Àwa olùkọ́ fásitì tí kò sí lábẹ́ ASUU kì í yanṣẹ́lódì láti bèèrè ẹ̀tọ́ wa, ìpalára ni wíwo iṣẹ́ níran ń kó bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ - CONUA

Ọpọ awọn akẹkọ fasiti joko si yara ikawe to ni akasọ, wọn n dori kodo lati kọ iwe

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 12

Bi iyanṣẹlodi awọn olukọ ile ẹkọ giga yunifasiti, Academic Staff Union of Universities (ASUU) ṣe n tẹsiwaju, ti awọn oṣiṣẹ labẹ Congress of Nigerian University Academic (CONUA) si n ba iṣẹ tiwọn lọ,

Idi ree ti BBC News Yoruba fi kan si ẹgbẹ awọn olukọ fasiti to wa labẹ ẹgbẹ CONUA lati sọ idi ti wọn ko fi kopa ninu iyansẹlodi to n lọ lọwọ.

Bakan naa, a fẹ mọ idi abajọ ti wọn ko fi fẹẹ lo ilana iyanṣẹlodi lati beere ẹtọ ti wọn ati ohun ti ẹgbẹ ọhun duro fun.

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Aarẹ ẹgbẹ CONUA lapapọ, Ọjọgbọn Niyi Sunmonu, ṣalaye pe:

"Akojọpọ awọn olukọ ile ẹkọ giga ni CONUA, laarin ọdun 2022 si 2023 si ni ẹgbẹ CONUA bẹrẹ, tijọba si fi ọwọ si agbekalẹ rẹ."

O ni gbogbo ipo to wa laaarin olukọ lati ibẹrẹ ti a mọ si Graduate assistant, titi de Professor ti i ṣe Ọjọgbọn, lo si wa ni CONUA.

Sunmonu ni awọn ọmọ ẹgbẹ CONUA wa ni fasiti ọgbọn (30) yika orilẹede Naijiria.

"Ìdí tí a kò fi darapọ̀ mọ́ ASUU láti yanṣẹ́lódì"

Nigba to n ṣalaye idi ti CONUA ko fi darapọ mọ iyanṣẹlodi ASUU to n lọ lọwọ, Aarẹ ẹgbẹ naa sọ pe ko lodi sofin lati lo ilana iyanṣẹlodi lati beere ẹtọ ẹgbẹ, ṣugbọn CONUA ko ri i bi ohun to wulo ni awọn ko ṣe ki n yanṣẹlodi ni tawọn.

"Awọn ẹgbẹ keji wa lo ni awọn fẹ yanṣẹlodi, awọn ni wọn si mọ ohun ti wọn ri, ohun ti wọn ri yẹn, awa ko ri i."

Sunmọnu sọ pe eyi ko tumọ si pe awọn naa ko ni ohun ti awọn n beere lọwọ ijọba, ṣugbọn ọna tawọn fi n beere lo yatọ.

O fi kun un pe ASUU lo n ba ijọba sọrọ, wọn ko pe CONUA si i, ati pe igba ti ajọsọ naa de aaye kan ni wọn ri i pe o ti ya kawọn yanṣẹlodi.

Aarẹ CONUA sọ pe bi awọn ba lọwọ si iyanṣẹlodi ASUU yii, bii igba ti eeyan ko ni laakaye ni.

Amugbalẹgbẹẹ Ọjọgbọn, Niyi Sunmonu (Aarẹ ẹgbẹ Congress of Nigerian University Academics (CONUA)

Oríṣun àwòrán, Guardian

Àkọlé àwòrán, Amugbalẹgbẹẹ Ọjọgbọn, Niyi Sunmonu, Aarẹ ẹgbẹ Congress of Nigerian University Academics (CONUA)
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ni itẹsiwaju alaye rẹ, Niyi Sunmonu sọ ohun ti ki i jẹ ki CONUA yanṣẹlodi ni pe ilana naa ko mu esi ayọ wa lati ogoji ọdun o le ti wọn ti n lo o fun ẹhonu.

"Iyanṣẹlodi maa n ṣakoba fun ilọsiwaju ni, awọn akẹkọọ ti ko mọwọ mẹsẹ lo n jiya ẹ. Awa naa jiya iyanṣẹlodi nigba ti a wa nipo akẹkọọ, awọn ọmọ wa lo tun wa n jiya naa bayii."

O fi kun un pe eyi ni CONUA ṣe kọ lati maa yanṣẹlodi bi wọn ba tilẹ fẹ fi aidunnu wọn han si ijọba.

Niwọn igba to jẹ pe ijọba awaarawa lo wa ni Naijiria, Aarẹ CONUA sọ pe asọye lo yẹ ki ẹgbẹ to ba fẹ ba ijọba sọrọ maa ni pẹlu wọn, ki i ṣe ki wọn maa yanṣẹlodi, ki awọn ti ko mọwọ mẹsẹ si maa jiya.

"Ti a ba sọ asọye pẹlu wọn ti ko mu esi wa, a tun maa fi ẹjọ wọn sun onitiju wọn.Bi ko ba tun mu esi ayọ wa, ka lọ sile ẹjọ, ti a ba ti kootu de, ka waa wo ohun ti yoo ṣẹlẹ.''

Bẹẹ ni Amugbalẹgbẹẹ Ọjọgbọn, Niyi Sunmonu ṣalaye.

O ni awọn eeyan ki i fẹ sọ asọyepọ pẹlu ijọba, nitori o maa n pẹ loju wọn ki esi to de. Sunmonu ni ṣe esi naa ti wa n ya bayii pẹlu iyanṣẹlodi ti wọn n ba bọ lati ọdun gbọọrọ.

Ṣé ASUU kò dí CONUA lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ nínú ìyanṣẹ́lódì yìí?

Nipa boya wọn n le tẹsiwaju lẹnu iṣẹ lasiko iyanṣẹlodi yii, Aarẹ CONUA dahun pe eyi kọ ni igba akọkọ ti awọn yoo ṣiṣẹ lasiko iyanṣẹlodi. O ni o ti ṣẹlẹ bẹẹ ri ni 2022, laaarin oṣu keji, ikẹta de ikẹrin.

Sunmonu sọ pe idanwo n ṣunmọ lasiko yẹn, igun keji si daṣẹ silẹ. O ni ṣugbọn CONUA n ṣiṣẹ lọ, awọn si pari idanwo naa.

"Ni ti eyi to n lọ lọwọ yii naa, awọn eeyan wa n ba iṣẹ lọ nibi ti wọn wa."

O fi kun un pe awọn igun keji gbiyanju lati di wọn lọwọ lawọn ibi kan, ṣugbọn awọn ọmọ ẹgbẹ CONUA ko da wọn lohun.

O tẹsiwaju pe ofin Naijiria fi aaye gba ẹni to ba fẹ ṣiṣẹ lasiko iyanṣẹlodi lati maa ṣe tiẹ lọ, òwò ki i fun òwò lọrun.

Lori awọn ileewe giga fasiti ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ CONUA, aarẹ ẹgbẹ naa darukọ: Obafemi Awololo Yunifasiti, Yunifasiti Benin, Ahmadu Bello Yunifasiti ni Zaria, Yunifasiti Maiduguri; l'Abuja, National Mathematical Center; Abuja, Alex Ekwueme University, Ikwo, Nmandi Azikwe Yunifasiti, Awka, Yunifasiti Calabar, Yunifasiti Uyo ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Aworan awọn akẹkọọ to jokoo sita lai ṣiṣẹ ninu ọgba ile ẹkọ giga. Akẹkọọbinrin to wa niwaju ninu aworaN naa n yẹ foonu rẹ wo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn akẹkọọ jokoo sita ninu ọgba ile ẹkọ wọn.

Ìyapa wọ ìyanṣẹ́lódì ASUU, àwọn olùkọ́ fásitì lábẹ́ ẹgbẹ́ CONUA kẹ̀yìn sí ìyanṣẹ́lódì

Latari iyanṣẹlodi ti ẹgbẹ awọn olukọ fasiti (ASUU) kede rẹ, igbimọ awọn olukọ yunifasiti ti a mọ si Congress of University Academics (CONUA) ti ni awọn ko ba wọn lọwọ si iyanṣẹlodi naa ni tawọn.

Atẹjade kan ti CONUA fi sita lọjọ Aiku, ọjọ kejila oṣu Kewaa ọdun 2025 ni wọn ti ni iyanṣẹlodi ASUU naa n da ariyanjiyan silẹ lawujọ awọn oṣiṣẹ fasiti ati awọn akẹkọọ.

Lati tan imọlẹ si ohun to ruju naa ni CONUA ninu atẹjade ti Aarẹ igbimọ naa,Ọmọwe 'Niyi Sunmonu, buwọlu, ni wọn ti ṣalaye pe:

"Awa olori Congress of University Academics (CONUA) fẹ la a ye gbogbo eeyan, pe CONUA ko kede iyanṣẹlodi kankan, bẹẹ ni a ko kopa ninu iyanṣẹlodi to n lọ lọwọ.

Aworan idanimọ CONUA

Oríṣun àwòrán, CONUA

Àkọlé àwòrán, Aworan idanimọ CONUA

Kí ni ìdí tí ẹgbẹ́ olúkọ́ lábẹ́ CONUA ṣe kẹ́yìn sí ìyanṣẹ́lódì?

Ninu atẹjade CONUA, wọn ṣalaye pe ko si idi kankan fun awọn lasiko yii lati kede ai gbọraẹniye tabi gunle iyanṣẹlodi kankan.

CONUA sọ pe nigba ti igbimọ to fẹnuko lori ajọsọ lasiko ipade oṣu Kẹwaa ọdun 2009 jokoo ipade, wọn ko pe awọn si i.

"Ẹgbẹ yii fẹhonuhan nigba naa, eyi to pada fa ipade ti a sẹ pẹlu Minisita eto ẹkọ lọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan-an ọdun 2025.

"Nibi ipade ni Minisita ti gba ọrọ wa yẹ wo, to si ni igbimọ Yayale Ahmed yoo ri i pe gbogbo ẹgbẹ yunifasiti apapọ ni yoo kan .

" O dun mọ wa pe ileeṣẹ eto ẹkọ ti ṣe eyi.

"Bi ko ba ti i kan CONUA, ti awọn ohun ti a beere fun ko si ti i mu ariyanjiyan wa lọdọ ijọba apapọ, ko si idi kankan fun CONUA lati gunle iyanṣẹlodi''

Bẹẹ ni apa kan atẹjade igbimọ naa ka.

Wọn ni ki ẹkọ nileewe giga duro digbi lai si idiwọ ni awọn duro fun, CONUA ni oun gbagbọ ninu ajọsọ alaafia pẹlu ijọba ati awọn alẹnulọrọ.

Nigba ti wọn n ṣalaye ipo wọn lori iyanṣẹlodi yii, CONUA ṣalaye pe

"A n fi eyi rọ awọn ọmọ ẹgbẹ wa lati maa ba iṣẹ lọ labala ẹkọ ati awọn to wa ni ọfiisi eto (Academic and administrative duties).

"Iduroṣinṣin yin ati otitọ inu ṣe pataki fun ẹka ẹkọ ilẹ wa lati gunke agba.

Bakan naa ni wọn rọ awọn ọga ile ẹkọ giga lati ri i pe aabo to peye wa fun awọn ọmọ ẹgbẹ CONUA lẹnu iṣẹ wọn.

Wọn ni ki awọn akẹkọọ naa ma ṣe bẹru, nitori CONUA duro lori ipinnu rẹ lati mu ẹkọ to ye kooro wa si imuṣẹ.

Kí ló mú ki ẹgbẹ́ olùkọ́ ASUU tún fi gùnlé ìyanṣẹ́lódì ọlọ́sẹ̀ méjì?

Àsíá ASUU àti èèyàn tó gbé pátákó pé ASUU gùnlé ìyanṣẹ́lódì dání

Oríṣun àwòrán, ASUU/X

Ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ti kéde ìgbésẹ̀ bíbẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì ọlọ́sẹ̀ méjì ní gbogbo ilé ẹ̀kọ́ gíga tó jẹ́ ti ìjọba bẹ̀rẹ̀ láti òní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹtàlá, oṣù Kẹwàá, ọdún 2025.

Ààrẹ àpapọ̀ fún ẹgbẹ́ ASUU, Ọ̀jọ̀gbọ́n Chris Piwuna ló kéde ìyanṣẹ́lódì náà níbi àpérò àwọn akọ̀ròyìn tó ṣe ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìlú Abuja lọ́jọ́ Àìkú.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Piwuna sọ pé kò sí ìgbésẹ̀ kan sàn-án láàárín ẹgbẹ́ náà àti ìjọba àpapọ̀ láti dáwọn dúró láti má gùnlé ìyanṣẹ́lódì tí wọ́n ti ń gbèrò náà.

Ó ní ìkìlọ̀ ọlọ́jọ̀ mẹ́rìnlá tí àwọn ti fi léde láti ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹsàn-án, 2025 ni ọjọ́ ti lọ lórí rẹ̀ láì sí èsì kankan láti ọwọ́ àwọn aláṣẹ tí ọ̀rọ̀ náà kàn.

Ó ṣàlàyé pé gbogbo àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì tó jẹ́ ti ìjọba àpapọ̀ tí wọ́n ti ń ṣe ẹgbẹ́ ASUU ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ kò ti ní ṣiṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kétàlá, oṣù Kẹwàá.

Ó fi kun pé ìgbésẹ̀ náà ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ti fẹnukò níbi ìpàdé àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ tó wáyé láìpẹ́.

Kí ló dé tí ASUU fi fẹ́ gùnlé ìyanṣẹ́lódì?

Ní ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2025 ni ẹgbẹ́ ASUU ti fún ìjọba àpapọ̀ ní gbèdéke ọjọ́ mẹ́rìnlá láti dáhùn àwọn ìbéèrè àwọn tàbí kí àwọn bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì.

ASUU nínú àtẹ̀jáde kan lẹ́yìn ìpàdé ẹgbẹ́ náà fẹ̀sùn kan ìjọba àpapọ̀ pé wọn kò ṣe ohun tí àwọn ń fẹ́, tí wọ́n sì ń dẹ́yẹ sí àwọn àti pé gbogbo ìfẹnùkò tí àwọn ní ni kò so èso rere.

Ní oṣù Kẹjọ, ọdún 2025 ni àwọn ẹgbẹ́ ASUU ní ilé ẹ̀kọ́ ìjọba àpapọ̀ àti ti ìpínlẹ̀ ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn nínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ wọn láti fi rán ìjọba lẹtí láti dáhùn àwọn ìbéèrè tó ti wà láàárín fún ọjọ́ pípẹ́.

"Gbogbo ìwọ́de tí a ṣe ni kò so èso rere kankan. Ohun tó fojú hàn báyìí ni pé ìjọba àpapọ̀ àti ti ìpínlẹ̀ kò náání ètò ẹ̀kọ́ àti ìgbáyégbádùn àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga rárá," ẹgbẹ́ ASUU sọ.

Ìjọba àpapọ̀ fèsì

Ẹ̀wẹ̀, ìjọba àpapọ̀ ní ọjọ́rú, ọ̀sẹ̀ tó kọjá ti pàrọwà sí ASUU láti má gùnlé ìyanṣẹ́lódì tí wọ́n ń gbèrò náà.

Mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́, Tunji Alausa sọ pé ìjọba àpapọ̀ ní ìfarajìn sí sísan gbogbo àjẹmọ́nú àwọn olùkọ́ náà tí ìjóba jẹ wọ́n.

Alausa sọ pé ìjọba àpapọ̀ ti ń bojú wo gbogbo àwọn ìbéèrè ẹgbẹ́ náà, tí wọ́n sì ti ń ṣe akitiyan láti jíròrò pẹ̀lú wọn lójúnà àti dènà wọn láti gùnlé ìyanṣẹ́lódì.

Ó ṣàlàyé pé ìjọba ti gbé ìgbìmọ̀ kan dìde tó máa jíròrò pẹ̀lú àwọn olùkọ́, àwọn tí kìí ṣe olùkọ́ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga tó fi mọ́ ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe àtàwọn ilé ẹ̀kọ́ olùkọ́ni.

Ó fi kun pé Ààrẹ Bola Tinubu ti fún àwọn ní ìdarí láti dènà ìyanṣẹ́lódì, kó má ba à sí ìdíwọ́ fún ètò ẹ̀kọ́ kankan.

Ṣùgbọ́n ààrẹ ASUU sọ pé ẹ̀bẹ̀ tí ìjọba àpapọ̀ ń bẹ àwọn nígbà tó ku ọjọ́ méjì tí àwọn máa bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì ti pẹ́ jù.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Pinuwa níbi ètò iléeṣẹ́ Channels TV lọ́jọ́rú tó kọjá sọ pé ìjọba kìí kọbi ara sí ìbéèrè àwọn àyàfi tí àwọn bá ti fẹ́ gùnlé ìyanṣẹ́lódì.

"Wọ́n pè wá sí ìpàdé ní ìpínlẹ̀ Sokoto, wọ́n dá ọ̀sẹ̀ mẹ́ta fún wa, tí a sì gbà àmọ́ a ò gbọ́ nǹkankan mọ́ títí di ìgbà tí a dúnkokò láti gùnlé ìyanṣẹ́lódì.

"Wọ́n ń bẹ̀ wá láti má gùnlé ìyanṣẹ́lódì. Ìfẹnùkò ọdún 2009 tí a ṣe pẹ̀lú ìjọba, a ò tíì rí àbọ̀ rẹ̀."

Ààrẹ ASUU náà tẹnumọ pé àwọn máa gùnlé ìyanṣẹ́lódì gẹ́gẹ́ bí àwọn ṣe sọ àyàfi tí ìjọba bá gbé ìgbésẹ̀ lórí àwọn ìbéèrè àwọn.

Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí ASUU yóò gùnlé ìyanṣẹ́lódì.

Ní oṣù Keji, ọdún 2022, ni ẹgbẹ́ ASUU gùnlé ìyanṣẹ́lódì olóṣù kan láti fi ṣèkìlọ̀ fún ìjọba láti mú àdéhùn tí wọ́n ṣe fún ẹgbẹ́ náà ṣẹ.

Ààrẹ ẹgbẹ́ ASUU nígbà náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Emmanuel Osodeke fi àtẹ̀jáde kan sórí ẹ̀rọ ayélujára Twitter rẹ̀ pé àwọn yóò gùnlé ìyanṣẹ́lódì ṣùgbọ́n ìfẹ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn ṣe pàtàkì.

Ní ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kọkànlá, ọdún 2021, ASUU fún ìjọba àpapọ̀ ní gbèdéke ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti dáhùn gbogbo ìbéèrè àwọn ṣùgbọ́n tí ìjọba kùnà láti ṣe.

Nígbà tó ń ikọ̀ ìròyìn BBC sọ̀rọ̀, ọ̀jọ̀gbọ́n Osodeke ní láti oṣù kìíní ọdún 2021 ní ìjọba àpapọ̀ ti ṣe àdéhùn fún àwọn ṣùgbọ́n tí wọn kò ṣe àmúṣẹ rẹ̀ títí inú oṣù kejìlá.

Ní ọdún 2020, oṣù mẹ́jọ ni ASUU fi yan iṣẹ́ lódì, ìyanṣẹ́lódì náà bẹ̀rẹ̀ nínú ọsù kẹta tó sì parí nínú oṣù kejìlá lẹ́yìn tí ìjọba àti ASUU tọwọ́bọ àdéhùn.

Lẹ́yìn èyí ni ìjọba kéde pé àwọn ti fún ASUU ní ọgbọ̀n bílíọ̀nù Náírà ṣùgbọ́n ASUU ní àwọn kò rí omira débi tí wọn yóò rí ẹ̀jẹ̀ títí di àsìkò yìí.

ASUU ní ìjọba kò ì tíì mú àdéhùn wọn ṣẹ.