Kwara Assembly: Ilé Arúgbó Saraki la fẹ́ lò fún ilé ìwòsàn àwọn òṣìṣẹ́

Bukola Saraki

Oríṣun àwòrán, @NGRSenate

Àkọlé àwòrán, Ile Asofin Kwara ni ijọba lo ni ilẹ ati ohun ini ti awọn gbe ẹsẹ le,kii se gomina tẹlẹri, Bukola Saraki.

Ile Asofin ni ipinlẹ Kwara ti pasẹ pe ki wọn gba ilẹ ti wọn n pe ni 'Ile Arugbo' pada lọwọ Aarẹ Ile Igbimọ Asofin tẹlẹri, Bukola Saraki.

Ile asofin naa sọ wi pe ijọba ipinlẹ Kwara lo ni ilẹ naa, kii se Bukola Saraki lo san owo ilẹ naa.

Atẹjade kan ti Oluranlọwọ fun olori Ile, Ibrahim Sheriff fi lede sọ wi pe, ko ba ofin mu bi ijọba ana ni ipinlẹ naa, se fun Saraki ni ilẹ ọhun, nitori ofin to jẹ mọ eto ifẹyinti ni ipinlẹ Kwara ti pin ẹtọ Saraki fun un.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fi kun wi pe Ile Arugbo naa ni wọn fẹ lo fun ile iwosan awọn oṣiṣẹ ati ile isẹ ijọba keji, ti ko si si ẹri pe ẹnikẹni san owo fun un.

Ile Igbimọ Asofin naa wa parọwa si ẹnikẹni ti ko ba tẹ lọrun lati fi ẹri han wi pe, awọn san owo fun ilẹ naa.