Kí ló ṣẹlẹ̀ tí ariwo fi ta pé Wale Edun, mínísítà ètò ẹ̀náwó, rọ lápá-rọ lẹ́sẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Federal Ministry of Finance/X
Ni opin ọsẹ ni ariwo gbalẹ lori ayelujara pe Minisita feto ẹnawo lorilẹede yii, Wale Edun, n saisan to lagbara.
Koda, iroyin ti a ko le fidi rẹ mulẹ naa ni Edun ti rọ lapa, rọ lẹsẹ, ti wọn si ti n mura lati gbe lọ soke okun lati gba itọju nile iwosan.
Gbogbo ọmọ Naijiria ni iroyin naa ba lojiji, ti wọn si n kọminu pe ki lo se Minisita naa, ti ilera rẹ fi yiwọ debi pe ko le rin mọ.
Bakan naa ni iroyin ti ko ni gbongbo ọhun sọ pe aarẹ Bola ti nubu ti n saayan lati wa ẹniti yoo rọpọ Edun, gẹgẹ bii Minisita nitori ilera rẹ to buru.
Ọrọ yii si lawọn eeyan n gba, bii ẹni gba igba ọti lori ayelujara, ki ileesẹ aarẹ ilẹ wa to tan imọlẹ si ọrọ naa.
Edun, to jẹ akọsẹmọṣẹ onimọ nipa ọrọ-aje lo ti n ṣagbatẹru oniruuru eto atunṣe ọrọ-aje ti ijọba Tinubu n ṣe lati ibẹrẹ ijọba to wa lode lati ọdun 2023.
Ileesẹ aarẹ fidi rẹ mulẹ pe ojojo n se ara Wale Edun, gomina banki apapọ ni yoo rọpo minisita feto isuna lati soju Naijiria nibi ipade Banki Agbaye l'Amerika
Bi iroyin se n ja rain nilẹ nipa ilera Wale Edun, ileeṣẹ aarẹ ti fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni ojojo n se ara Minisita naa, ti ara rẹ ko si le lasiko yii.
Atẹjade ti ileesẹ aarẹ fisita ni, Aarẹ Bola Tinubu fẹ fi ẹlomiran rọpo minisita eto inawo ati alakoso ọrọ aje, Wale Edun, nitori o wa lori idubulẹ aisan.
Oludamọran aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga, to buwọlu atẹjade naa ti kede wi pe gomina banki apapọ Naijiria, CBN, Olayemi Cardoso, ni yoo dari ikọ Naijiria lọ sibi ipade banki agbaye ati ajọ IMF to bẹrẹ lonii niluu Washington DC, lorilẹede Amẹrika.
Onanuga ni eyi waye nitori ailera minisita eto inawo, Edun, to yẹ ko ṣiwaju ikọ orilẹede Naijiria lọ sibi ipade naa.
Oludamọran aarẹ ni minisita keji fun eto inawo , Doris Uzoka-Anete, naa yoo kọwọọ rin pẹlu Cardoso lọ si ibi ipade ọhun l'Amẹrika.
Gẹgẹ bi banki agbaye ṣe ṣalaye, lara awọn koko ipade naa ni ijiroro lori idagbasoke ọrọaje eyi ti yoo waye lọjọ kẹrindinlogun oṣu yii.
Ipade ajọ IMF naa jẹ ọkan gboogi lara koko ti wọn yoo sọrọ le lori ni Washington DC lọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹwaa yii.
Awọn nnkan mii ti wọn yoo sọrọ le lori nibi ipade ọhun ni ọrọ-agbe agbaye oni ẹlẹkunjẹkun atwọn nnkan mii.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
''Loootọ ni minisita eto inawo ni ailera, amọ, kii ṣe arun rọpa-rọsẹ''
Ẹwẹ, iwe iroyin Punch ṣalaye pe agba oṣiṣẹ kan nileeṣẹ aarẹ ti fidi rẹ mulẹ wi pe irọ nla ni iroyin to sọ pe minisita eto inawo ti larun rọpa-rọsẹ, wọn si ti gbe lọ soke okun fun itọju.
Iwe iroyin Punch ni oṣiṣẹ ileeṣẹ aarẹ naa ti ko fẹ darukọ ara rẹ sọ pe loootọ ni Edun n ṣaarẹ, amọ, ko ni arun rọpa-rọsẹ.
''Edun wa ni ile rẹ, wọn o gbe e lọ soke okun fun itọju.
O le lọ gba itọju nibi kibi to ba wu u tawọn dokita ba ni ki o ṣe bẹẹ, amọ, irọ ni pe o ti larun rọpa rọsẹ.
Ko ni arun rọpa-rọsẹ, idi niyii ti a ṣe fi atẹjade sita pe o ni ailera,'' agba oṣiṣẹ nileeṣẹ aarẹ lo sọ bẹẹ.
Elomiran lati ileeṣẹ aarẹ tun fidi rẹ mulẹ pe awọn dokita n ṣe itọju Ọgbẹni Edun lọwọ lorilẹede Naijiria, ṣugbọn o ṣee ṣe ki o lọ soke okun fun itọju sii.
''Awọn dokita Naijiria lo n tọju rẹ bayii, o le lọ soke okun ti o ba ṣe pataki lati ṣe bẹẹ.
Amọ, o wa nile rẹ bayii, ijọba ko si gbero lati rọpo rẹ,'' oṣiṣẹ ileeṣẹ aarẹ.
Oludamọran aarẹ lori eto iroyin, Onanuga, naa sọ pe ''ẹni ọdun mọkandinlaadọrin ni Wale Edun.
Ṣadeedee lo ni ailera, amọ, o si n gba itọju ni Naijiria; ara rẹ ti n ya diẹdiẹ.''
Ọgbẹni Edun ni kọmiṣọna fun eto inawo nipinlẹ Eko laarin ọdun 1999 si 2004 lasiko ijọba Bola Tinubu gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Eko
Ileeṣẹ ijọba to n ri si eto inawo ko tii sọ nkankan lori ailera minisita Edun titi di akoko yii.
Ta ni Wale Edun ti wọn lo n se ojojo?
Oloye Adebayo Olawale Edun, ti gbogbo eeyan mọ si Wale Edun, jẹ akọsẹmọsẹ onimọ nipa ọrọ aje, osisẹ banki ni ẹka idokowo ati oloselu.
Wale Edun jẹ Minisita feto ẹnawo ati ọrọ aje fun ijọba aarẹ Bola Tinubu lati ọdun 2023 to ti gori aleefa lati maa tukọ orilẹede Naijiria.
Bakan naa lo jẹ alaga fun igbimọ awọn gomina ni Banki agbaye lọdun 2023.
Oun si ni ọmọ orilẹede Naijiria akọkọ ti yoo di ipo naa mu lati ọgọta ọdun sẹyin.
Ni ọdun 1999, Wale Edun lo jẹ Minisita feto ẹnawo nipinlẹ Eko lasiko ti Sẹnatọ Bola Tinubu jẹ gomina nipinlẹ naa.
Edun si lo di ipo naa mu titi di ọdun 1984 ti saa akọkọ gomina Tinubu pari bii gomina ni ipinlẹ Eko.















