Sọ iye tí o fi ṣe ọ̀nà yìí ní pàtó, yéé ṣe kùrùkẹrẹ kiri lórí owó iṣẹ́ àgbàṣe – Makinde tahùn sí Umahi, mínísítà iṣẹ́ òde lóríi títì etíkun Eko sí Calabar

Oríṣun àwòrán, Facebook/Makinde/Umahi/Oseni
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti sọrọ lori awuyewuye to n waye nipa iye owo ti ijọba apapọ n ṣe opopona ipinlẹ Eko si Calabar, iyẹn Lagos-Calabar Coastal Highway.
Nigba to n sọrọ nibi eto kan lọjọ Ẹti, Makinde sọ pe ko nilo ki minisita fun ọrọ iṣẹ, David Umahi, maa wo oju ofurufu ko to le dahun ibere lori iye owo ti ijọba n na ni pato lori ọna naa.
Ọrọ yii lo n jade lẹyin họwuhọwu to waye laarin Umahi ati sọrọsọrọ ori ẹrọ amohunmaworahn Arise, Rufai Oseni lọjọ Iṣẹgun.
Ṣaaju lori eto naa ni Rufai ti kọkọ bere lọwọ Umahi pe ko sọ iye ti ijọba n na lati ṣe ọna naa, ko si ṣalaye iye owo kilomita kọọkan.
Ibeere naa ko dun mọ Umahi ninu, eyii to mu ko pe ara rẹ ni Ọjọgbọn ninu iṣẹ imọ ẹrọ, ati pe iye owo ti wọn na lori awọn kilomita kọọkan yatọ sira wọn, alaye eyii ti yoo ṣoro lati ye Oseni.
O ni "Ibere ọmọde lasan ni ibere yii, ko si mu ọgbọn wa.
"Iṣẹ n lọ lọwọ, a ti san owo, o si wa n bere lọwọ mi pe bawo ni a ṣe na owo. Iṣẹ ni a fẹ fi owo naa ṣe, a o si san owo ọhun gẹgẹ bii iṣẹ ti wọn ba ṣe.
"Bawo ni o ṣe maa bere lọwọ mi iye ti a n na lori kilomita kan? Iye ti a n na yatọ sira wọn, iye owo ti a maa na lori kilomita to wa niwaju yatọ si eyii ti a maa na lori kilomita to tẹlẹ.
"Gbe ẹnu rẹ dakẹ ki o ye sọ ohun ti o ko mọ. Ọjọgbọn ni mi ninu iṣẹ yii, o ko mọ nnkankan. Mo ni imọ iṣẹ yii daadaa. O ko ni oye ohun ti o n bere."
Bi Umahi ṣe n fun Oseni lesi yii, Oseni kọ jalẹ lati ju ọwọ silẹ fun minisita naa.
Ki ni Makinde sọ?
Nigba ti Makinde n sọrọ nibi eto kan, o ni ibere ti Oseni bere lọwọ Umahi kii ṣe eyii to le lati dahun.
O ni "Wọn bere lọwọ minisita iye ti wọn n na si oju ọna niṣe lo n sọ nnkan mii pe kilomita to wa niwau ju eyii to tẹle lọ, o daa elo gan ni iye kilomita kan jẹ?
"Nigba ti a ṣe ọna Oyo si Iseyin, iye owo ti a na jẹ N9.99b tabi N10b.
"A si ṣe kilomita mẹrinlelọgbọn si marundinlogoji, to n tumọ si pe iye owo kilomita kan jẹ nnkan bii N238m."
Ti ẹ ko ba gbagbe, lẹyin ti Aarẹ Tinubu gori alefa ijọba lo bẹrẹ iṣẹ eti omi ipinlẹ Eko si Calabar naa, eyii ti yoo gba ipinlẹ mẹsan an kọja.
Ọgọrun meje kilomita ni apapọ ọna naa yoo jẹ amọ wọn ti pari kilomita mẹtadinlaadọta ninu rẹ gẹgẹ bii ohun ti ijọba sọ.















