pé ó kú oríre ayẹyẹ ìgbéyàwó.
Seyi Edun ni ki alayọnusọ kọju mọ tiẹ, Nainalowo jẹwọ pe ẹkan ṣoṣo lohun de sọọsi ri laye

Oríṣun àwòrán, Instagram/bukunmioluwasina/iamnino_b/
Awọn iroyin to jẹyọ lagbo oṣere Yoruba taa mọ si Yollywood lọsẹ yii ṣebi ẹni pe amulumala ni.
Bi awọn kan ti ṣe n dawọ idunnu laarin awọn oṣere, bẹẹ ni ibanujẹ n dori agbarijọpọ awọn oṣere kodo nitori ipapoda agba oṣere kan.
Ninu ohun taa mu tọ yin wa naa tun ni iroyin itakoọrọ to waye laarin Seyi Edun ati eeyan kan to ranṣẹ eebu si loju opo Instagram.
Ki a ma wulẹ dena pẹnu pupọ, ẹkunrẹrẹ ohun to ṣẹlẹ ree
Falana gbọ tiẹ,Ọlọrun ti doju ti yin naa-Seyi Edun
Esi yi ni gbajugbaja oṣere Seyi Edun fọ fun eeyan kan @dorathy_137 to bọ sori opo rẹ ni Instagram lati sọ fun pe ko wa bi yoo ti ṣe loyun fun ọkọ rẹ.
Ọrọ yii jẹ ohun to mu iriwisi ọtọọtọ wa lati ọdọ awọn ololufẹ Seyi Edun ti pupọ si ni ki ẹni naa gbaju mọ ọrọ tiẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Ninalowo jẹwọ pe ẹkan ṣoṣo lohun fẹsẹ tẹ inu sọọṣi laye
Arẹwa ọkunrin oṣere Yoruba, Bolanle Ninalowo lo jẹwọ ọrọ yii to si tun sọ awọn nkan mii to ni ṣe pẹlu ibagbepọ lọkọ laya.
Lori eto ileeṣẹ iroyin TVC ta mọ si 'The View' lo ti sọ fun awọn olukopa pe oun kii ṣe ẹni to fi tara tara ko ọrọ ẹsin lekan, ṣugbọn ko tunmọ si pe oun ko gbagbọ ninu Ọlọrun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
O ni lorileede Naijiria iyatọ wa laarin ki eeyan bẹru Ọlọrun ati ki eeyan maa tẹle ẹsin kan.

Oríṣun àwòrán, Instagram/iamnino
Ni akotan ọrọ rẹ o jẹwọ pe ẹẹkan ṣoṣo loun ti de ṣọọṣi ri laye oun.
Bukunmi Oluwashina ṣe igbeyawo bonkẹlẹ
Iroyin eleyii dabi ole to yọ tọ onile laarin oru fun ọpọ awọn ololufẹ Bukunmi Oluwashina.
Lati owurọ Ọjọbọ ti fidio igbeyawo rẹ ti jade si ori ayelujara, ni awọn ololufẹ rẹ ati awọn akẹẹgbẹ rẹ kan ti n sọ boṣe ya wọn lẹnu pe o ṣe igbeyawo ni ikọkọ.

Oríṣun àwòrán, Instagram/bukunmioluwasina/
Aṣẹyinwa aṣẹyinbọ, Bukunmi tọrọ aforijin lọdọ awọn eeyan ti onikaluku naa si ki tọkọtaya tuntun naa ku ayọ igbeyawo.
Diẹ lara aworan igbeyawo to fi oju opo rẹ ree

Oríṣun àwòrán, Bunkunmi Oluwasina

Oríṣun àwòrán, Bunkunmi Oluwasina
Jimoh Aliu Aworo re bi agba ree
Ọjọbọ, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2020 ni ilumọọka osere tiata, Jimoh Aliu dagbere faye.
Nigba aye rẹ, Jimoh Aliu ṣe gudugudu meje ati yaya mẹfa lati mu iyatọ ba iṣẹ tiata lori mohunworan.

Oríṣun àwòrán, NTA ado-ekiti/city people magazine
Ṣaaju iku rẹ, Aliu n ṣiṣẹ lori fiimu maarun, ti ireti wa pe awọn agbaagba oṣere Nollywood yoo kopa ninu rẹ.
Ṣugbọn, iku mu u lọ lasiko to n ya ọkan ninu rẹ to pe akọle rẹ ni "Olowo Ite".













