Fuel Price Hike: Ìjọba Nàìjíríà rọ aráàlú láti yí ọkọ̀ àti gẹnẹrétọ̀ wọn sí èyí tó ń lo afẹ́fẹ́ gáàsì lọ́fẹ̀ẹ́

Ile epo

Oríṣun àwòrán, Twitter/PPPRA

Minisita fun ọrọ epo rọbi, Timipre Sylva ti kede pe lati oṣu Kẹwaa ọdun 2020 lọ, ijọba apapọ yoo bẹrẹ si yi awọn ọkọ ayọkẹlẹ ati gẹnẹretọ awọn araalu pada si eyi to n lo afẹfẹ gaasi.

Sylva ni wọn yoo ṣe eyi lọfẹẹ fawọn ọmọ Naijiria lọna ati mu adinku ba owo epo petirolu to gbowo lori.

Ori eto kan lori mohunmaworan apapọ ilẹ wa ni Minisita ti kede bẹẹ laarọ ọjọ Aje.

Sylvia ni awọn ọkọ ayọkẹlẹ ni wọn ṣe lati maa lo gaasi ati epo petirolu papọ, bẹẹ si ni afẹfẹ gaasi dinwo ju epo petirolu lọ."

Awọn ọmọ Naijiria yoo lanfaani lati yan eyi to ba wu wọn. Ijọba yoo si bẹrẹ eto naa pẹlu awọn kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta nilu Portharcourt."

O fikùn pe ilo afẹfẹ gaasi ba oju ọjọ wa mu ni Naijiria, ti eyi ba si dohun tán, Naijiria yoo ri iranwọ gba lati ilẹ okeere.