Ìyá Ìbejì ọmọ Aráyé le figbe ta, bí ayé ṣe ní òun ló kú, dípo Ìyá ilé Ọ̀ọ́kán

Oríṣun àwòrán, Ronke Gboye/ Kunle Aford You Tube
Ma fi ọrun yọ mi, gbogbo wa la n lọ. Ṣugbọn bi eeyan ko ba ti i ku, baba ẹnikan ko le gbeni sin.
Eyi lo mu Abilekọ Nike Gboye, agba oṣere ti awọn eeyan mọ si Iya Ibeji ọmọ araye le, ṣalaye nipa iroyin iku rẹ ti awọn kan bẹrẹ si i gbe kiri lati ana, ọjọ Iṣẹgun.
Iroyin iku Iya Ibeji ọmọ araye le to gbode lojiji yii ko ṣẹyin iku agba oṣerebinrin tiata mi-in, iyẹn Iya Ile ọọkan ti orukọ rẹ gan-an n jẹ Florence Ogunbiyi to jade lanaa.
Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pe niṣe ni awọn ẹka iroyin kan bẹrẹ si i kede pe Iya Ibeji ọmọ araye le, lo jade laye.
Koda, awọn ẹka iroyin naa tun fi fọto asiko ti Iya Ibeji n ṣe aisan gbe ikede iku rẹ naa lẹsẹ, o si ti n tan kari ayelujara.
BBC News Yoruba kan si Iya Ibeji ọmọ arayele lori foonu lowurọ ọni, Ọjọruu, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹwaa ọdun 2025, eyi ni ohun ti iya naa ati ọmọ rẹ, Ronke Gboye, ba wa sọ.

Oríṣun àwòrán, Ronke Gboye
''Èmí wà láyé, mo wà nílé mi n'Ibadan''
"Gẹgẹ bi ẹyin naa ṣe n gbọ ohun mi ketekete yii, mi o ku o, mo wa laye, mo wa ninu ile mi n'Ibadan.
"Ọrẹ mi ni Iya ile ọọkan, a jọ ṣiṣẹ tiata papọ ni, agbegbe Ifo, nipinle Ogun lo n gbe, a jọ wa papọ ri.
"Oun lo ṣalaisi bayii, emi kọ ni mo ku. Ẹ ba mi sọ fun gbogbo eeyan pe mo ṣi wa laaye.''
Bẹẹ ni Iya Ibeji ọmọ arayele ṣalaye.
Ikede iku oṣerebinrin naa lai ti i ku rẹ ko ṣẹyin aarẹ to ṣe e lọdun diẹ sẹyin, eyi to mu ko beere iranlọwọ araalu, ti Pasitọ Ademola to ni ijọ Agbala Gabriel n'Ibadan si ṣe iranlọwọ ile kan fun un ati ṣọọbu ti iya naa yoo ti maa ta ọja pẹẹ-pẹẹ-pẹ.

Oríṣun àwòrán, Ronke Gboye
Àwọn èèyàn ti fẹ́ pè mi pa lórí ìròyìn ikú màmá mi, Iya Ibeji ọmọ araye le wà láyé o.
Nigba to n kin ọrọ iya rẹ lẹyin nipa iroyin iku to jade naa, Ronke Gboye to jẹ ọmọ Iya Ibeji, ṣo pe awọn eeyan ti fẹrẹ pe oun pa lorii foonu.
"Ọpọ eeyan lo n pe mi lati beere pe ṣe loootọ ni mama mi ku, mo si n jẹ ki wọn mọ pe maami o ku, wọn wa laaye nile wọn n'Ibadan nibi.
"Iya Ile ọọkan to ku yii jẹ ọrẹ wọn tẹlẹ, mo ranti pe a ti jọ gbe ile kan naa ri ni Meiran, niluu Eko.
"Awọn ati Iya Ibeji jọ ṣiṣẹ pọ bii ẹgbẹ kan naa nigba kan, koda, nigba ti Agbala ṣi ile fun Iya Ibeji, Iya ile ọọkan waa ki wa nibi.
"Oṣu kan gbako ni wọn lo nibi, ti wọn fẹ ri Agbala Gabriel boya yoo le ri iranlọwọ gba, ṣugbọn wọn ko pada ri i. Ara wọn o dẹ ya.
"Nigba ti mo ri i pe wahala yẹn pọ ju fun mi, mi o le maa tọju wọn ki n tun maa tọju iya mi ni mo ṣe ni ki wọn pada sile wọn.
"Ẹ ba mi sọ fun gbogbo ọmọ Naijiria, pe Iya Ibeji ọmọ araye le kọ lo ku, bo tilẹ jẹ pe awọn naa ko fi bẹẹ ranti nnkan pupọ mọ, ṣugbọn wọn ṣi wa laye o.''
Ronke Gboye, ọmọ Iya Ibeji ọmọ araye le lo wi bẹẹ
Ta a ni Iya Ibeji ọmọ araye le?
Nike Gboye, Iya Ibeji ọmọ araye le, ki i ṣe oṣere ti awọn ọdọ asiko yii mọ, ṣugbọn fun awọn eeyan to ti n ba ere tiata Yoruba bọ lati bii ogoji ọdun sẹyin, odu ni mama naa lagbo tiata.
Ere ọlọsẹ mẹtala kan ti wọn pe akọle ẹ ni Ọmọ Araye le, eyi ti Oloogbe Ola Omonitan (Baba No Regret) kọ, lo fun Nike Gboye ni okiki pupọ, to si tun fun un ni orukọ Iya Ibeji Ọmọ araye le ti awọn eeyan mọ ọn si.
Ọmọ bibi ipinlẹ Osun naa jẹ iyawo fun agba oṣere, Oloogbe Gboye tawọn eeyan mọ si Tiro Ahọmọju.
Iku ọmọ rẹ akọbi to waye ni nnkan bii ọdun mẹta sẹyin lo di aarẹ si Iya Ibeji lara.
Aarẹ naa pọ, ṣugbọn pẹlu iranlọwọ Ọlọrun ati awọn ẹlẹyinju aanu, Iya naa dide lori ẹsẹ rẹ, o si n gbe ile ti Agbala Gabriel kọ fun un siluu Ibadan, bi ko tilẹ le lọ si oko ere mọ.
Ọ̀fọ̀ ńlá tún ṣẹ̀ lágbo tíátà, àgbà òṣèré míì lobinrin jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Kunle Afod TV/Youtube
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe gbà òṣèré tíátà nnì, Iya Ile Okan ti jáde láyé.
Àtẹ̀jáde kan tí gbajúmọ̀ òṣèré Kunle Afod fi sórí ìkànnì Instagram rẹ̀ ló ti kéde ikú àgbà òṣèré náà.
Ó kọ sójú òpó náà pé àwọn padà pàdánù òṣèré náà.
Ní ọdún tó kọjá ni Kunle Afod ṣe àbẹ̀wò sí ilé Iya Ile Okan ní abúlé kan tó wà ní ìpínlẹ̀ Ogun.
Nínú fídíò àbẹ̀wò ẹ̀hún tí Kunle Afod fi sórí ìkànnì Youtube rẹ̀ ni ìyá náà ti sọ fún Afod pé òun ti ń ṣe àárẹ̀ fún ìgbà pípẹ́.
Ó ní ẹsẹ̀ òun ni ó kọ́kọ́ ń dun òun kó tó di pé ojú ọ̀tún bẹ̀rẹ̀ sí ní yọ òun lẹ́nu.
Ó ṣálàyé ojú ọ̀tún òun kò ríràn mọ́ látàrí àárẹ̀ náà, gbogbo ìgbìyànjú láti rí ìwòsàn fún un ló sì já sí pàbó.
Iya Ile Okan sọ pé lára ìgbìyànjú òun ni òun ṣe ṣe àbẹ̀wò sí ọgbà Agbala Gabriel ní ìlú Ibadan ṣùgbọ́n tí òun kò rí Agbala Gabriel bá sọ̀rọ̀.
Lẹ́yìn náà ni Kunle Afod ṣe ìkówójọ, tí wọ́n sì fún ìyá náà ní owó ₦720,000.
















