Àlàyé rèé lórí báwọn olólùfẹ́ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Kano Pillars ṣe na 3SC ní àlùkì lẹ́yìn tí wọn gbá ọ̀mì ní Kano

Awọn agbabọọ̀l;u 3SC meji ti wọn fara gbọgbẹ lasiko ti ija bẹ silẹ nigba ti wọn gba bọọlu pẹlu Kano Pillars. Ọkan fi ọwọ bo oju rẹ ti wọn na, ko si wọ asọ sara, o si di irun ori rẹ sẹyin nigba ti ekeji wọ asọ ere idaraya alawọ buluu, o kun irun ori rẹ ni awọ goolu, to si na ọwọosi rẹ ti wọn we bandeji mọ si oke.

Oríṣun àwòrán, 3SC TV

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Gugugbẹ ja ni papa iṣere Sani Abacha to wa niluu Kano lalẹ ọjọ Aiku lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu Shooting Stars (3SC) ti ilu Ibadan pada jẹ goolu mọ ẹgbẹ agbabọọlu Kano Pillars lara lasiko to ku iṣẹju diẹ ki ifẹsẹwọnṣe to n waye laarin wọn pari.

Goolu ti 3SC jẹ yii lo mu ki ifẹsẹwọnsẹ ọhun pari si ami ayo kọọkan fun ikọ agbagbọọlu mejeji ni ọjọ kẹjọ idije bọọlu afẹsẹgba Naijiria, Nigerian Premier Football League (NPFL).

Lẹyin ti 3Sc sọ goolu naa wọle tan ni awọn alatilẹyin Kano Pillars binu ya wọ ori papa ti wọn si bẹrẹ si n ṣe iya fun awọn alakoso ere, to fi mọ awọn agbagbọọlu 3SC.

Papa isere ti ikọlu naa ti waye, ọpọ eeyan wa lori papa, ti wọn n sa asala fun ẹmi wọn, ti a si ri afẹfẹ tajutaju to n se eefin laarin ọpọ ero.

Oríṣun àwòrán, 3SC TV

"Awọn ololufẹ Kano Pillars fo irin ti wọn fi pin papa iṣere, wọn wọ inu papa ti awọn agbagbọọlu maa n wa, wọn si bẹrẹ si n le rẹfiri kabakaba"

Gbas-gbos naa le to bẹẹ ti awọn agbofinro fi yin afẹfẹ tajutaju lati tu wọn ka.

Awọn aworan lati papa iṣere naa ṣafihan awọn ololufẹ Kano Pillars pẹlu igi lọwọ wọn, to fi mọ awọn ohun ija mii ti wọn si n le awọn alakoso ere kuro lori papa.

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ṣalaye pe pupọ ninu awọn alakoso ere ọhun ni ko ba farapa yanayana amọ ori ko wọn yọ.

Akọroyin kan ti ọrọ naa ṣoju rẹ jabọ pe "rugudu nla lo ja ni papa iṣẹre naa, ni kete ti Shooting Stars sọ goolu wọ inu awọn Kano Pillars bayii, ni wahala bẹrẹ.

"Wọn fo irin ti wọn fi pin papa iṣere, wọn si wọ inu papa ti awọn agbagbọọlu maa n wa, wọn si bẹrẹ si n le adari ayo naa kabakaba.

"Niṣe lawọn ọlọpaa ni lati yin afẹfẹ tajutaju lati le wọn pada sẹyin."

Wayi o, kii ṣe igba akọkọ ree ti ija yoo bẹ silẹ lasiko ifẹsẹwọnsẹ ni liigi bọọlu Naijiiria.

Ninu oṣu Kẹrin ọdun yii, awọn ololufẹ 3SC yii kan naa de awọn agbabọọlu, rẹfiri atawọn akọroyin ni igbekun fun odidi wakati kan ni papa iṣẹre Lekan Salami to wa niluu Ibadan lẹyin ti 3SC gba ọmi pẹlu ikọ agbabọọlu Ikorodu City.

A fẹ ki wọn mu awọn eeyan to wa nidi iwa idaluru naa, ki wọn si foju wọn ko ata ofin, ki wọn si se agbekalẹ ifiyajẹni lati dena iwa yii lọjọ iwaju - 3SC

Nigba ti wọn n salaye bi rogbodiyan naa se waye, ikọ agbabọọlu 3SC koro oju si isẹlẹ naa, eyinto sapejuwe bii iwa idaluru.

Atẹjade kan ti ikọ adari 3SC fisita lori isẹlẹ naa salaye pe ohun eelo fun irẹpọ, itara ati awujọ lo yẹ ki ifẹsẹwọnsẹ ere bọọlu jẹ nitori pe ere lasan la n fi ọmọ ayo se.

"Ko yẹ ki iwa ipa tabi idunkooko mọ ni maa waye lasiko ere bọọlu, a si n ke si ikọ NPFL atawọn agbofinro lati tanna wadii isẹlẹ naa.

A fẹ ki wọn mu awọn eeyan to wa nidi idaluru naa, ki wọn si foju ko ata ofin, bakan naa, a fẹ ki wọn se agbekalẹ eto ifiyajẹni to gbopọn lati dena irufẹ iwa yii lọjọ iwaju.

Ohun to yẹ ko se koko ni sise ipese eto aabo to gbopọn fun ẹka ere idaraya ati awọn olukopa"

Ikọ 3SC wa fọwọ gbaya pe ohun to jẹ oun logun ni aisegbe ninu ere idaraya ati ibọwọ funraẹni lasiko ifigagbaga kọọkan.

Iṣẹlẹ yii ko dun mọ wa ninu, a o gbe igbesẹ to yẹ lori rẹ - NPFL

Wayi o, ikọ to n se akoso ifẹsẹwọnsẹ bọọlu liigi labẹle, The Nigerian Premier Football League (NPFL) ti sọrọ nipa isẹlẹ ifiyajẹni to waye nilu Kano naa.

Ninu atẹjade kan ti Davidson Owumi, to jẹ adari ajọ NPFL fi lede, o bu ẹnu atẹ iṣẹlẹ naa, o si juwe rẹ gẹgẹ bii eyiii ti ko bojumu.

NPFL ni awọn n reti awọn ẹri maa jẹ mi rinṣo lori ohun to ṣẹlẹ ni papa iṣere naa ati ọrọ lẹnu awọn alakoso ere.

O ni "A bu ẹnu atẹ lu bi wọn ṣe wu iwa ipa ati idunkokomọni si awọn agabọọlu, alakoso bọọlu atawọn ololufẹ bọọlu."

O sọ siwaju si pe iwa yii kii ṣe irufẹ iwa to maa n waye lemọlemọ amọ awọn yoo gbe igbesẹ to tọ lori rẹ ni kete ti ọwọ awọn ba ti to gbogbo ẹri ti yẹ tan.

NPFL pari atẹjade naa pe awọn ko ni sinmi ninu ojuṣe awọn lati ri pe irufẹ iwa ibajẹ bẹẹ ko waye lagbo ere bọọlu afẹsẹgba ni Naijiria mọ.

Asiko ti awọn olulufẹ Kano Pillars ya bo ori papa

Oríṣun àwòrán, Naija metro

Iye igba ti awọn ikọ agbabọọlu mii kọlu 3SC lasiko ifẹsẹwọnsẹ lori papa

April 27, 2012 - Gombe

Lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2012, awọn ololufẹ Gombe United kọlu awọn agbabọọlu atawọn alakoso Shooting Stars lori papa, koda, wọn gun agbagbọọlu 3Sc kan lọbẹ lọdun naa lọhun.

Sept 11, 2013 – Akure

Lọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan an, ọdun 2013, awọn ololufẹ ẹgbẹ agbagbọọlu Sunshine Starts ti ilu Akure kọlu awọn agbabọọlu 3SC lẹyin ifẹsẹwọnsẹ kan ti esi rẹ ko tẹ Sunshine Stars lọrun. Iṣẹlẹ naa mu ki wọn fi ofin de ẹgbẹ agbagbọọlu ọhun fun akoko diẹ ki ajọ NPFL to pada yọ okun lọrun wọn.

Oct 12, 2025 -Kano

Igba kẹta ti awọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu mii yoo kọlu 3SC ni eyii to waye ni papa iṣere Sanni Abacha to wa niluu Kano lọdun 2025 yii.