Orí kó ìkọ agbábọ́ọ̀lù Super Eagles yọ lọ́wọ́ ikú ọkọ̀ òfufufú

Aworan yii ṣafihan ikọ agbabọọlu Super Eagles ilẹ Naijiria ti wọn tò, wọn fi ọwọ ọtun si aya wọn pẹlu aṣọ ikọ naa ti wọm wọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ikọ agbabọọlu Super Eagles ilẹ Naijiria.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Iku to ba fẹ pani, to ṣini ni fila, o yẹ ki oluwarẹ maa dupẹ ni.

Bẹẹ lọrọ ri fun ikọ agbabọọlu ilẹ wa, Super Eagles, lanaa ode yii, nigba ti ọkọ ofurufu to n gbe wọn bọ pada sile lati Polokwane, South Africa, balẹ ni ti pajawiri ni Luanda, orilẹede Angola, lati dena ijamba to le mu ẹmi lọ.

Gẹgẹ bi ajọ to n ri si ere bọọlu lorilẹede yii, NFF, ṣe ṣalaye, : "Baaluu ValueJet to n gbe ikọ naa lati Polokwane, South Africa, lọ si Uyo fun ifẹsẹwọnsẹ ti yoo waye lọjọ Iṣẹgun fun ti idije ife ẹyẹ agbaye ọdun 2026, ti wọn yoo ti koju ilẹ Olominira Benin Republic, koju iṣoro ferese to fọ lofurufu, lẹyin to gbera nibi ti wọn ti rọ epo si i ni Luanda, orilẹede Angola.

"Awakọ naa tete ṣe bii akọṣẹmọṣẹ, o dari baaluu pada si papakọ ofurufu Luanda, lati dena ijamba.

"Ọkọ yii kan naa lo ti kọkọ ko awọn ikọ Super Eagles kan lọ si Polokwane lalẹ Ọjọbọ, to si balẹ si South Africa ni aarọ ọjọ Ẹti."

NFF ṣèlérí láti pààrọ̀ ọkọ̀ òfurufú náà

Ajọ NFF ninu alaye rẹ, tẹsiwaju pe ọkọ ofurufu yii kan naa ni wọn lo lasiko ti Super Eagles koju ikọ Bafana Bafana ilẹ South Africa, ni Bloemfontein, loṣu to kọja.

"Ajọ NFF fi da ẹyin ololufẹ ati alẹnulọrọ gbogbo loju, pe ValueJet ati awọn ẹka to yẹ, titi kan Minisita irinajo ofurufu ati ti ilẹ okeere, ati Olori oṣiṣẹ lọfiisi Aarẹ, ti n ṣiṣẹ lori bi wọn yoo ṣe gba iwe aṣẹ ti yoo paaarọ baaluu yii.

Baaluu tuntun naa yoo fo lati Eko lọ si Luanda, lati gbe ikọ agbabọọlu yii lọ si Uyo."

Ajọ NFF dupẹ lọwọ awọn ololufẹ ikọ naa fun suuru ti wọn ni, wọn ni awọn yoo ri i daju pe Super Eagles balẹ gudẹ pẹlu alaafia .

Lasiko ti a n pari iroyin yii, afikun alaye ti NFF fi si oju opo X wọn ni pe ikọ Super Eagles ti balẹ si Uyo.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post