Bí ìdìbò ààrẹ ṣe ń wáyé, ìjọba Cameroon kìlọ̀ lórí ìkéde èsì ìbò ṣáájú àjọ elétò ìbò

Mínísítà fọ́rọ̀ abẹ́lé ní Cameroon, Paul Atanga Nji wọ kóòtù dúdú pẹ̀lú ṣáàtì funfun lábẹ́ àti Táì aláwọ̀ búlúù ní ọrùn rẹ̀ . Ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbohùngbohùn wà níwájú rẹ̀, tí àwòrán ààrẹ Cameroon, Paul Biya wà lẹ́yìn rẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Michel Mvondo/BBC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Bí ètò ìdìbò láti yan ààrẹ tuntun ṣe ń wáyé lónìí ọjọ́ Àìkú, Mínísítà fọ́rọ̀ abẹ́lé ní Cameroon, Paul Atanga Nji, ti ṣèkìlọ̀ fáwọn olùdíje níbi ètò ìdìbò ààrẹ orílẹ̀ èdè náà láti yé kéde ara wọn gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí, kí àjọ elétò ìdìbò tó kéde ẹni tó gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò náà.

Níbi àpérò àwọn akọ̀ròyìn tí mínísítà náà ṣe, ló ti ṣèkìlọ̀ náà bí ó ṣe ń sọ pé àwọn ti ń gbọ́ ìròyìn pé olùdíje kan ti ń gbèrò láti kéde ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò tó ń wáyé lónìí.

Àmọ́ Nji kò dárúkọ olùdíje náà.

Ó júwe èròńgbà náà bí èyí tí kò bá òfin mu, tó sì dúnkokò láti fi òfin gbé olùdíje tó bá ṣe bẹ́ẹ̀.

Àwọn olùdíje gbọ́dọ̀ ṣetán láti lo ìlànà òfin láti dá ààbò bo ẹ̀tọ́ wọn"

Paul Atanga Nji ni "Gbogbo àwọn tó ń gbèrò láti kéde èsì ìdìbò ààrẹ tàbí kéde ara wọn gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò náà ni yóò máa tẹ òfin lójú mọ́lẹ̀, kí ẹni bẹ́ẹ̀ sì máa retí láti fojú winá òfin.

"Àwọn olùdíje gbọ́dọ̀ ṣetán láti lo ìlànà òfin láti dá ààbò bo ẹ̀tọ́ wọn."

Ṣáájú ni mínísítà náà ti kọ́kọ́ fẹ̀sùn kàn pé àwọn olùdíje nínú ẹgbẹ́ alátakò ti ń gbìyànjú láti da ètò ìdìbò náà rú nípa lílo ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn àti gbígbé èsì ìdìbò òfégè jáde.

Ó tẹpẹlẹ mọ pé àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò nìkan ni òfin gbà láàyè láti kéde èsì ìbò.

Nji sọ àrídájú rẹ̀ pé ìjọba ti gbé àwọn ìgbésẹ̀ láti ri dájú pé ètò ìdìbò náà lọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀.

Àmọ́ ṣe ni ìkọnilọ́minú wà pé ó ṣeéṣe kí wọ́n dẹ́yẹ sí ẹkùn àwọn tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní orílẹ̀ èdè náà láti máṣe kópa níbi ètò ìdìbò náà.

Kí ló ti wáyé ṣáájú níbi ìdìbò ààrẹ tó kọjá ní Cameroon?

Ní ọdún 2018, Paul Biya ni wọ́n kéde gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí ètò ìdìbò ààrẹ orílẹ̀ èdè náà.

Ṣùgbọ́n olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú alátakò, Maurice Kamto fẹ̀sùn kàn pé èrú wáyé níbi ètò ìdìbò ọ̀hún àti pé òun gan ni ó jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò náà.

Lẹ́yìn náà ni wọ́n fi sí àhámọ́ fẹ́sùn pé ó ṣètò ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn káàkiri òpópónà.

Èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ ni ìrètí wà pé ó máa kópa níbi ètò ìdìbò láti yan adarí tuntun fún orílẹ̀ èdè Cameroon ní ọjọ́ Àìkú.

Láàárín ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún tí ètò ìdìbò náà bá wáyé ni ìrètí wà pé àjọ elétò ìdìbò máa kéde èsì ìbò.

Ààrẹ Paul Biya, ẹni ọdún méjìlélógún (92), tó ti lò ọdún mẹ́tàlélógójì lórí ipò ààrẹ Cameroon, tí kò sì pàdánù ìbò kankan rí ni àwọn èèyàn ń sọ pé ó ṣeéṣe kó jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò náà.